Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa ẹ foríbalẹ̀ níbi ẹsẹ̀ rẹ̀; ó jẹ́ mímọ́.

  2. Mose àti Aaroni wà nínú àwọn àlùfáà rẹ̀ Samuẹli wà nínú àwọn tí ó ń ké pe orúkọ rẹ̀ wọ́n ké pe Olúwa, ó sì dá wọn lóhùn.

  3. Ó sọ̀rọ̀ sí wọn nínú ọ̀wọ́n àwọsánmọ̀, wọ́n pa ẹ̀rí rẹ̀ mọ́ àti ìlànà tí ó fún wọn.

  4. Olúwa Ọlọ́run wa, ó dá wọn lóhùn; ó jẹ́ Ọlọ́run tí ó ń dáríjì àwọn ọmọ Israẹli ìwọ tí ó ń fi ìyà àìṣedéédéé wọn jẹ wọ́n.

  5. Gbígbéga ni Olúwa Ọlọ́run wa kí a sìn ín ní òkè mímọ́ rẹ̀ nítorí Olúwa Ọlọ́run wa jẹ́ mímọ́.

  6. Saamu. Fún ọpẹ́. Ẹ hó ìhó ayọ̀ sí Olúwa, gbogbo ayé.

  7. Ẹ fi ayọ̀ sin Olúwa, ẹ wá síwájú rẹ̀ pẹ̀lú orin dídùn

  8. Olúwa Ọlọ́run ni ó dá wa, kí ẹ̀yin kí ó mọ̀ pé tirẹ̀ ni àwa, àwa ní ènìyàn rẹ̀ àti àgùntàn pápá rẹ̀.

  9. Ẹ lọ sí ẹnu-ọ̀nà rẹ̀ pẹ̀lú ọpẹ́ àti sí àgbàlá rẹ̀ pẹ̀lú ìyìn; ẹ fi ọpẹ́ àti ìyìn fún orúkọ rẹ̀.

  10. Nítorí tí Olúwa pọ̀ ní oore ìfẹ́ rẹ̀ sì wà títí láé; àti òtítọ́ rẹ̀ láti ìran de ìran.

  11. Ti Dafidi. Saamu. Èmi yóò kọrin ìfẹ́ àti òdodo; sí ọ Olúwa, èmi yóò máa kọrin ìyìn.

  12. Èmi yóò máa rin ìrìn mi pẹ̀lú ọgbọ́n láìlẹ́ṣẹ̀, ìgbà wo ni ìwọ yóò wá sí ọ̀dọ̀ mi? Èmi yóò máa rìn ní ilé mi pẹ̀lú àyà pípé.

  13. Ní ojoojúmọ́ ní èmi yóò wá máa pa a lẹ́nu mọ gbogbo àwọn ènìyàn búburú ilẹ̀ náà; èmi yóò gé àwọn olùṣe búburú kúrò ní ìlú Olúwa.

  14. Àdúrà olùpọ́njú tí àárẹ̀ mú, tí ó sí ọkàn rẹ̀ payá níwájú Olúwa. Gbọ́ àdúrà mi, Olúwa, jẹ́ kí igbe ẹ̀bẹ̀ mi kí ó wá sí ọ̀dọ̀ rẹ.

  15. Má ṣe pa ojú rẹ mọ́ kúrò lọ́dọ̀ mi ní ọjọ́ tí èmi wà nínú ìpọ́njú. Dẹ etí rẹ sí mi; nígbà tí mo bá pè, dá mi lóhùn kíákíá.

  16. Nítorí ìbínú ríru rẹ, nítorí ìwọ ti gbé mi sókè, ìwọ sì gbé mi ṣánlẹ̀.

  17. Ṣùgbọ́n ìwọ, Olúwa, ni yóò dúró láéláé; ìrántí rẹ láti ìran dé ìran.

  18. Nítorí tí àwọn òkúta jẹ́ inú dídùn sí àwọn ìránṣẹ́ rẹ; wọ́n sì káàánú erùpẹ̀ rẹ.

  19. Àwọn kèfèrí yóò bẹ̀rù orúkọ Olúwa, gbogbo ọba ayé yóò máa bẹ̀rù ògo rẹ.

  20. Torí tí Olúwa yóò gbé Sioni ró, yóò farahàn nínú ògo rẹ̀.

  21. Jẹ́ kí a kọ èyí fún ìran tí ń bọ̀, àwọn ènìyàn tí a kò tí ì dá yóò yin Olúwa:

  22. “Olúwa wo ilẹ̀ láti òkè mímọ́ rẹ̀ wá láti ọ̀run wá ni ó bojú wo ayé,

  23. Kí a lè sọ orúkọ Olúwa ní Sioni àti ìyìn rẹ̀ ní Jerusalẹmu.

  24. Ní ìgbà tí a kó àwọn ènìyàn àti ìjọba pọ̀ láti máa sìn Olúwa.

  25. Ní ipa ọ̀nà mi, ó rẹ agbára mi sílẹ̀, ó gé ọjọ́ mi kúrú.