Fò sí àkóónú

Israel

1,007 ẹsẹ · 20 ọmọ ẹbí

A tún mọ̀ ọ́n sí: Jacob

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Israel

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ó sì gbà wọ́n ní ọwọ́ wọn, ó sì fi ṣe ohun ọnà fínfín, ó sì dà á ní àwòrán ẹgbọrọ màlúù. Nígbà náà ni wọn wí pé, “Israẹli, wọ̀nyí ni òrìṣà, ti ó mú un yín jáde wá láti Ejibiti.”

  2. Wọ́n ti yí kánkán kúrò nípa ọ̀nà tí mo ti mo pàṣẹ fún wọn, wọ́n sì ti dá ère ẹgbọrọ màlúù fún ara wọn. Wọ́n ti foríbalẹ̀ fún un, wọ́n sì ti rú ẹbọ sí i, wọ́n sì ti sọ pé, ‘Israẹli wọ̀nyí ní òrìṣà tí ó mú un yín jáde láti Ejibiti wá.’ ”

  3. Rántí àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ Abrahamu, Isaaki àti Israẹli, ẹni tí ìwọ búra fún fúnra rẹ̀, ‘Tí o wí fún wọn pé, Èmi yóò mú irú-ọmọ rẹ pọ̀ bí ìràwọ̀ ojú ọ̀run, Èmi yóò sì fún irú-ọmọ rẹ ní gbogbo ilẹ̀ tí mo ti pinnu fún wọn, yóò sì jẹ́ ogún ìní wọn láéláé.’ ”

  4. Ó sì gbé ẹgbọrọ màlúù tí wọ́n ṣe, ó sì fi iná jó wọn; ó sì lọ̀ wọ́n kúnná, ó dà á sínú omi, ó sì mú àwọn ọmọ Israẹli mu ún.

  5. Nígbà náà ni ó sọ fún wọn pé, “Èyí ni Olúwa, Ọlọ́run Israẹli, wí pé, ‘Kí olúkúlùkù ọkùnrin kí ó kọ idà rẹ̀ sí ẹ̀gbẹ́ rẹ̀. Ẹ lọ padà, kí ẹ jà láti àgọ́ kan dé òmíràn, olúkúlùkù kí ó pa arákùnrin rẹ̀ ọ̀rẹ́ rẹ̀ àti aládùúgbò rẹ.’ ”

  6. Olúwa sọ fún Mose pé, “Fi ìhín yìí sílẹ̀, ìwọ àti àwọn ènìyàn tí o mú gòkè láti Ejibiti wá, kí ẹ sì gòkè lọ sí ilẹ̀ tí Èmi ti pinnu ní ìbúra fún Abrahamu, Isaaki àti Jakọbu wí pé, ‘Èmi yóò fi fún irú-ọmọ rẹ.’

  7. Nítorí Olúwa ti wí fún Mose pé, “Sọ fún àwọn ọmọ Israẹli pé, ‘Ènìyàn Ọlọ́rùn líle ní ẹ̀yin, bí Èmi bá lè wá sí àárín yín ni ìṣẹ́jú kan, Èmi lè pa yín run. Nísìnsinyìí, bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ rẹ kúrò, Èmi yóò sì gbèrò ohun tí Èmi yóò ṣe pẹ̀lú rẹ.’ ”

  8. Bẹ́ẹ̀ àwọn ọmọ Israẹli bọ́ ohun ọ̀ṣọ́ wọn kúrò lára wọn ní òkè Horebu.

  9. Ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta lọ́dún, gbogbo àwọn ọkùnrin ni kí ó farahàn níwájú Olúwa Olódùmarè, Ọlọ́run Israẹli.

  10. Olúwa sì wí fún Mose pé, “Kọ àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí sílẹ̀, nítorí nípa àwọn ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ni Èmi bá ìwọ àti Israẹli dá májẹ̀mú.”

  11. Nígbà tí Aaroni àti gbogbo àwọn ọmọ Israẹli rí Mose, ojú rẹ̀ ń dán, ẹ̀rù sì ń bà wọ́n láti súnmọ́ ọn.

  12. Lẹ́yìn èyí gbogbo àwọn ọmọ Israẹli súnmọ́ ọn, ó sì fún wọn ní gbogbo àṣẹ tí Olúwa fún un lórí òkè Sinai.

  13. Ṣùgbọ́n nígbàkígbà tí Mose bá wà níwájú Olúwa láti bá a sọ̀rọ̀, á ṣí ìbòjú náà títí yóò fi jáde. Nígbà tí ó bá sì jáde, á sì sọ fún àwọn ọmọ Israẹli ohun tí a ti pàṣẹ fún un,

  14. àwọn ọmọ Israẹli sì rí i pé ojú rẹ̀ ń dán. Mose á sì tún fi ìbòjú bo ojú rẹ̀ títí á fi lọ bá Olúwa sọ̀rọ̀.

  15. Mose pe gbogbo ìjọ Israẹli ó sì wí fún wọn pé, “Wọ̀nyí ni àwọn ohun ti Olúwa ti pàṣẹ fún un yín láti ṣe.

  16. Mose sọ fún gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa pàṣẹ.

  17. Gbogbo ìjọ àwọn ọmọ Israẹli sì kúrò níwájú Mose,

  18. Gbogbo àwọn ènìyàn Israẹli ọkùnrin àti obìnrin ẹni tí ó fẹ́ mú ọrẹ àtinúwá fún Olúwa fún gbogbo iṣẹ́ tí Olúwa ti pàṣẹ fún wọn láti ṣe nípasẹ̀ Mose.

  19. Nígbà náà ni Mose wí fún àwọn ọmọ Israẹli pé, “Wò ó, Olúwa ti yan Besaleli ọmọ Uri, ọmọ Huri, ti ẹ̀yà Juda,

  20. Wọ́n gba gbogbo ọrẹ tí àwọn ọmọ Israẹli ti mú wá lọ́wọ́ Mose fún kíkọ́ ibi mímọ́ náà. Àwọn ènìyàn sì ń mú ọrẹ àtinúwá wá ní àràárọ̀.

  21. Ó ṣiṣẹ́ òkúta óníkìsì tí a tò sí ojú ìdè wúrà, tí a sì fín wọn gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ àwọn ọmọ Israẹli.

  22. Ó sì so wọ́n mọ́ aṣọ èjìká ẹ̀wù efodu náà bí òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  23. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

  24. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  25. Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.