Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ ti la ìlànà rẹ̀ sílẹ̀ kí a sì pa wọ́n mọ́ gidigidi.

  2. Ọ̀nà mi ìbá dúró ṣinṣin láti máa pa òfin rẹ̀ mọ́!

  3. Nígbà náà, ojú kò ní tì mí nígbà tí mo bá ń kíyèsi àṣẹ rẹ̀ gbogbo.

  4. Èmi yóò yìn ọ́ pẹ̀lú ọkàn ìdúró ṣinṣin bí èmi bá ti kọ́ òfin òdodo rẹ̀.

  5. Èmi yóò gbọ́rọ̀ sí àṣẹ rẹ̀, má ṣe kọ̀ mí sílẹ̀ pátápátá.

  6. Báwo ni àwọn ọ̀dọ́ yóò ti ṣe pa ọ̀nà rẹ̀ mọ́? Láti máa gbé ní ìbámu sí ọ̀rọ̀ rẹ.

  7. Èmi wá ọ pẹ̀lú gbogbo ọkàn mi má ṣe jẹ́ kí èmi yapa kúrò nínú àṣẹ rẹ.

  8. Èmi ti pa ọ̀rọ̀ rẹ mọ́ ní ọkàn mi kí èmi má ba à ṣẹ̀ sí ọ.

  9. Ìyìn ni fún Olúwa; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

  10. Pẹ̀lú ètè mi èmi tún ṣírò gbogbo òfin tí ó wá láti ẹnu rẹ.

  11. Èmi ń yọ̀ ní ọ̀nà ẹ̀rí rẹ, bí ènìyàn ṣe ń yọ̀ nínú ọláńlá.

  12. Èmi ń ṣe àṣàrò nínú ìlànà rẹ èmi sì kíyèsi ọ̀nà rẹ.

  13. Inú mi dùn sí àṣẹ rẹ; èmi kì yóò gbàgbé ọ̀nà rẹ.

  14. Ṣe rere sí ìránṣẹ́ rẹ, èmi yóò sì wà láààyè; èmi yóò ṣe ìgbọ́ràn sí ọ̀rọ̀ rẹ.

  15. La ojú mi kí èmi lè ríran rí ohun ìyanu tí ó wà nínú òfin rẹ.

  16. Àlejò ní èmi jẹ́ láyé, má ṣe pa àṣẹ rẹ mọ́ fún mi.

  17. Ọkàn mi pòruurù pẹ̀lú ìfojúsọ́nà nítorí òfin rẹ nígbà gbogbo.

  18. Ìwọ fi àwọn agbéraga bú, àwọn tí a fi gégùn ún tí ó ṣìnà kúrò nínú àṣẹ rẹ.

  19. Mú ẹ̀gàn àti àbùkù kúrò lára mi, nítorí èmi pa òfin rẹ mọ́.

  20. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé àwọn alákòóso kójọpọ̀, wọ́n ń sọ̀rọ̀ ìbàjẹ́ sí mi, ṣùgbọ́n ìránṣẹ́ rẹ ń ṣe àṣàrò nínú àṣẹ rẹ.

  21. Ọkàn mí lẹ̀ mọ́ erùpẹ̀; ìwọ sọ mí di ààyè gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

  22. Èmi tún ọ̀nà mi ṣírò ìwọ sì dá mi lóhùn; kọ́ mi ní àṣẹ rẹ.

  23. Jẹ́ kí n mọ ẹ̀kọ́ ìlànà rẹ: nígbà náà ni èmi yóò ṣe àṣàrò iṣẹ́ ìyanu rẹ.

  24. Ọkàn mi ń ṣe àárẹ̀ pẹ̀lú ìbànújẹ́; fi agbára fún mi gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

  25. Pa mí mọ́ kúrò nínú ọ̀nà ẹ̀tàn fún mi ní oore-ọ̀fẹ́ nípa òfin rẹ.