Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The First Born

29 ẹsẹ · 40 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ni Ọlọ́run wí pé, “Mo gbọ́, ṣùgbọ́n Sara aya rẹ̀ yóò bí ọmọkùnrin kan fún ọ, ìwọ yóò sì pe orúkọ rẹ̀ ní Isaaki, èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú rẹ̀ ní májẹ̀mú ayérayé àti àwọn irú-ọmọ rẹ̀ lẹ́yìn rẹ̀.

  2. Ṣùgbọ́n ní ti Iṣmaeli, mo gbọ́ ohun tí ìwọ wí, èmi yóò bùkún fún un nítòótọ́, èmi ó sì mú un bí sí i, yóò sì pọ̀ sí i, òun yóò sì jẹ́ baba fún àwọn ọmọ ọba méjìlá, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò sì sọ ọ́ di orílẹ̀-èdè ńlá.

  3. Ṣùgbọ́n èmi yóò fi ìdí májẹ̀mú mi múlẹ̀ pẹ̀lú Isaaki, ẹni tí Sara yóò bí fún ọ ni ìwòyí àmọ́dún.”

  4. Nígbà náà ni ó súre fún Josẹfu wí pé, “Ǹjẹ́ kí Ọlọ́run, ẹni tí baba mi Abrahamu àti Isaaki rìn níwájú rẹ̀, Ọlọ́run tí ó ti jẹ́ olùtọ́jú àti aláàbò mi ní gbogbo ọjọ́ ayé mi títí di òní,

  5. Angẹli tí ó dá mi ní ìdè kúrò lọ́wọ́ gbogbo ewu, kí ó súre fún àwọn ọmọkùnrin wọ̀nyí. Kí a máa fi orúkọ mi pè wọ́n àti orúkọ àwọn baba mi Abrahamu àti Isaaki, kí wọn kí ó sì pọ̀ sí i lọ́pọ̀lọ́pọ̀ lórí ilẹ̀ ayé.”

  6. Nígbà tí Josẹfu rí i pé baba òun gbé ọwọ́ ọ̀tún lé Efraimu lórí, inú rẹ̀ bàjẹ́, ó sì gbá ọwọ́ baba rẹ̀ mú láti gbé ọwọ́ rẹ̀ kúrò lórí Efraimu lọ sí orí Manase.

  7. Josẹfu wí fun pé, “Rárá, baba mi, èyí ni àkọ́bí, orí rẹ̀ ni kí ìwọ kí o gbé ọwọ́ ọ̀tún rẹ lé.”

  8. Ṣùgbọ́n baba rẹ̀ kò gbà, ó wí pé, “Mo mọ̀, ọmọ mi, mo mọ̀. Òun náà yóò di orílẹ̀-èdè, òun náà yóò sì di ńlá. Ṣùgbọ́n àbúrò rẹ̀ yóò di ẹni ńlá jù ú lọ, irú-ọmọ rẹ yóò sì di ọ̀pọ̀lọpọ̀ orílẹ̀-èdè.”

  9. Ó súre fún wọn lọ́jọ́ náà pé, “Ní orúkọ yín ni Israẹli yóò máa súre yìí pé, ‘Kí Ọlọ́run ṣe ọ́ bí i ti Efraimu àti Manase.’ ” Ó sì gbé Efraimu gẹ́gẹ́ bí ẹ̀gbọ́n sí Manase.

  10. Olúwa sọ fún Mose pé, “Ka gbogbo àkọ́bí ọmọkùnrin Israẹli láti ọmọ oṣù kan ó lé kí o sì ṣe àkọsílẹ̀ orúkọ wọn.

  11. Kí o sì gba àwọn ọmọ Lefi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli, kí o sì gba gbogbo ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Lefi fún mi dípò gbogbo àkọ́bí àwọn ẹran ọ̀sìn àwọn ọmọ Israẹli. Èmi ni Olúwa.”

  12. Mose sì ka gbogbo àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  13. Àpapọ̀ iye àwọn àkọ́bí ọkùnrin láti ọmọ oṣù kan ó lé, ní àkọsílẹ̀ orúkọ wọn jẹ́ ẹgbẹ̀rún méjìlélógún ó lé ọ̀rìnlúgba ó dín méje (22,273).

  14. Owó tí a fi ra àwọn àkọ́bí ọmọ Israẹli tó lé yìí, ni kí o kó fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀.”

  15. Nígbà náà ni Mose gba owó ìràpadà àwọn ènìyàn tó ṣẹ́kù lẹ́yìn tí àwọn ọmọ Lefi ti ra àwọn yòókù padà.

  16. Mose sì gba egbèje ṣékélì ó dín márùndínlógójì (1,365) gẹ́gẹ́ bí iye ṣékélì ibi mímọ́ lọ́wọ́ àkọ́bí àwọn ọmọ Israẹli.

  17. Mose sì kó owó ìràpadà yìí fún Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún un.

  18. Nígbà tí wọ́n dé, Samuẹli rí Eliabu, ó rò nínú ara rẹ̀ pé lóòótọ́ ẹni òróró Olúwa dúró níbí níwájú Olúwa.

  19. Ṣùgbọ́n Olúwa sọ fún Samuẹli pé, “Má ṣe wo ti ìrísí rẹ̀ tàbí ti gíga rẹ̀, nítorí èmi ti kọ̀ ọ́ sílẹ̀. Olúwa kì í wo ohun tí ènìyàn máa ń wò. Ènìyàn máa ń wo òde ara ṣùgbọ́n Olúwa máa ń wo ọkàn.”

  20. Nígbà náà ni Jese pe Abinadabu, ó sì jẹ́ kí ó rìn kọjá ní iwájú Samuẹli. Ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí.”

  21. Jese sì jẹ́ kí Ṣamma rìn kọjá ní iwájú Samuẹli, ṣùgbọ́n Samuẹli wí pé, “Olúwa kò yan ẹni yìí náà.”

  22. Jese jẹ́ kí àwọn ọmọ rẹ̀ méje rìn kọjá ní iwájú Samuẹli ṣùgbọ́n Samuẹli sọ fún un pé, “Olúwa kò yan àwọn wọ̀nyí.”

  23. Nígbà náà ni ó béèrè lọ́wọ́ Jese pé, “Ṣé èyí ni gbogbo àwọn ọmọ rẹ?” Jese dáhùn pé, “Ó ku àbíkẹ́yìn wọn, ó ń tọ́jú agbo àgùntàn.” Samuẹli sì wí pé, “Rán ìránṣẹ́ lọ pè é wá; àwa kò ní jókòó títí òun yóò fi dé.”

  24. Ó sì ránṣẹ́ sí i, wọ́n sì mú un wọlé wá, ó jẹ́ ẹni tó mọ́ra, àwọ̀ ara rẹ̀ dùn ún wò, ó jẹ́ arẹwà gidigidi. Nígbà náà ni Olúwa wí pé, “Dìde kí o sì fi òróró yàn án, òun ni ẹni náà.”

  25. wọ́n wí pé, “Olùkọ́, Mose wí fún wa pé, bí ọkùnrin kan bá kú ní àìlọ́mọ, kí arákùnrin rẹ̀ ṣú aya rẹ̀ lópó, kí ó sì bí ọmọ fún un.