Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọn ń ṣògo nínú orúkọ rẹ̀ ní gbogbo ọjọ́, wọn ń yin òdodo rẹ.

  2. Nítorí ìwọ ni ògo agbára wọn; nípa ojúrere ni ìwo wá ń ṣògo.

  3. Nítorí ti Olúwa ni asà wa, ọba wa sì ni Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  4. Nígbà náà ni ìwọ sọ̀rọ̀ nínú ìran, sí àwọn olóòtítọ́ rẹ, wí pé, “Èmi ti gbé adé kalẹ̀ sórí ẹni tí ó lágbára, èmi ti gbé ẹni tí a yàn láti ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn ga.

  5. Èmi ti rí Dafidi ìránṣẹ́ mi; pẹ̀lú òróró mímọ́ mi ni mo fi yàn án.

  6. Ìgbà gbogbo ni ọwọ́ mi yóò máa wà pẹ̀lú rẹ̀ apá mí yóò sì fi agbára fún un.

  7. Èmi yóò run àwọn ọ̀tá rẹ níwájú rẹ èmi yóò lu àwọn tí ó kórìíra rẹ bolẹ̀.

  8. Òtítọ́ mi àti ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ yóò wà pẹ̀lú rẹ àti ní orúkọ mi ni a ó gbé ìwo rẹ ga.

  9. Èmi ó gbé ọwọ́ rẹ lórí òkun, àti ọwọ́ ọ̀tún rẹ lórí àwọn odo ńlá.

  10. Òun yóò kígbe sí mi pé, ‘Ìwọ ni baba mi, Ọlọ́run mi, àti àpáta ìgbàlà mi!’

  11. Èmi yóò ṣe é ni àkọ́bí mi, ẹni gíga ju àwọn ọba ayé.

  12. Títí láé ni èmi yóò pa ìfẹ́ dídúró ṣinṣin mọ́ fún un, àti májẹ̀mú mi pẹ̀lú rẹ̀ yóò dúró gbọingbọin.

  13. Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ̀ múlẹ̀ títí láé, àti ìtẹ́ rẹ gẹ́gẹ́ bí ọ̀run ti wà láé.

  14. “Bí àwọn ọmọ rẹ̀ bá kọ òfin mi sílẹ̀ tí wọn kò sì rìn gẹ́gẹ́ bí ìlànà mi.

  15. Tí wọn bá ba ìlànà mi jẹ́ tí wọn kò sì pa àṣẹ mi mọ́,

  16. nígbà náà ni èmi ó fì ọ̀gọ̀ bẹ ìrékọjá wọn wò; àti ẹ̀ṣẹ̀ wọn pẹ̀lú pàṣán;

  17. ṣùgbọ́n èmi kò ní mú ìfẹ́ mi tí ó dúró ṣinṣin kúrò lọ́dọ̀ rẹ, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò jẹ́ kí òtítọ́ mi kí ó yẹ̀.

  18. Èmi kì yóò sẹ́ májẹ̀mú mi, bẹ́ẹ̀ ni èmi kì yóò yí ọ̀rọ̀ tí ó ti ẹnu mi jáde padà.

  19. Lẹ́ẹ̀kan ṣoṣo ni èmi ti fi ìwà mímọ́ mi búra; èmi kì yóò purọ́ fún Dafidi.

  20. Irú-ọmọ rẹ yóò dúró títí láé, àti ìtẹ́ rẹ̀ yóò dúró bí oòrùn níwájú mi.

  21. Ṣùgbọ́n nísinsin yìí ìwọ ti ṣá tì, ìwọ sì kórìíra; ìwọ kún fún ìrunú sí ẹni àmì òróró rẹ.

  22. Ìwọ ti sọ májẹ̀mú ìránṣẹ́ rẹ di òfo; ìwọ tàbùkù adé rẹ nínú eruku.

  23. Ìwọ ti wó gbogbo àwọn odi rẹ̀ ìwọ sọ ibi gíga rẹ̀ di ahoro.

  24. Ìwọ ti gbé ọwọ́ ọ̀tún ọ̀tá rẹ̀ sókè; ìwọ mú gbogbo ọ̀tá rẹ̀ yọ̀.

  25. Ìwọ ti gé ọjọ́ èwe rẹ̀ kúrú; ìwọ sì fi ìtìjú bò ó.