Skip to content

Babylon

255 verses · 3 known names

A tún mọ̀ ọ́n sí: Babylon's, Sheshach

32.5300, 44.4200 Wo lórí Google Maps

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Babylon

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nísinsin yìí, Èmi yóò fa gbogbo orílẹ̀-èdè rẹ fún Nebukadnessari ọba Babeli ìránṣẹ́ mi; Èmi yóò sì mú àwọn ẹranko búburú wọ̀n-ọn-nì jẹ́ tirẹ̀.

  2. “ ‘ “Ṣùgbọ́n tí orílẹ̀-èdè tàbí ìjọba kan kò bá ní sin Nebukadnessari ọba Babeli, tàbí kí ó tẹ orí rẹ̀ ba ní abẹ́ àjàgà rẹ̀, Èmi yóò fi ìyà jẹ orílẹ̀-èdè náà nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, ni Olúwa wí títí Èmi yóò fi run wọ́n nípa ọwọ́ rẹ̀.

  3. Nítorí náà, ẹ má ṣe tẹ́tí sílẹ̀ sí àwọn wòlíì yín, àwọn aláfọ̀ṣẹ yín, àwọn tí ń rọ́ àlá fún un yín, àwọn oṣó yín, tàbí àwọn àjẹ́ yín tí wọ́n ń sọ fún un yín pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli.’

  4. Ṣùgbọ́n bí orílẹ̀-èdè kankan bá tẹ orí rẹ̀ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, tí ó sì sìn ín, Èmi yóò jẹ́ kí orílẹ̀-èdè náà wà lórí ilẹ̀ rẹ̀ láti máa ro ó, àti láti máa gbé ibẹ̀ ni Olúwa wí.” ’ ”

  5. Èmi sì sọ ọ̀rọ̀ náà fún Sedekiah ọba Juda wí pé: “Tẹ orí rẹ ba lábẹ́ àjàgà ọba Babeli, sìn ín ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ, ìwọ yóò sì yè.

  6. Kí ló dé tí ìwọ àti àwọn ènìyàn rẹ yóò ṣe kú nípa idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn, èyí tí Olúwa fi ń halẹ̀ mọ́ àwọn orílẹ̀-èdè tí kò bá sin ọba Babeli?

  7. Ẹ má ṣe fetísílẹ̀ sí ọ̀rọ̀ àwọn wòlíì tí ó ń sọ wí pé, ‘Ẹ̀yin kò ní sin ọba Babeli,’ nítorí pé àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín.

  8. Nígbà náà ni mo sọ fún àwọn àlùfáà àti gbogbo àwọn ènìyàn náà wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ, ẹ má ṣe fetí sí nǹkan tí àwọn wòlíì ń sọ pé, ‘Láìpẹ́ ohun èlò ilé Olúwa ni a ó kó padà láti Babeli,’ àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ. Ẹ má tẹ́tí sí wọn.

  9. Má ṣe tẹ́tí sí wọn, ẹ máa sin ọba Babeli, ẹ̀yin yóò sì yè. Èéṣe tí ìlú yóò fi di ahoro?

  10. Tí wọ́n bá jẹ́ wòlíì, tí wọ́n sì ní ọ̀rọ̀ Olúwa, jẹ́ kí wọ́n bẹ Olúwa àwọn ọmọ-ogun kí a má ṣe kó ohun èlò tí ó kù ní ilé Olúwa àti ní ààfin ọba Juda àti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

  11. Èyí tí Nebukadnessari ọba Babeli kò kó lọ nígbà tí ó mú Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda lọ sí ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli, pẹ̀lú àwọn ọlọ́lá Juda àti Jerusalẹmu.

  12. ‘A ó mú wọn lọ sí ilẹ̀ Babeli, ní ibẹ̀ ni wọn ó sì wà títí di ìgbà tí mo bá padà,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa. ‘Lẹ́yìn èyí, Èmi yóò mú wọn padà, Èmi yóò sì ṣe wọ́n lọ́jọ̀ ní ibí yìí.’ ”

  13. “Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: ‘Èmi yóò mú àjàgà ọba Babeli rọrùn.

