Jesus
A tún mọ̀ ọ́n sí: Jesus Christ, Immanuel, Emmanuel, Christ
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesus
Ó ń sọ̀rọ̀ lòdì sí àwọn ará Helleni, ó sì ń jà wọ́n ní iyàn; ṣùgbọ́n wọn ń pète láti pa a.
Nígbà náà ni ìjọ wà ni àlàáfíà yíká gbogbo Judea àti ni Galili àti ni Samaria, wọn ń fẹsẹ̀múlẹ̀, wọn ń rìn ní ìbẹ̀rù Olúwa, àti ni ìtùnú Ẹ̀mí Mímọ́, wọn ń pọ̀ sí i.
Peteru sì wí fún un pé, “Aenea, Jesu Kristi mú ọ láradá; dìde kí ó sì tún àkéte rẹ ṣe.” Ó sì dìde lójúkan náà.
Gbogbo àwọn tí ń gbé Lida àti Ṣaroni sì rí i, wọn sì yípadà sí Olúwa.
Èyí sì di mí mọ̀ já gbogbo Joppa; ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì gba Olúwa gbọ́.
Nígbà tí ó sì tẹjúmọ́ ọn, ti ẹ̀rù sì bà á, ó ní, “Kín ni, Olúwa?” Ó sì wí fún un pé, “Àdúrà rẹ àti ọrẹ-àánú, tìrẹ gòkè lọ síwájú Ọlọ́run fún ìrántí.
Ṣùgbọ́n Peteru dáhùn pé, “Rara, Olúwa; nítorí èmi kò jẹ ohun èèwọ̀ àti aláìmọ́ kan rí.”
Ṣùgbọ́n ni gbogbo orílẹ̀-èdè, ẹni tí ó bá bẹ̀rù rẹ̀, ti ó sì ń ṣiṣẹ́ òdodo, ẹni ìtẹ́wọ́gbà ni lọ́dọ̀ rẹ̀.
Ẹyin mọ ọrọ̀ tí Ọlọ́run rán sí àwọn ọmọ Israẹli láti kéde ìròyìn ayọ̀ àlàáfíà nípasẹ̀ Jesu Kristi, ẹni ti ṣe Olúwa ohun gbogbo.
Àní Jesu ti Nasareti, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti da Ẹ̀mí Mímọ́ àti agbára le lórí; ẹni tí ó ń kiri ṣe oore, ó ń ṣe ìmúláradá gbogbo àwọn tí èṣù sì ń pọ́n lójú; nítorí Ọlọ́run wà pẹ̀lú rẹ̀.
“Àwa sì ni ẹlẹ́rìí gbogbo ohun tí ó ṣe, ní ilẹ̀ àwọn Júù, àti ni Jerusalẹmu. Ẹni tí wọ́n pa nípa gbígbékọ́ sí orí igi.
Òun ni Ọlọ́run jí dìde ni ọjọ́ kẹta ó sì fi i hàn gbangba.
Kì í ṣe fún gbogbo ènìyàn ni o ri, bí kò ṣe fún àwa ti a jẹ́ ẹlẹ́rìí ti a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn tẹ̀lé, ti a bá a jẹ, ti a sì bá à mu lẹ́yìn ìgbà ti ó jíǹde kúrò nínú òkú.
Ó sì pàṣẹ fún wa láti wàásù fún àwọn ènìyàn, àti láti jẹ́rìí pé, òun ni a ti ọwọ́ Ọlọ́run yàn ṣe onídàájọ́ ààyè àti òkú.
Òun ni gbogbo àwọn wòlíì jẹ́rìí sì pé, ẹnikẹ́ni ti ó bá gbà á gbọ́ yóò rí ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀ gbà nípa orúkọ rẹ̀.”
Ó sì pàṣẹ kí a bamitiisi wọn ni orúkọ Jesu Kristi. Nígbà náà ni wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó dúró ni ọjọ́ mélòó kan.
“Ṣùgbọ́n mo dáhùn wí pé, ‘Rara Olúwa! Nítorí ohun èèwọ̀ tàbí ohun aláìmọ́ kan kò wọ ẹnu mi rí láéláé.’
Nígbà náà ni mo rántí ọ̀rọ̀ Olúwa, bí ó ti wí pé, ‘Johanu fi omi bamitiisi nítòótọ́; ṣùgbọ́n a ó fi Ẹ̀mí Mímọ́ bamitiisi yín.’
Ǹjẹ́ bí Ọlọ́run sì ti fi irú ẹ̀bùn kan náà fún wọn bí ó ti fi fún àwa pẹ̀lú nígbà tí a gba Jesu Kristi Olúwa gbọ́, ta ni èmi tí n ó fi rò pé mo le è de Ọlọ́run ní ọ̀nà?”
Ṣùgbọ́n àwọn kan ń bẹ nínú wọn tí ó jẹ́ ará Saipurọsi àti Kirene; nígbà tí wọ́n dé Antioku, wọ́n sọ̀rọ̀ fún àwọn Helleni pẹ̀lú, wọ́n ń wàásù ìròyìn ayọ̀ nípa Jesu Olúwa.
Ọwọ́ Olúwa sì wà pẹ̀lú wọn, ọ̀pọ̀lọpọ̀ ènìyàn sì gbàgbọ́, wọ́n sì yípadà sí Olúwa.
Nígbà ti ó dé ti ó sì rí ẹ̀rí oore-ọ̀fẹ́ Ọlọ́run, ó yọ̀, ó sì gba gbogbo wọn níyànjú pé, pẹ̀lú ìpinnu ọkàn ni kí wọn fi ara mọ́ Olúwa.
Nítorí òun jẹ́ ènìyàn rere, ó sì kún fún Ẹ̀mí Mímọ́ àti fún ìgbàgbọ́; ènìyàn púpọ̀ ni a sì kà kún Olúwa.
Sì wò ó, angẹli Olúwa farahàn, ìmọ́lẹ̀ sì mọ́ nínú túbú; ó sì lu Peteru pẹ́pẹ́ lẹ́gbẹ̀ẹ́, ó jí i, ó ni, “Dìde kánkán!” Ẹ̀wọ̀n sí bọ́ sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ Peteru.
Nígbà tí ojú Peteru sì wálẹ̀, ó ní, “Nígbà yìí ni mo tó mọ̀ nítòótọ́ pé, Olúwa rán angẹli rẹ̀, ó sì gbà mi lọ́wọ́ Herodu àti gbogbo ohun tí àwọn ènìyàn Júù ń retí!”