God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Kí ó fi omi sàn nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì sun gbogbo rẹ̀ lórí pẹpẹ, ó jẹ́ ọrẹ ẹbọ sísun, ọrẹ ẹbọ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
kí ó pa á ní apá àríwá pẹpẹ níwájú Olúwa, kí àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ yí gbogbo ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ náà ká.
Kí ó fi omi ṣan nǹkan inú àti àwọn ẹsẹ̀ rẹ̀, kí àlùfáà sì gbé gbogbo rẹ̀ wá láti sun lórí pẹpẹ. Ó jẹ́ ẹbọ sísun tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
“ ‘Bí ó bá sì ṣe pé ti ẹyẹ ni ẹbọ sísun ọrẹ ẹbọ rẹ̀ sí Olúwa, ǹjẹ́ kí ó mú ọrẹ ẹbọ rẹ̀ wá nínú àdàbà tàbí ọmọ ẹyẹlé.
Kí ó gbá apá rẹ̀ méjèèjì mú, kí ó fà á ya, ṣùgbọ́n kí ó má ya á tan pátápátá. Lẹ́yìn náà ni àlùfáà yóò sun ún lórí igi tí ó ń jó lórí pẹpẹ, ẹbọ sísun ni ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
“ ‘Bí ẹnìkan bá mú ọrẹ ẹbọ ohun jíjẹ wá fún Olúwa ọrẹ rẹ̀ gbọdọ̀ jẹ́ ìyẹ̀fun dáradára, kí ó da òróró sí i, kí o sì fi tùràrí sí i,
kí ó sì gbé lọ fún àwọn ọmọ Aaroni tí í ṣe àlùfáà. Àlùfáà yóò bu ẹ̀kúnwọ́ kan nínú ìyẹ̀fun àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí kí ó sì sun ún gẹ́gẹ́ bí ẹbọ ìrántí lórí pẹpẹ, ọrẹ tí a fi iná ṣe, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ náà jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ ìpín tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
Mú ọrẹ ohun jíjẹ tí a fi àwọn nǹkan wọ̀nyí ṣe wá fún Olúwa gbé e fún àlùfáà, ẹni tí yóò gbe e lọ sí ibi pẹpẹ.
Àlùfáà yóò sì mú ẹbọ ìrántí nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí, yóò sì sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
Ìyókù nínú ọrẹ ohun jíjẹ yìí jẹ́ ti Aaroni àti àwọn ọmọ rẹ̀, ó jẹ́ èyí tí ó mọ́ jùlọ nínú ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
“ ‘Gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ tí ẹ bá mú wá fún Olúwa kò gbọdọ̀ ní ìwúkàrà nínú, nítorí pé ẹ kò gbọdọ̀ sun ohun wíwú tàbí oyin nínú ọrẹ tí ẹ fi iná sun sí Olúwa.
Ẹ lè mú wọn wá fún Olúwa gẹ́gẹ́ bí ọrẹ àkọ́so ṣùgbọ́n ẹ kò gbọdọ̀ mú wọn wá sórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí òórùn dídùn.
Ẹ fi iyọ̀ dun gbogbo ọrẹ ohun jíjẹ yín. Ẹ má ṣe aláìfi iyọ̀ májẹ̀mú Ọlọ́run yín sínú àwọn ọrẹ ohun jíjẹ yín, ẹ fi iyọ̀ sí gbogbo ọrẹ yín.
“ ‘Bí ẹ bá mú ọrẹ ohun jíjẹ ti àkọ́so oko yín wá fún Olúwa kí ẹ mú ọkà tuntun tí a fi iná yan.
Àlùfáà yóò sun ẹbọ ìrántí lára ọkà àti òróró náà, pẹ̀lú gbogbo tùràrí gẹ́gẹ́ bí ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
“ ‘Bí ọrẹ ẹnìkan bá jẹ́ ọrẹ àlàáfíà, tí ó sì mú ẹran wá láti inú agbo màlúù yálà akọ tàbí abo, kí ó mú èyí tí kò ní àbùkù wá síwájú Olúwa.
Láti ara ọrẹ àlàáfíà ni kí ẹni náà ti mú ẹbọ tí a fi iná sun sí Olúwa, gbogbo ọ̀nà tí ó bo nǹkan inú ẹran náà àti gbogbo ọ̀rá tí ó so mọ́ wọn.
Nígbà náà ni àwọn ọmọ Aaroni yóò sun ún lórí pẹpẹ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sísun tí a fi iná sun, àní òórùn dídùn sí Olúwa.
“ ‘Bí ó bá ṣe inú agbo ewúrẹ́ àti àgùntàn ni ó ti mú ọrẹ àlàáfíà wá fún Olúwa kí ó mú akọ tàbí abo tí kò ní àbùkù.
Bí ó bá ṣe pé ọ̀dọ́-àgùntàn ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
Kí o sì mú wá nínú ẹbọ àlàáfíà náà, fún ẹbọ tí a fi iná ṣe sí Olúwa; ọ̀rá rẹ̀ àti gbogbo ìrù rẹ̀ tí ó ní ọ̀rá, òun ni kí o mú kúrò súnmọ́ egungun ẹ̀yìn àti ọ̀rá tí ó bo ìfun lórí; àti gbogbo ọ̀rá tí ń bẹ lára ìfun.
Kí àlùfáà sun ún lórí pẹpẹ bí oúnjẹ ọrẹ tí a fi iná sun sí Olúwa.
“ ‘Bí ó bá ṣe pé ewúrẹ́ ni ó mú, kí ó mú un wá síwájú Olúwa.
Lára ọrẹ tó mú wá, kí ó mú ẹbọ sísun fún Olúwa, gbogbo ọ̀rá tí ó bo nǹkan inú rẹ̀ àti ohun gbogbo tó so mọ́ ọn.