Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ̀yin yóò fi orúkọ yín sílẹ̀ fún àwọn àyànfẹ́ mi gẹ́gẹ́ bí ègún; Olúwa Olódùmarè yóò sì pa yín, ṣùgbọ́n fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ ni òun yóò fún ní orúkọ mìíràn.

  2. Ẹnikẹ́ni tí ó bá gbàdúrà ìbùkún ní ilẹ̀ náà yóò ṣe é nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́; Ẹni tí ó bá búra ní ilẹ̀ náà yóò búra nípasẹ̀ Ọlọ́run òtítọ́. Nítorí ìyọnu àtijọ́ yóò di ìgbàgbé yóò sì fi ara sin kúrò lójú mi.

  3. “Kíyèsi i, Èmi yóò dá àwọn ọ̀run tuntun àti ayé tuntun. A kì yóò rántí ohun àtẹ̀yìnwá mọ́, tàbí kí wọn wá sí ọkàn.

  4. Ṣùgbọ́n ẹ yọ̀ kí inú yín dùn títí láé nínú ohun tí èmi yóò dá, nítorí èmi yóò dá Jerusalẹmu láti jẹ́ ohun ìdùnnú àti àwọn ènìyàn rẹ̀, ohun ayọ̀.

  5. Èmi yóò ṣe àjọyọ̀ lórí Jerusalẹmu n ó sì ní inú dídùn nínú àwọn ènìyàn mi; ariwo ẹkún àti igbe ni a kì yóò gbọ́ nínú rẹ̀ mọ́.

  6. Wọn kì yóò kọ́ ilé fún ẹlòmíràn láti gbé, tàbí kí wọn gbìn fún ẹlòmíràn láti jẹ. Nítorí gẹ́gẹ́ bí ọjọ́ orí igi kan, bẹ́ẹ̀ ní ọjọ́ àwọn ènìyàn mi yóò rí; àwọn àyànfẹ́ mi yóò jẹ iṣẹ́ ọwọ́ wọn fún ìgbà pípẹ́.

  7. Wọn kì yóò ṣe iṣẹ́ lásán, wọn kí yóò bímọ fún wàhálà; nítorí wọn yóò jẹ́ àwọn ènìyàn ti Olúwa bùkún fún, àwọn àti àwọn ìrandíran wọn pẹ̀lú wọn.

  8. Kí wọn tó pè, èmi yóò dáhùn; nígbà tí wọ́n sì ń sọ̀rọ̀ lọ́wọ́, èmi yóò gbọ́.

  9. Ìkookò àti ọ̀dọ́-àgùntàn yóò jẹun pọ̀, kìnnìún yóò sì jẹ koríko gẹ́gẹ́ bí akọ màlúù, ṣùgbọ́n erùpẹ̀ ni yóò jẹ́ oúnjẹ ejò. Wọn kì yóò pa ni lára tàbí pa ni run ní gbogbo òkè mímọ́ mi,” ni Olúwa wí.

  10. Báyìí ni Olúwa wí: “Ọ̀run ni ìtẹ́ mi, ayé sì ni àpótí ìtìsẹ̀ mi. Níbo ni ilé tí ẹ ó kọ́ fún mi wà? Níbo ní ibi ìsinmi mi yóò gbé wà?

  11. Kì í ha á ṣe ọwọ́ mi ló tí ṣe nǹkan wọ̀nyí, bẹ́ẹ̀ ni wọ́n sì wà?” ni Olúwa wí. “Eléyìí ni ẹni tí mo kà sí: ẹni náà tí ó rẹra rẹ̀ sílẹ̀ tí ó sì kẹ́dùn ní ọkàn rẹ̀, tí ó sì wárìrì sí ọ̀rọ̀ mi.

  12. fún ìdí èyí ni èmi pẹ̀lú yóò ṣe fi ọwọ́ líle mú wọn n ó sì mú ohun tí wọ́n bẹ̀rù rẹ̀ wá sórí wọn. Nítorí nígbà tí mo pè, kò sí ẹni tí ó dáhùn, nígbà tí mo sọ̀rọ̀, ẹnikẹ́ni kò tẹ́tí sílẹ̀. Wọ́n ṣe ohun búburú ní ojú mi wọ́n sì yan ohun tí mo kórìíra rẹ̀.”

