Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èmi ti yan ọ̀nà òtítọ́ èmi ti gbé ọkàn mi lé òfin rẹ.

  2. Èmi yára di òfin rẹ mú. Olúwa má ṣe jẹ́ kí ojú kí ó tì mí.

  3. Èmi sáré ní ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ, nítorí ìwọ, ti tú ọkàn mi sílẹ̀.

  4. Kọ́ mi, Olúwa, láti tẹ̀lé àṣẹ rẹ; nígbà náà ni èmi yóò pa wọ́n mọ́ dé òpin.

  5. Fún mi ní òye, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́ èmi yóò sì máa kíyèsi i pẹ̀lú ọkàn mi.

  6. Fi ipa ọ̀nà àṣẹ rẹ hàn mí, nítorí nínú rẹ̀ ni èmi rí inú dídùn.

  7. Yí ọkàn mi padà sí òfin rẹ kí ó má ṣe sí ojúkòkòrò mọ́.

  8. Yí ojú mi padà kúrò láti máa wo ohun asán: pa ọ̀nà mi mọ́ gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ rẹ.

  9. Mú ìlérí rẹ sẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí òfin rẹ dára.

  10. Yí ẹ̀gàn mi padà tí mo bẹ̀rù nítorí tí ìdájọ́ rẹ dára.

  11. Kíyèsi i, ọkàn mi ti fà sí ẹ̀kọ́ rẹ! Pa ayé mi mọ́ nínú òdodo rẹ.

  12. Jẹ́ kí ìfẹ́ rẹ tí kì í kùnà wá bá mi, Olúwa, ìgbàlà rẹ gẹ́gẹ́ bí ìpinnu rẹ.

  13. Nígbà náà ni èmi yóò dá ẹni tí ń sọ̀rọ̀ ẹ̀gàn sí mi lóhùn, nítorí èmi gbẹ́kẹ̀lé ọ̀rọ̀ rẹ.

  14. Má ṣe gba ọ̀rọ̀ òtítọ́ láti ẹnu mi nítorí èmi ti gbé ìrètí mi sínú àṣẹ rẹ.

  15. Èmi yóò máa gbọ́rọ̀ sí òfin rẹ nígbà gbogbo láé àti láéláé.

  16. Èmi yóò máa rìn káàkiri ní òmìnira, nítorí èmi ti kígbe ẹ̀kọ́ rẹ jáde.

  17. Èmi yóò sọ̀rọ̀ òfin rẹ níwájú àwọn ọba ojú kì yóò sì tì mí,

  18. nítorí èmi ní inú dídùn nínú àṣẹ rẹ nítorí èmi ní ìfẹ́ wọn.

  19. Èmi gbé ọwọ́ mi sókè nítorí àṣẹ rẹ, èyí tí èmi fẹ́ràn, èmi sì ń ṣe àṣàrò òfin rẹ̀.

  20. Rántí ọ̀rọ̀ rẹ sí ìránṣẹ́ rẹ, nítorí ìwọ ti fún mi ní ìrètí.

  21. Ìtùnú mi nínú ìpọ́njú mi ni èyí: ìpinnu rẹ pa ayé mi mọ́.

  22. Àwọn agbéraga fi mí ṣe ẹlẹ́yà láì dádúró, ṣùgbọ́n èmi kò padà nínú òfin rẹ.

  23. Èmi rántí àwọn òfin rẹ ìgbàanì, Olúwa, èmi sì rí ìtùnú nínú wọn.

  24. Ìbínú dì mímú ṣinṣin nítorí àwọn ẹni búburú, tí wọ́n ti kọ òfin rẹ sílẹ̀.

  25. Ní òru èmi rántí orúkọ rẹ, Olúwa, èmi yóò sì pa òfin rẹ mọ́