Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.

  2. Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

  3. Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.” A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

  4. Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

  5. Olúwa jẹ ọba, jẹ́ kí ayé kí ó yọ̀ jẹ́ kí inú ọ̀pọ̀lọpọ̀ erékùṣù kí ó dùn.

  6. Ojú ọ̀run àti òkùnkùn yíká òdodo àti ìdájọ́ ni ó ṣe ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìtẹ́ rẹ̀.

  7. Iná ń jó níwájú rẹ̀. Ó sì ń jó àwọn ọ̀tá rẹ̀ yíkákiri.

  8. Òkè gíga yọ́ gẹ́gẹ́ bí ìda níwájú Olúwa, níwájú Olúwa gbogbo ayé.

  9. Àwọn ọ̀run ròyìn òdodo rẹ̀, gbogbo ènìyàn sì rí ògo rẹ̀.

  10. Gbogbo àwọn tí ń sin ère fínfín ni ojú yóò tì, àwọn tí ń fi ère gbéraga, ẹ máa sìn ín, gbogbo ẹ̀yin ọlọ́run!

  11. Sioni gbọ́, inú rẹ̀ sì dùn inú àwọn ilé Juda sì dùn, nítorí ìdájọ́ rẹ, Olúwa.

  12. Nítorí pé ìwọ, Olúwa, ni ó ga ju gbogbo ayé lọ ìwọ ni ó ga ju gbogbo òrìṣà lọ.

  13. Jẹ kí gbogbo àwọn tí ó fẹ́ Olúwa, kórìíra ibi, ó pa ọkàn àwọn ènìyàn mímọ́ rẹ̀ mọ́ ó gbà wọ́n ní ọwọ́ àwọn ènìyàn búburú.

  14. Ẹ yọ̀ nínú Olúwa, ẹ̀yin tí ẹ jẹ́ olódodo, kí ẹ sì yin orúkọ rẹ̀ mímọ́.

  15. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, nítorí tí ó ṣe ohun ìyanu; ọwọ́ ọ̀tún rẹ̀ àti apá mímọ́ rẹ̀ o ṣe iṣẹ́ ìgbàlà fún un

  16. Olúwa ti sọ ìgbàlà rẹ̀ di mí mọ̀ o fi òdodo rẹ̀ han àwọn orílẹ̀-èdè.

  17. Ó rántí ìfẹ́ rẹ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ fún àwọn ará ilé Israẹli; gbogbo òpin ayé ni ó ti rí iṣẹ́ ìgbàlà Ọlọ́run wa.

  18. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé, ẹ bú sáyọ̀, ẹ kọrin ìyìn,

  19. ẹ fi dùùrù kọrin sí Olúwa, pẹ̀lú dùùrù àti ìró ohùn orin mímọ́,

  20. pẹ̀lú ìpè àti fèrè ẹ hó fún ayọ̀ níwájú Olúwa ọba.

  21. ẹ jẹ́ kí wọn kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí yóò wá ṣèdájọ́ ayé bẹ́ẹ̀ ni yóò ṣe ìdájọ́ àwọn orílẹ̀-èdè nínú òdodo àti àwọn ènìyàn ní àìṣègbè pẹ̀lú.

  22. Olúwa jẹ ọba; jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì Ó jókòó lórí ìtẹ́ kérúbù jẹ́ kí ayé kí ó wárìrì.

  23. Olúwa tóbi ní Sioni; Ó sì ga jù gbogbo orílẹ̀-èdè lọ.

  24. Kí wọ́n sì yin orúkọ rẹ̀ tí ó tóbi tí ó ni ẹ̀rù, Mímọ́ ni Òun.

  25. Ọba náà ní agbára, ó sì fẹ́ òdodo, ìwọ fi ìdí àìṣègbè múlẹ̀; ìwọ ṣe ohun tí ó tọ́ àti ohun tí ó yẹ nínú Jakọbu.