Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n àwa ó fi ìbùkún fún Olúwa láti ìsinsin yìí lọ àti títí láéláé. Ẹ yin Olúwa.

  2. Èmi fẹ́ràn Olúwa, nítorí ó gbọ́ ohùn mi; ó gbọ́ ẹkún mi fún àánú.

  3. Nítorí ó yí etí rẹ̀ padà sí mi, èmi yóò máa pè é ni wọ́n ìgbà tí mo wà láààyè.

  4. Nígbà náà ni mo ké pe orúkọ Olúwa: “Olúwa, èmi bẹ̀ ọ́, gba ọkàn mi!”

  5. Olúwa ní oore-ọ̀fẹ́, ó sì ní òdodo; Ọlọ́run wa kún fún àánú.

  6. Olúwa pa àwọn ọlọ́kàn fífúyẹ́ mọ́ nígbà tí mo wà nínú àìní ńlá, ó gbà mí.

  7. Padà, ìwọ ọkàn mi, sí ibi ìsinmi rẹ, nítorí Olúwa ṣe dáradára sí ọ.

  8. Nítorí ìwọ, Olúwa, ti gba ọkàn mi kúrò lọ́wọ́ ikú, ojú mi kúrò lọ́wọ́ omijé, àti ẹsẹ̀ mi kúrò lọ́wọ́ ìṣubú,

  9. nítorí èmi yóò máa rìn níwájú Olúwa ní ilẹ̀ alààyè.

  10. Kí ni èmi yóò san fún Olúwa nítorí gbogbo rere rẹ̀ sí mi?

  11. Èmi yóò gbé ago ìgbàlà sókè èmi yóò sì máa ké pe orúkọ Olúwa.

  12. Èmi yóò mú ìlérí mi ṣẹ sí Olúwa ní ojú àwọn ènìyàn rẹ̀.

  13. Iyebíye ní ojú Olúwa àti ikú àwọn ẹni mímọ́ rẹ̀.

  14. Olúwa, nítòótọ́ ìránṣẹ́ rẹ ni mo jẹ́; èmi ni ìránṣẹ́ rẹ, ọmọ ìránṣẹ́bìnrin rẹ; ó ti tú mi sílẹ̀ nínú ìdè mi.

  15. Èmi yóò rú ẹbọ ọpẹ́ sí ọ èmi yóò sì ké pe orúkọ Olúwa.

  16. Èmi yóò mú ìlérí mi sẹ sí Olúwa ní ojú gbogbo àwọn ènìyàn rẹ̀,

  17. nínú àgbàlá ilé Olúwa ní àárín rẹ̀, ìwọ Jerusalẹmu. Ẹ yin Olúwa.

  18. Ẹ yin Olúwa, gbogbo ẹ̀yin orílẹ̀-èdè; ẹ pòkìkí rẹ̀, gbogbo ẹ̀yin ènìyàn.

  19. Nítorí ìfẹ́ ńlá rẹ̀ tí ó ní sí wa, àti òtítọ́ Olúwa dúró láéláé. Ẹ yin Olúwa!

  20. Ẹ fi ọpẹ́ fún Olúwa, nítorí tí ó dára; àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  21. Jẹ́ kí Israẹli wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

  22. Jẹ́ kí ilé Aaroni wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé”.

  23. Jẹ́ kí àwọn tí ó bẹ̀rù Olúwa wí pé: “Àánú rẹ̀ dúró láéláé.”

  24. Nínú ìrora mi, mo sọkún sí Olúwa, ó sì dá mi lóhùn nípa pé ó tú mi sílẹ̀.

  25. Olúwa ń bẹ fún èmi; èmi kì yóò bẹ̀rù. Kí ni ènìyàn lè ṣe sí mi?