Fò sí àkóónú

Jesse

44 ẹsẹ · 10 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Jesse

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nabali sì dá àwọn ìránṣẹ́ Dafidi lóhùn pé, “Ta ni ń jẹ́ Dafidi? Tàbí ta ni sì ń jẹ́ ọmọ Jese? Ọ̀pọ̀lọpọ̀ ìránṣẹ́ ni ń bẹ ni ìsinsin yìí tí wọn sá olúkúlùkù kúrò lọ́dọ̀ olúwa rẹ̀.

  2. Ọkùnrin Beliali kan sì ń bẹ níbẹ̀ orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Ṣeba ọmọ Bikri ará Benjamini; ó sì fún ìpè ó sì wí pé, “Àwa kò ní ipa nínú Dafidi, bẹ́ẹ̀ ni àwa kò ni ìní nínú ọmọ Jese! Kí olúkúlùkù ọkùnrin lọ sí àgọ́ rẹ̀, ẹ̀yin Israẹli!”

  3. Wọ̀nyí sì ni ọ̀rọ̀ ìkẹyìn Dafidi. “Dafidi ọmọ Jese, àní ọkùnrin tí a ti gbéga, ẹni àmì òróró Ọlọ́run Jakọbu, àti olórin dídùn Israẹli wí pé,

  4. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i pé ọba kọ̀ láti gbọ́ ti àwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn pé, “Ìpín wo ni àwa ní nínú Dafidi, ìní wo ni àwa ní nínú ọmọ Jese? Padà sí àgọ́ rẹ, ìwọ Israẹli! Bojútó ilé ara rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ará Israẹli padà sí ilé wọn.

  5. Boasi baba Obedi àti Obedi baba Jese.

  6. Jese sì ni baba Eliabu àkọ́bí rẹ̀; ọmọ ẹlẹ́ẹ̀kejì sì ni Abinadabu, ẹlẹ́ẹ̀kẹta ni Ṣimea,

  7. Kò sì béèrè lọ́wọ́ Olúwa, bẹ́ẹ̀ ni Olúwa pa á, Ó sì yí ìjọba náà padà sọ́dọ̀ Dafidi ọmọ Jese.

  8. Nígbà náà Ẹ̀mí Mímọ́ wa sórí Amasai ìjòyè àwọn ọgbọ̀n, ó sì wí pé, “Tìrẹ ni àwa ń ṣe, ìwọ Dafidi! Àwa pẹ̀lú rẹ, ìwọ ọmọ Jese! Àlàáfíà, àlàáfíà fún ọ, àti àlàáfíà fún àwọn tí ó ràn ó lọ́wọ́, nítorí Ọlọ́run rẹ̀ yóò ràn ọ́ lọ́wọ́.” Bẹ́ẹ̀ ni Dafidi sì gbà wọ́n ó sì mú wọn jẹ olórí ẹgbẹ́ ogun.

  9. Dafidi ọmọ Jese jẹ́ ọba lórí gbogbo Israẹli.

  10. Nígbà tí gbogbo Israẹli rí i wí pé ọba kọ̀ láti gbọ́ tiwọn, wọ́n sì dá ọba lóhùn wí pé, “Ìpín kí ní a ní nínú Dafidi, ìní wo ni a ní nínú ọmọ Jese? Ẹ lọ sí àgọ́ yín, ẹ̀yin Israẹli! Bojútó ilé rẹ, ìwọ Dafidi!” Bẹ́ẹ̀ ní gbogbo àwọn ọmọ Israẹli lọ sí ilé wọn.

  11. Rehoboamu fẹ́ Mahalati tí ó jẹ́ ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Dafidi Jerimoti bi àti ti Abihaili, ọmọbìnrin ti ọmọkùnrin Jese Eliabu bí.

  12. Èyí ni ìparí àdúrà Dafidi ọmọ Jese.

  13. Èèkàn kan yóò sọ láti ibi kùkùté Jese, láti ara gbòǹgbò rẹ̀ ni ẹ̀ka kan yóò ti so èso.

  14. Ní ọjọ́ náà, gbòǹgbò Jese yóò dúró gẹ́gẹ́ bí àsíá fún gbogbo ènìyàn, àwọn orílẹ̀-èdè yóò pagbo yí i ká, ibùdó ìsinmi rẹ̀ yóò jẹ́ èyí tí ó lógo.

  15. Salmoni ni baba Boasi, Rahabu sí ni ìyá rẹ̀; Boasi ni baba Obedi, Rutu sí ni ìyá rẹ̀; Obedi sì ni baba Jese;

  16. Jese ni baba Dafidi ọba. Dafidi ni baba Solomoni, ẹni tí ìyá rẹ̀ jẹ́ aya Uriah tẹ́lẹ̀ rí.

  17. tí í ṣe ọmọ Jese, tí í ṣe ọmọ Obedi, tí í ṣe ọmọ Boasi, tí í ṣe ọmọ Salmoni, tí í ṣe ọmọ Nahiṣoni,

  18. Nígbà ti ó sì mú Saulu kúrò, ó gbé Dafidi dìde ní ọba fún wọn, ẹni tí ó sì jẹ́rìí rẹ̀ pé, ‘Mo rí Dafidi ọmọ Jese ẹni bí ọkàn mi, ti yóò ṣe gbogbo ìfẹ́ mi.’

  19. Isaiah sì tún wí pé, “Gbòǹgbò Jese kan ń bọ̀ wá, òun ni ẹni tí yóò dìde ṣe àkóso àwọn Kèfèrí; Àwọn Kèfèrí yóò ní ìrètí nínú rẹ̀.”