  14. Láàrín ọdún méjì, Èmi yóò mú gbogbo ohun èlò tí ọba Nebukadnessari; ọba Babeli kó kúrò ní ilé Olúwa tí ó sì kó lọ sí Babeli padà wá.

  15. Èmi á tún mú ààyè Jekoniah ọmọ Jehoiakimu ọba Juda padà, àti gbogbo àwọn tí ń ṣe àtìpó láti Juda ní Babeli,’ èyí ni ọ̀rọ̀ Olúwa pé, ‘àjàgà yín láti ọwọ́ ọba Babeli yóò rọrùn.’ ”

  16. Jeremiah wòlíì wí pé, “Àmín! Kí Olúwa kí ó ṣe bẹ́ẹ̀! Kí Olúwa kí ó mú ọ̀rọ̀ rẹ̀ tí ìwọ sọ àsọtẹ́lẹ̀ ṣẹ, láti mú ohun èlò ilé Olúwa àti gbogbo àwọn ìgbèkùn láti ilẹ̀ Babeli padà wá sí ibí yìí.

  17. Hananiah sọ níwájú gbogbo ènìyàn wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa wí: ‘Bákan náà ni Èmi yóò fọ́ àjàgà ọrùn Nebukadnessari, ọba Babeli láàrín ọdún méjì.’ ” Wòlíì Jeremiah sì bá ọ̀nà tirẹ̀ lọ.

  18. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí: Èmi yóò fi àjàgà onírin sí ọrùn gbogbo orílẹ̀-èdè láti lè máa sin Nebukadnessari ọba Babeli, àti pé gbogbo yín ni ẹ̀ ó máa sìn ín. Èmi yóò tún fún un ní àṣẹ lórí àwọn ẹranko búburú.’ ”

  19. Èyí ni ọ̀rọ̀ inú lẹ́tà tí wòlíì Jeremiah rán láti Jerusalẹmu sí ìyókù nínú àwọn àgbàgbà tí ó wà ní ìgbèkùn àti sí àwọn àlùfáà, àwọn wòlíì àti gbogbo àwọn ènìyàn tí Nebukadnessari tí kó ní ìgbèkùn láti Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

  20. Ó fi lẹ́tà náà rán Eleasa ọmọ Ṣafani àti Gemariah ọmọ Hilkiah, ẹni tí Sedekiah ọba Juda rán sí Nebukadnessari ọba Babeli. Wí pé.

  21. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa Ọlọ́run Alágbára Israẹli sọ fún gbogbo àwọn ènìyàn tí mo kó lọ ṣe àtìpó láti Jerusalẹmu ní Babeli:

  22. Báyìí ni Olúwa wí: “Nígbà tí ẹ bá lo àádọ́rin ọdún pé ní Babeli, èmi yóò tọ̀ yín wá láti ṣe àmúṣẹ ìlérí ńlá mi fún un yín, àní láti kó o yín padà sí Jerusalẹmu.

  23. Ẹ̀yin lè wí pé, “Olúwa ti gbé àwọn wòlíì dìde fún wa ní Babeli.”

  24. Nítorí náà, gbogbo ẹ̀yin ìgbèkùn, ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí mo rán lọ kúrò ní Jerusalẹmu lọ sí Babeli.

  25. Èyí ni ohun tí Olúwa àwọn ọmọ-ogun, Ọlọ́run Israẹli sọ nípa Ahabu ọmọ Kolaiah àti nípa Sedekiah ọmọ Maaseiah tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké fún un yín lórúkọ mi: “Èmi yóò fi wọ́n lé Nebukadnessari ọba Babeli lọ́wọ́. Òun yóò sì gba ẹ̀mí wọn ní ìṣẹ́jú yìí gan an.