  13. Ẹ gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ ń wárìrì nípasẹ̀ ọ̀rọ̀ rẹ̀: “Àwọn arákùnrin yín tí wọ́n kórìíra yín, tí wọ́n ta yín nù nítorí orúkọ mi, wí pé, ‘Jẹ́ kí a yin Olúwa lógo, kí a le rí ayọ̀ yín!’ Ṣùgbọ́n àwọn ni ojú yóò tì.

  14. Gbọ́ rògbòdìyàn láti ìlú wá, gbọ́ ariwo náà láti tẹmpili wá! Ariwo tí Olúwa ní í ṣe tí ó ń san án fún àwọn ọ̀tá rẹ̀ ohun tí ó tọ́ sí wọn.

  15. Ǹjẹ́ èmi a ha máa mú wá sí ìrọbí kí èmi má sì mú ni bí?” ni Olúwa wí. “Ǹjẹ́ èmi a ha máa ṣé ilé ọmọ nígbà tí mo ń mú ìbí wá?” Ni Ọlọ́run yín wí.

  16. Nítorí báyìí ni Olúwa wí: “Èmi yóò fún un ní àlàáfíà gẹ́gẹ́ bí odò àti ọrọ̀ orílẹ̀-èdè gẹ́gẹ́ bí ìṣàn omi; ẹ̀yin yóò mu ọmú, a ó sì gbé yín ní apá rẹ̀ a ó bá yín ṣeré ní orúkún rẹ̀.

  17. Gẹ́gẹ́ bí ìyá ti í tu ọmọ rẹ̀ nínú, bẹ́ẹ̀ ni èmi yóò tù yín nínú a ó sì tù yín nínú lórí Jerusalẹmu.”

  18. Nígbà tí ẹ bá rí èyí, inú yín yóò dùn ẹ̀yin yóò sì gbilẹ̀ gẹ́gẹ́ bí i koríko; ọwọ́ Olúwa ni a ó sọ di mí mọ̀ fún àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀, ṣùgbọ́n ìbínú rẹ̀ ni a ó fihàn fún àwọn ọ̀tá rẹ̀.

  19. Kíyèsi i, Olúwa ń bọ̀ pẹ̀lú iná àti kẹ̀kẹ́ ogun rẹ̀ tí ó dàbí ìjì líle; òun yóò mú ìbínú rẹ sọ̀kalẹ̀ pẹ̀lú ìrunú, àti ìbáwí rẹ̀ pẹ̀lú ahọ́n iná.

  20. Nítorí pẹ̀lú iná àti idà ni Olúwa yóò ṣe ìdájọ́ lórí i gbogbo ènìyàn, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ ni àwọn tí Olúwa yóò pa.

  21. “Gbogbo àwọn tí wọ́n ya ara wọn sí mímọ́ tí wọ́n sì sọ ara wọn di mímọ́ láti lọ sínú ọgbà, tí wọ́n tẹ̀lé ẹni tí ó wà láàrín àwọn tí ó jẹ ẹran ẹlẹ́dẹ̀ àti èkúté àti àwọn ohun ìríra mìíràn ni wọn yóò bá òpin wọn pàdé papọ̀,” ni Olúwa wí.

  22. “Àti Èmi, nítorí ìgbésẹ̀ wọn àti èrò wọn, èmi ti múra tán láti wá kó àwọn orílẹ̀-èdè àti ahọ́n jọ, wọn yóò sì wá wo ògo mi.

  23. “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.

  24. Wọn yóò sì mú àwọn arákùnrin yín wá, láti gbogbo orílẹ̀-èdè, sí òkè mímọ́ mi ní Jerusalẹmu gẹ́gẹ́ bí ọrẹ sí Olúwa lórí ẹṣin, lórí kẹ̀kẹ́ ẹrù àti ọkọ̀-ẹṣin, àti lórí ìbáaka àti ìbákasẹ,” ni Olúwa wí. “Wọn yóò kó wọn wá, gẹ́gẹ́ bí àwọn ọmọ Israẹli ti mú ọrẹ oníhóró wọn wá, sínú Tẹmpili Olúwa nínú ohun èlò mímọ́.

  25. Àti pé èmi yóò sì yan àwọn kan nínú wọn pẹ̀lú láti jẹ́ àlùfáà àti Lefi,” ni Olúwa wí.