Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìwọ tí gba ọ̀rẹ́ mi tí ó súnmọ́ mi kúrò lọ́wọ́ mi ìwọ sì sọ mi di ìríra sí wọn. A há mi mọ́, èmi kò sì le è jáde;

  2. ojú mi káàánú nítorí ìpọ́njú. Mo kígbe pè ọ́, Olúwa, ní gbogbo ọjọ́; mo na ọwọ́ mi jáde sí ọ.

  3. Ìwọ ó fi iṣẹ́ ìyanu rẹ hàn fún òkú bi? Àwọn òkú yóò ha dìde láti yìn ọ́ bí?

  4. A ó ha fi ìṣeun ìfẹ́ rẹ hàn ní ibojì bí, tàbí òtítọ́ rẹ ní ipò ìparun?

  5. A ha lè mọ iṣẹ́ ìyanu rẹ ní òkùnkùn bí àti òdodo rẹ ní ilẹ̀ ìgbàgbé?

  6. Ṣùgbọ́n mo kígbe sí ọ fún ìrànlọ́wọ́, Olúwa; ní òwúrọ̀ ni àdúrà mí wá sọ́dọ̀ rẹ.

  7. Olúwa, èéṣe tí ìwọ fi kọ̀ mí tí ìwọ fi ojú rẹ pamọ́ fún mi?

  8. Láti ìgbà èwe mi, ìṣẹ́ ń ṣẹ́ mi, èmi múra àti kú; nígbà tí ẹ̀rù rẹ bá ń bà mí, èmi di gbére-gbère.

  9. Ìbínú rẹ ti kọjá lára mi; ìbẹ̀rù rẹ ti gé mi kúrò.

  10. Ìwọ ti mú ọ̀rẹ́ àti olùfẹ́ mi kúrò lọ́dọ̀ mi; òkùnkùn sì jẹ́ ọ̀rẹ́ tímọ́tímọ́ mi.

  11. Maskili ti Etani ará Esra. Èmi kọrin títóbi ìfẹ́ Olúwa títí láé; pẹ̀lú ẹnu mi ní èmi yóò jẹ́ kí a mọ òtítọ́ rẹ láti ìran dé ìran.

  12. Èmi ó wí pé, ìfẹ́ rẹ dúró títí láé, pé ìwọ gbe òtítọ́ rẹ kalẹ̀ ní ọ̀run fúnra rẹ̀.

  13. Ìwọ wí pé, “Èmi ti dá májẹ̀mú pẹ̀lú àwọn àyànfẹ́ mi mo ti búra fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.

  14. ‘Èmi ó fi ìdí irú-ọmọ rẹ múlẹ̀ títí láé èmí ó sì máa gbe ìtẹ́ rẹ ró láti ìran dé ìran.’ ”

  15. Àwọn ọ̀run yóò máa yin iṣẹ́ ìyanu rẹ, Olúwa, òtítọ́ rẹ ni ìpéjọpọ̀ àwọn ẹni mímọ́.

  16. Ta ni ó wà ní ọ̀run tí a lè fiwé Olúwa? Ta ni nínú àwọn ọmọ alágbára ti a lè fiwé Olúwa?

  17. Nínú àjọ ìgbìmọ̀ ẹni mímọ́, wọ́n bẹ̀rù Ọlọ́run gidigidi; ó sì ní ìbùyìn fún ju gbogbo àwọn tí ó yí i ká.

  18. Olúwa Ọlọ́run alágbára, ta ló dàbí rẹ ìwọ jẹ́ alágbára, Olúwa, òtítọ́ rẹ sì yí ọ ká.

  19. Ìwọ ń darí ríru omi Òkun; nígbà tí ó ru àwọn omi sókè, ìwọ mú wọn parọ́rọ́.

  20. Ìwọ ni ó ti ya Rahabu pẹ́rẹpẹ̀rẹ bí ẹni tí a pa; ìwọ ti fi apá ọwọ́ agbára rẹ tú àwọn ọ̀tá rẹ ká.

  21. Tìrẹ ní àwọn ọ̀run, ayé pẹ̀lú jẹ́ tìrẹ: ayé àti ohun gbogbo tí ó wà nínú rẹ̀: ìwọ ti gbé wọn kalẹ̀.

  22. Gúúsù àti àríwá ìwọ ni ó dá wọn; Tabori àti Hermoni ń fi ayọ̀ yin orúkọ rẹ.

  23. Ìwọ ní apá agbára; agbára ní ọwọ́ rẹ, gíga ní ọwọ́ ọ̀tún rẹ.

  24. Òdodo àti òtítọ́ ni ìpìlẹ̀ ìtẹ́ rẹ: ìdúró ṣinṣin ìfẹ́ àti òtítọ́ ń lọ síwájú rẹ.

  25. Ìbùkún ni fún àwọn ènìyàn tí wọn mọ ohùn ayọ̀ nì, Olúwa wọ́n ó máa rìn ní ìmọ́lẹ̀ ojú rẹ.