Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Ilé tí ọkùnrin náà bá wọ̀, kí ẹ wí fún baálé náà pé, ‘Olùkọ́ rán wa pé, níbo ni gbàngàn àpèjẹ náà gbé wa, níbi tí èmi yóò gbé jẹ àsè ìrékọjá pẹ̀lú àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mi?’
Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn méjì náà sì jáde lọ àárín ìlú. Wọ́n bá gbogbo nǹkan gẹ́gẹ́ bí Jesu tí sọ fún wọn. Wọ́n sì pèsè àsè ìrékọjá.
Nígbà tí ó di alẹ́, Jesu àti àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ dé síbẹ̀.
Bí wọ́n sì ti jókòó yí tábìlì ká, tí wọ́n ń jẹun, Jesu wí pé, “Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, ọ̀kan nínú ẹ̀yin tí ẹ ń bá mi jẹun yìí ni yóò fi mí hàn.”
Ọkàn wọn sì bẹ̀rẹ̀ sí í dàrú. Olúkúlùkù sì ń bi í ní ọ̀kọ̀ọ̀kan wí pé, “Dájúdájú, kì í ṣe èmi?”
Ó sì dáhùn wí pé, “Ọ̀kan nínú ẹ̀yin méjìlá tí ó ń bá mi tọwọ́ bọ àwo jẹun nísinsin yìí ni.
Nítòótọ́ Ọmọ Ènìyàn ń lọ bí a ti kọ̀wé nípa rẹ̀, ṣùgbọ́n ègbé ní fún ọkùnrin náà, láti ọwọ́ ẹni tí a ti fi Ọmọ Ènìyàn hàn. Ìbá sàn fún un bí a kò bá bí i rárá.”
Bí wọ́n ti ń jẹun lọ́wọ́, Jesu mú ìṣù àkàrà kan, ó gbàdúrà sí i. Lẹ́yìn náà ó bù ú sí wẹ́wẹ́, ó sì fi fún wọn. Ó wí pé, “Ẹ gbà jẹ, èyí yìí ni ara mi.”
Bákan náà, ó sì mú ago wáìnì, ó dúpẹ́ fún un, ó sì gbé e fún wọn. Gbogbo wọn sì mu nínú rẹ̀.
Ó sì wí fún wọn pé, “Èyí ni ẹ̀jẹ̀ mi tí májẹ̀mú tuntun, tí a ta sílẹ̀ fún ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn.
Lóòótọ́ ni mo wí fún un yín, èmi kò tún ní mu ọtí wáìnì mọ́ títí yóò fi di ọjọ́ náà tí Èmi yóò mu ún ní tuntun nínú ìjọba Ọlọ́run.”
Jesu sì wí fún wọn pé, “Gbogbo yín ni ẹ ó sa kúrò lọ́dọ̀ mi, a ti kọ̀wé rẹ pé, “ ‘Èmi yóò lu olùṣọ́-àgùntàn àwọn agbo àgùntàn yóò sì fọ́nká.’
Ṣùgbọ́n lẹ́yìn ìgbà ti mo ba jíǹde tan, èmi yóò síwájú yin lọ sí Galili.”
Ṣùgbọ́n Peteru dá a lóhùn, ó wí pé, “Bí gbogbo ènìyàn tilẹ̀ sá kúrò lẹ́yìn rẹ, èmi kò ní sá.”
Jesu si wí fún un pé, “Jẹ́ kí ń sọ òótọ́ fún ọ. Kí àkùkọ tó ó kọ lẹ́ẹ̀kejì ní òwúrọ̀ ọ̀la, ìwọ, pàápàá yóò ti sọ lẹ́ẹ̀mẹ́ta wí pe ìwọ kò mọ̀ mí rí.”
Ṣùgbọ́n Peteru fa ara ya, ó wí pé, “Bí mo tilẹ̀ ní láti kú pẹ̀lú rẹ̀, èmi kò jẹ́ sọ pé n kò mọ̀ ọ́n rí.” Ìlérí yìí kan náà ni àwọn ọmọ-ẹ̀yìn ìyókù bẹ̀rẹ̀ sí í ṣe.
Nígbà tí wọ́n dé ibi kan tí wọ́n ń pè ní ọgbà Getsemane. Jesu wí fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ pé, “Ẹ jókòó dè mí níhìn-ín títí n ó fi lọ gbàdúrà.”
Ó sì mú Peteru àti Jakọbu àti Johanu lọ pẹ̀lú rẹ̀. Òun sì kún fún ìrẹ̀wẹ̀sì àti ìbànújẹ́ gidigidi.
Ó sì lọ síwájú díẹ̀, ó dojúbo ilẹ̀, ó sì bẹ̀rẹ̀ sí i gbàdúrà pé, bí ó bá ṣe e ṣe kí wákàtí tí ó bọ̀ náà ré òun kọjá.
Ó sì wí pé, “Ábbà, Baba, ìwọ lè ṣe ohun gbogbo, mú ago yìí kúrò lórí mi, ṣùgbọ́n kì í ṣe èyí tí èmi fẹ́, bí kò ṣe èyí tí ìwọ fẹ́.”
Nígbà tí ó sì padà dé ọ̀dọ̀ àwọn ọmọ-ẹ̀yìn mẹ́ta, ó bá wọn lójú oorun. Ó sì wí fún Peteru pé, “Simoni, o ń sùn ni? Ìwọ kò lè bá mi ṣọ́nà fún wákàtí kan?
Ó sì tún lọ lẹ́ẹ̀kan sí i. Ó sì gbàdúrà gẹ́gẹ́ bí ó ti gbà á ti ìṣáájú.
Nígbà tí ó sì tún padà dé, ó bá wọn wọ́n ń sùn, nítorí pé ojú wọn kún fún oorun. Wọn kò sì mọ irú èsì tí wọn ìbá fún un.
Ó sì wá nígbà kẹta, ó sì wí fún wọn pé, “Ẹ máa sùn kí ẹ sì máa sinmi ó tó bẹ́ẹ̀, wákàtí náà ti dé, wò ó, a fi Ọmọ Ènìyàn lé àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ lọ́wọ́.
Ẹ dìde, ẹ jẹ́ kí a máa lọ. Ẹ wò ó, ẹni tí yóò fi mí hàn wà ní tòsí!”