God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Nípasẹ̀ Ọlọ́run ni àwa ó ṣe akin nítorí òun ó tẹ àwọn ọ̀tá wa mọ́lẹ̀.
Fún adarí orin. Ti Dafidi. Saamu. Ọlọ́run, ti èmi ń fi ìyìn fún, má ṣe dákẹ́,
Yan àwọn ènìyàn búburú láti dojúkọ jẹ́ kí àwọn olùfisùn dúró ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀.
Kí ẹ̀ṣẹ̀ àwọn baba rẹ̀ kí ó wà ní ìrántí ní ọ̀dọ̀ Olúwa. Má ṣe jẹ́ kí a yọ ẹ̀ṣẹ̀ ìyá wọn kúrò.
Jẹ́ kí ẹ̀ṣẹ̀ wọn kí ó wà ní ìrántí níwájú Olúwa kí ó lè gé ìrántí wọn kúrò lórí ilẹ̀.
Èyí ni èrè àwọn ọ̀tá mi láti ọwọ́ Olúwa wá; àti ti àwọn tí ń sọ̀rọ̀ ibi sí ọkàn mi.
Ṣùgbọ́n ìwọ, ìwọ ṣe fún mi Olúwa Olódùmarè, ṣe rere fún mi nítorí orúkọ rẹ. Nítorí tí àánú rẹ dára, ìwọ gbà mí.
Ràn mí lọ́wọ́, Olúwa Ọlọ́run mi; gbà mí gẹ́gẹ́ bí ìṣeun ìfẹ́ rẹ.
Jẹ́ kí wọn mọ̀ pé ọwọ́ rẹ ni èyí wí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ṣe é.
Wọ́n ó máa gégùn ún, ṣùgbọ́n ìwọ máa súre, nígbà tí wọn bá dìde kí ojú kí ó tì wọ́n, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ yóò yọ̀.
Pẹ̀lú ẹnu mi èmi yóò máa yin Olúwa gidigidi ní àárín ọ̀pọ̀ ènìyàn èmi yóò máa yìn ín.
Nítorí ó dúró ní apá ọ̀tún aláìní láti gbà á lọ́wọ́ àwọn tí ń dá ọkàn rẹ̀ lẹ́bi.
Ti Dafidi. Saamu. Olúwa sọ fún Olúwa mi pé, “Ìwọ jókòó ní ọwọ́ ọ̀tún mi, títí èmi yóò fi sọ àwọn ọ̀tá rẹ di àpótí ìtìsẹ̀ rẹ.”
Olúwa yóò na ọ̀pá agbára rẹ̀ láti Sioni wá, ìwọ jẹ ọba láàrín àwọn ọ̀tá rẹ.
Àwọn ènìyàn rẹ jẹ́ ọ̀rẹ́ àtinúwá ní ọjọ́ ìjáde ogun rẹ, nínú ẹwà mímọ́, láti inú òwúrọ̀ wá ìwọ ni ìrì ẹwà rẹ.
Olúwa ti búra, kò sì í yí ọkàn padà pé, “Ìwọ ni àlùfáà, ní ipasẹ̀ Melkisedeki.”
Olúwa, ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ ni yóò lu àwọn ọba bolẹ̀ ni ọjọ́ ìbínú rẹ̀.
Ẹ máa yin Olúwa. Èmi yóò máa yin Olúwa pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi, ní àwùjọ àwọn olóòtítọ́, àti ní ìjọ ènìyàn.
Iṣẹ́ Olúwa tóbi, àwọn tí ó ní inú dídùn, ń ṣe àṣàrò nínú rẹ̀.
Iṣẹ́ rẹ̀ ni ọláńlá àti ògo: àti òdodo rẹ̀ dúró láéláé.
Ó ti ṣe iṣẹ́ ìyanu rẹ̀, láti máa rántí: Olúwa ni olóore-ọ̀fẹ́ àti pé ó kún fún àánú.
Ó ti fi oúnjẹ fún àwọn tí ó bẹ̀rù rẹ̀: òun ń rántí májẹ̀mú rẹ̀.
Ó ti fihan àwọn ènìyàn rẹ̀ agbára iṣẹ́ rẹ̀ láti fún wọn ní ilẹ̀ ìlérí ní ìní.
Iṣẹ́ ọwọ́ rẹ̀ jẹ́ òtítọ́ àti ìdájọ́; gbogbo òfin rẹ̀ sì dájú.
Ó rán ìràpadà sí àwọn ènìyàn rẹ̀: ó pàṣẹ májẹ̀mú rẹ̀ títí láé, mímọ́ àti ọ̀wọ̀ ni orúkọ rẹ̀.