Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ago àti pomegiranate kọjú sí àyíká ìṣẹ́tí ọ̀já àmùrè láti máa wọ̀ ọ́ fún iṣẹ́ àlùfáà, bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  2. Ọ̀já náà jẹ́ ti ọ̀gbọ̀ olókùn dáradára, aṣọ aláró, elése àlùkò àti òdòdó tí a fi iṣẹ́ abẹ́rẹ́ ṣe bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  3. Ó ṣe àwo, adé mímọ́, láti ara kìkì wúrà, wọ́n sì kọ̀wé sí i, gẹ́gẹ́ bí i ìkọ̀wé lórí èdìdì: Mímọ́ sí Olúwa.

  4. Wọ́n sì so ọ̀já aláró mọ́ ọn láti ṣo ó mọ́ fìlà náà, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  5. Bẹ́ẹ̀ ni gbogbo iṣẹ́ àgọ́ náà, ti àgọ́ àjọ parí. Àwọn ọmọ Israẹli ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  6. Àwọn ọmọ Israẹli ti ṣe gbogbo iṣẹ́ náà gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  7. Mose bẹ iṣẹ́ náà wò, ó sì rí i wí pé wọ́n ti ṣe é gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ. Nítorí náà Mose sì bùkún fún wọn.

  8. Olúwa sì wí fún Mose pé,

  9. Nígbà náà wọ Aaroni ní aṣọ mímọ́, ta òróró sí i ní orí, kí o sì yà á sí mímọ́, nítorí kí ó lè máa sìn mi bí àlùfáà.

  10. Ta òróró sí wọn ní orí gẹ́gẹ́ bí o ti ta òróró sí baba wọn ní orí, nítorí kì wọn lè máa sìn mi bí àlùfáà. Ìtasórí wọn yóò jẹ́ iṣẹ́ àlùfáà ti yóò máa lò fún gbogbo ìrandíran tó ń bọ̀.”

  11. Mose ṣe ohun gbogbo gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún un.

  12. Ó na aṣọ àgọ́ náà sórí àgọ́, ó sì fi ìbòrí bo orí àgọ́ náà, bí Olúwa ṣe pàṣẹ fún Mose.

  13. Ó sì gbé àpótí náà wá sínú àgọ́; ó sì sọ aṣọ títa, ó sì ta á bo àpótí ẹ̀rí, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  14. ó sì to àkàrà sórí rẹ̀ níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  15. Ó sì tan àwọn fìtílà náà níwájú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  16. ó sì jó tùràrí dídùn lórí rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  17. Ó gbé pẹpẹ ẹbọ sísun sí ẹ̀gbẹ́ ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ, ó sì rú ẹbọ sísun àti ẹbọ oúnjẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  18. Wọ́n máa ń wẹ̀ nígbàkígbà tí wọ́n bá wọ àgọ́ àjọ tàbí tí wọ́n bá súnmọ́ pẹpẹ, gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pàṣẹ fún Mose.

  19. Nígbà náà ni àwọsánmọ̀ bo àgọ́ àjọ, ògo Olúwa bo àgọ́ náà.

  20. Mose kò sì lè wọ inú àgọ́ àjọ, nítorí àwọsánmọ̀ wà ní orí àgọ́, ògo Olúwa sì ti kún inú àgọ́ náà.

  21. Nítorí náà àwọsánmọ̀ Olúwa wà lórí àgọ́ ní ọ̀sán, iná sì wà nínú àwọsánmọ̀ ní alẹ́, ní ojú gbogbo ilé Israẹli ní gbogbo ìrìnàjò wọn.

  22. Olúwa sì pe Mose, ó sì bá a sọ̀rọ̀ láti inú àgọ́ àjọ. Ó wí pé,

  23. “Bá àwọn ọmọ Israẹli sọ̀rọ̀ kí o sì wí fún wọn pé, ‘Bí ẹnikẹ́ni nínú yín bá mú ọrẹ ẹbọ wá fún Olúwa, kí ọrẹ ẹbọ yín jẹ́ ẹran ọ̀sìn láti inú agbo ẹran tàbí láti inú ọ̀wọ́ ẹran.

  24. “ ‘Bí ọrẹ ẹbọ náà bá jẹ́ ẹbọ sísun láti inú agbo ẹran kí òun kí ó mú akọ màlúù tí kò lábùkù. Ó sì gbọdọ̀ mú un wá sí ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ kí ó ba à lè jẹ́ ìtẹ́wọ́gbà níwájú Olúwa

  25. Kí ó pa ọ̀dọ́ akọ màlúù náà níwájú Olúwa, lẹ́yìn náà ni àwọn àlùfáà tí í ṣe ọmọ Aaroni yóò gbé ẹ̀jẹ̀ ẹran náà, wọn yóò sì wọ́n ẹ̀jẹ̀ náà yí pẹpẹ tí ó wà ní ẹnu-ọ̀nà àgọ́ àjọ ká.