God
Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God
Ọba sì dúró lẹ́bàá òpó, ó sì sọ májẹ̀mú di tuntun níwájú Olúwa, láti tẹ̀lé Olúwa àti láti pa òfin rẹ̀ mọ́, ìlànà àti òfin pẹ̀lú gbogbo ọkàn rẹ̀ àti gbogbo ẹ̀mí rẹ̀, àti láti ṣe ìwádìí àwọn ọ̀rọ̀ májẹ̀mú tí a kọ sínú ìwé yìí. Nígbà náà, gbogbo àwọn ènìyàn sì ṣèlérí fúnra wọn sí májẹ̀mú náà.
Ọba sì pàṣẹ fún Hilkiah olórí àlùfáà àti àwọn, àlùfáà tí ó tẹ̀lé e ní ipò àti àwọn olùṣọ́nà láti yọ kúrò nínú ilé Olúwa gbogbo ohun èlò tí a ṣe fún Baali àti Aṣerah àti gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run. Ó sì sun wọ́n ní ìta Jerusalẹmu ní pápá àfonífojì Kidironi. Ó sì kó eérú wọn jọ sí Beteli.
Ó mú ère òrìṣà Aṣerah láti ilé Olúwa sí àfonífojì Kidironi ní ìta Jerusalẹmu, ó sì sun wọ́n níbẹ̀. Ó lọ̀ ọ́ bí àtíkè ó sì fọ́n eruku náà sórí isà òkú àwọn ènìyàn tí ó wọ́pọ̀.
Ó sì wó ibùgbé àwọn ọkùnrin alágbèrè ojúbọ òrìṣà lulẹ̀. Tí ó wà nínú ilé Olúwa àti ibi tí àwọn obìnrin tí ń ṣe iṣẹ́ aṣọ híhun fún òrìṣà Aṣerah.
Bí ó tilẹ̀ jẹ́ wí pé, àwọn àlùfáà ibi gíga kò jọ́sìn ní ibi pẹpẹ Olúwa ní Jerusalẹmu, wọ́n jẹ nínú àkàrà aláìwú pẹ̀lú àwọn àlùfáà ẹlẹgbẹ́ ẹ wọn.
Ó sì kúrò láti ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé sí ilé Olúwa, àwọn ẹṣin tí àwọn ọba Juda ti yà sọ́tọ̀ sí oòrùn náà. Wọ́n wà nínú ilé ẹjọ́ lẹ́bàá yàrá oníṣẹ́ tí orúkọ rẹ̀ a máa jẹ́ Natani-Meleki. Josiah sì sun àwọn kẹ̀kẹ́ tí a yà sọ́tọ̀ fún oòrùn.
Ó wó o palẹ̀ pẹpẹ tí àwọn ọba Juda ti wọ́n gbé dúró ní orí òrùlé lẹ́bàá yàrá òkè ti Ahasi pẹ̀lú àwọn pẹpẹ tí Manase ti kọ́ nínú ilé ẹjọ́ méjèèjì sí ilé Olúwa. Ó ṣí wọn kúrò níbẹ̀, ó fọ́ wọn sí wẹ́wẹ́. Ó sì da ekuru wọn sínú àfonífojì Kidironi.
Nígbà náà, Josiah wò yíká, nígbà tí ó sì rí àwọn isà òkú tí ó wà níbẹ̀ ní ẹ̀bá òkè, ó yọ egungun kúrò lára wọn, ó sì jó wọn lórí pẹpẹ láti sọ ọ́ di èérí ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí a ti kéde láti ọ̀dọ̀ ènìyàn Ọlọ́run tí ó ti àwọn nǹkan wọ̀nyí tẹ́lẹ̀.
Ọba sì béèrè pé, “Kí ni ọwọ̀n isà òkú yẹn tí mo rí?” Àwọn ọkùnrin ìlú ńlá wí pé, “Ó sàmì sí isà òkú ènìyàn Ọlọ́run tí ó wá láti Juda, tí ó sì kéde ìdojúkọ pẹpẹ Beteli, ohun kan wọ̀nyí tí ìwọ ti ṣe sí wọn.”
Gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe ní Beteli, Josiah sì kúrò, ó sì ba gbogbo ojúbọ òrìṣà ti ibi gíga jẹ́, tí àwọn ọba Israẹli ti kọ́ sí àwọn ìlú ní Samaria, tí ó ti mú Olúwa bínú.
Ọba pàṣẹ fún gbogbo àwọn ènìyàn pé, “Ẹ ṣe ìrántí àjọ ìrékọjá sí Olúwa Ọlọ́run yín, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ ọ́ sí inú ìwé májẹ̀mú yìí.”
Ṣùgbọ́n ní ọdún kejìdínlógún tí ọba Josiah, àjọ ìrékọjá yìí ni a ṣe ìrántí sí Olúwa ní Jerusalẹmu.
Síwájú sí, Josiah sì lé àwọn oṣó àti àwọn ẹ̀mí ní àwọn ìdílé, àti àwọn òrìṣà àti gbogbo àwọn nǹkan ìríra tí a rí ní Juda àti ní Jerusalẹmu. Èyí ni ó ṣe kí ó le è mú ọ̀rọ̀ òfin náà ṣe ní ti òfin tí a kọ sínú ìwé tí Hilkiah àlùfáà ti rí nínú ilé Olúwa.
Kò sì sí ọba kankan níwájú tàbí lẹ́yìn Josiah tí ó dàbí rẹ̀, tí ó yí padà sí olúwa tinútinú àti gẹ́gẹ́ bí ó ti ṣe tọkàntọkàn pẹ̀lú gbogbo ẹ̀mí i rẹ̀, pẹ̀lú gbogbo agbára rẹ̀ ní ìbámu pẹ̀lú gbogbo òfin Mose.
Bí ó ti wù kí ó rí Olúwa kò yípadà kúrò nínú ìmúná ìbínú ńlá rẹ̀ tí ó jó sí Juda, nítorí gbogbo èyí tí Manase ti ṣe láti mú un bínú.
Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa wí pé, “Èmi yóò mú Juda kúrò pẹ̀lú níwájú mi, bí mo ti mú Israẹli, èmi yóò sì kó Jerusalẹmu, ìlú ńlá tí mo yàn àti ilé Olúwa yìí, nípa èyí tí mo sọ, ‘Níbẹ̀ ni orúkọ mi yóò wà?’ ”
Ó ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.
Ó sì ṣe búburú lójú Olúwa gẹ́gẹ́ bí baba a rẹ̀ ti ṣe.
Olúwa sì rán àwọn ará Babeli, àwọn ará Aramu, àwọn ará Moabu àti àwọn ọmọ Ammoni. Ó rán wọn láti pa Juda run, ní ìbámu pẹ̀lú ọ̀rọ̀ Olúwa tí ó ti sọ nípasẹ̀ àwọn ìránṣẹ́ rẹ̀ wòlíì.
Nítòótọ́ eléyìí ṣẹlẹ̀ sí Juda gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa, láti mú wọn kúrò níwájú rẹ̀ nítorí ẹ̀ṣẹ̀ Manase àti gbogbo nǹkan tí ó ṣe.
Àti pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí a ta sílẹ̀ nítorí ó ti kún Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ tí Olúwa kò sì fẹ́ láti dáríjì.
Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí baba rẹ̀ ti ṣe.
Gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti sọ Nebukadnessari kó gbogbo ìṣúra láti inú ilé Olúwa àti láti ilé ọba, ó sì mú u lọ gbogbo ohun èlò wúrà ti Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Olúwa.
Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, gẹ́gẹ́ bí Jehoiakimu ti ṣe.
Nítorí tí ìbínú Olúwa, ni gbogbo èyí ṣe ṣẹ sí Jerusalẹmu, àti Juda, ní òpin ó ta wọ́n nù kúrò níwájú rẹ̀. Nísinsin yìí Sedekiah sì ṣọ̀tẹ̀ sí ọba Babeli.