Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Òun yóò pè mí, èmi yóò sì dá a lóhùn; èmi yóò wà pẹ̀lú rẹ̀ nínú ìpọ́njú, èmi yóò gbà á, èmi yóò sì bu ọlá fún un.

  2. Pẹ̀lú ẹ̀mí gígùn ni èmi yóò fi tẹ́ ẹ lọ́rùn, èmi yóò sì fi ìgbàlà mi hàn án.”

  3. Saamu. Orin. Fún Ọjọ́ Ìsinmi. Ohun rere ni láti máa fi ọpẹ́ fún Olúwa àti láti máa kọrin sí orúkọ rẹ̀, Ọ̀gá-ògo,

  4. láti kéde ìfẹ́ rẹ̀ ní òwúrọ̀ àti òtítọ́ rẹ̀ ní alẹ́,

  5. Nítorí ìwọ ni ó mú inú mi dùn nípa iṣẹ́ rẹ Olúwa; èmi kọrin ayọ̀ sí iṣẹ́ ọwọ́ rẹ.

  6. Báwo ni iṣẹ́ rẹ tí tóbi tó, Olúwa? Èrò inú rẹ ìjìnlẹ̀ ni!

  7. Ṣùgbọ́n ìwọ Olúwa ni a ó gbéga títí láé.

  8. Nítorí nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ, Olúwa, nítòótọ́ àwọn ọ̀tá rẹ yóò ṣègbé; gbogbo àwọn olùṣe búburú ni a ó fọ́nká.

  9. Ìwọ ti gbé ìwo mi ga bí i ti màlúù igbó; òróró dídára ni a dà sí mi ní orí.

  10. tí a gbìn sí ilé Olúwa, Wọn yóò rúwé nínú àgbàlá Ọlọ́run wa.

  11. láti fihàn pé, “Ẹni ìdúró ṣinṣin ni Olúwa; òun ni àpáta mi, kò sì ṣí aburú kankan nínú rẹ̀.”

  12. Olúwa ń jẹ ọba, ọláńlá ni ó wọ̀ ní aṣọ; ọláńlá ni Olúwa wọ̀ ní aṣọ àti ìhámọ́ra rẹ̀ pẹ̀lú agbára. Ó fi ìdí ayé múlẹ̀; kò sì le è yí.

  13. Ìjọba rẹ̀ wà láti ọjọ́ pípẹ́; ìwọ wà títí ayérayé.

  14. A ti gbé òkun sókè, Olúwa, òkun ti gbé ohùn wọn sókè; òkun ti gbé rírú omi wọn sókè.

  15. Ó ni ògo ju àrá omi ńlá lọ, ó ni ògo ju òkun rírú lọ Olúwa ga ní ògo.

  16. Ẹ̀rí rẹ̀ dúró ṣinṣin; ìwà mímọ́ ni ó fi ṣe ilé rẹ̀ lọ́ṣọ̀ọ́ fún ọjọ́ àìlópin, Olúwa.

  17. Olúwa Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san, Ọlọ́run ẹni tí ń gbẹ̀san.

  18. Gbé ara rẹ sókè, ìwọ onídàájọ́ ayé; san ẹ̀san fún agbéraga ohun tí ó yẹ wọ́n.

  19. Báwo ní yóò ti pẹ́ tó, Olúwa tí àwọn ẹni búburú yóò kọ orin ayọ̀?

  20. Wọ́n fọ́ àwọn ènìyàn rẹ túútúú, Olúwa: wọ́n pọ́n ilẹ̀ ìní rẹ̀ lójú.

  21. Wọ́n sọ pé, “Olúwa kò rí i; Ọlọ́run Jakọbu kò sì kíyèsi i.”

  22. Ẹni tí ó gbin etí, ó lè ṣe aláìgbọ́ bí? Ẹni tí ó dá ojú? Ó ha lè ṣe aláìríran bí?

  23. Ẹni tí ń bá orílẹ̀-èdè wí, ṣé kò lè tọ́ ni ṣọ́nà bí? Ẹni tí ń kọ́ ènìyàn ha lè ṣàìní ìmọ̀ bí?

  24. Olúwa mọ èrò inú ènìyàn; ó mọ̀ pé asán ni wọ́n.

  25. Ìbùkún ni fún ènìyàn náà tí ìwọ bá wí, Olúwa, ẹni tí ìwọ kọ́ nínú òfin rẹ,