Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Èyí ni ọ̀rọ̀ tí Olúwa ti sọ nípa rẹ̀, “ ‘Wúńdíá ọmọbìnrin Sioni kẹ́gàn rẹ ó sì fi ọ́ ṣe ẹlẹ́yà. Ọmọbìnrin Jerusalẹmu mi orí sí ọ gẹ́gẹ́ bí o ti sálọ.

  2. Nípa àwọn ìránṣẹ́ rẹ ìwọ ti sọ̀rọ̀ búburú sí Olúwa. Tì wọ sì wí pé, “Pẹ̀lú ọ̀pọ̀ kẹ̀kẹ́ mi ni èmi sì fi dé orí àwọn òkè ńlá, sí ibi gíga jùlọ Lebanoni. Èmi a sì ké igi kedari gíga rẹ̀ lulẹ̀, àti ààyò igi firi rẹ̀. Èmi a sì lọ sí orí òkè ìbùwọ̀ rẹ̀ sínú ibi tí ó dára jù nínú igbó rẹ̀.

  3. “ ‘Ṣé ìwọ kò tí ì gbọ́? Ní ọjọ́ pípẹ́ sẹ́yìn mo yàn án. Ní ọjọ́ ogbó ni mo ṣètò rẹ̀; nísinsin yìí mo ti mú wá sí ìkọjá pé ìwọ ti yí ìlú olódi padà dí òkìtì àlàpà òkúta.

  4. “ ‘Ṣùgbọ́n èmi mọ ibi tí ìwọ dúró àti ìgbà tí ìwọ bá dé tàbí lọ àti bí ìwọ ṣe ìkáàánú rẹ: sí mi.

  5. Ṣùgbọ́n ìkáàánú rẹ sí mi àti ìrora rẹ dé etí mi, Èmi yóò gbé ìwọ̀ mi sí imú rẹ àti ìjánu mi sí ẹnu rẹ, èmi yóò mú ọ padà nípa wíwá rẹ.’

  6. Láti inú Jerusalẹmu ní àwọn ìyókù yóò ti wá àti láti orí òkè Sioni ni ọ̀pọ̀ àwọn tí ó sá àsálà. Ìtara Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò ṣe èyí.

  7. “Nítorí èyí ni ohun tí Olúwa sọ nípa ti ọba Asiria: “Kò ní wọ ìlú yìí tàbí ta ọfà síbí. Kò ní wá níwájú rẹ pẹ̀lú àpáta tàbí kó ìdọ̀tí àgbò sí ọ̀kánkán rẹ.

  8. Nípa ọ̀nà tí ó gbà wá ni yóò padà; kì yóò wọ ìlú ńlá yìí, ni Olúwa wí.

  9. Èmi yóò dá ààbò bo ìlú ńlá yìí, èmi yóò sì pa á mọ́ fún èmi tìkára mi àti fún Dafidi ìránṣẹ́ mi.”

  10. Ní alẹ́ ọjọ́ náà, angẹli Olúwa jáde lọ ó sì pa ọ̀kẹ́ mẹ́sàn-án lé ẹgbẹ̀ẹ́dọ́gbọ̀n (185,000) ènìyàn ní ibùdó àwọn ará Asiria. Nígbà tí wọ́n sì dìde dúró ní òwúrọ̀ ọjọ́ kejì níbẹ̀ ni gbogbo òkú wà!

  11. Ní ayé ìgbà wọ̀n-ọn-nì Hesekiah ṣe àìsàn ó sì wà ní ojú ikú. Wòlíì Isaiah ọmọ Amosi lọ sọ́dọ̀ rẹ̀ ó sì wí pé, “Èyí ni ohun tí Olúwa sọ: tún ilé rẹ ṣe, ṣùgbọ́n ìwọ yóò kú; o kò ní í gbádùn.”

  12. Hesekiah yí ojú rẹ̀ padà sí ògiri ó sì gbàdúrà sí Olúwa pé,

  13. “Rántí, Olúwa mi, bí èmi ṣe rìn níwájú rẹ àti pẹ̀lú bí èmi ṣe jẹ́ olóòtítọ́ àti pẹ̀lú gbogbo ọkàn ìfọkànsìn mi tí èmi sì ti ṣe ohun tí ó dára níwájú rẹ.” Hesekiah sọkún kíkorò.

  14. Kí ó tó di wí pé Isaiah jáde kúrò ní àárín àgbàlá ààfin, ọ̀rọ̀ Olúwa wá sí ọ̀dọ̀ rẹ̀ pé:

  15. “Lọ padà kí o sì sọ fún Hesekiah, olórí àwọn ènìyàn mi pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa, Ọlọ́run baba rẹ Dafidi sọ: Mo ti gbọ́ àdúrà rẹ mo sì ti rí omijé rẹ, Èmi yóò wò ọ́ sàn. Ní ọjọ́ kẹta láti ìsinsin yìí, ìwọ yóò lọ sókè ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  16. Èmi yóò fi ọdún mẹ́ẹ̀ẹ́dógún kún ọjọ́ ayé rẹ. Èmi yóò sì gbà ọ́ àti ìlú ńlá yìí láti ọwọ́ ọba Asiria. Èmi yóò sì dáàbò bo ìlú yìí nítorí ti èmi tìkára mi àti nítorí ti Dafidi ìránṣẹ́ mi.’ ”

  17. Hesekiah sì béèrè lọ́wọ́ Isaiah pé, “Kí ni yóò jẹ́ àmì pé Olúwa yóò wò mí sàn àti wí pé èmi yóò lọ sókè sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa láti ọjọ́ kẹta títí di òní?”

  18. Isaiah dáhùn pé, “Èyí ni àmì tí Olúwa fún ọ wí pé Olúwa yóò ṣe ohun tí ó ti ṣe ìlérí: kí òjìji lọ síwájú ìgbésẹ̀ mẹ́wàá, tàbí kí ó padà lọ ní ìgbésẹ̀ mẹ́wàá?”

  19. Nígbà náà wòlíì Isaiah ké pe Olúwa, Olúwa sì ṣe òjìji padà sí ìgbésẹ̀ mẹ́wàá ó ti sọ̀kalẹ̀ ní òpópó ọ̀nà Ahasi.

  20. Nígbà náà Isaiah wí fún Hesekiah pé, “Gbọ́ ọ̀rọ̀ Olúwa,

  21. àkókò náà yóò sì dé nítòótọ́ nígbà tí gbogbo ohun tí ó wà ní ààfin àti gbogbo ohun tí baba rẹ̀ ti kó pamọ́ sókè títí di ọjọ́ òní, wọn yí ó gbe lọ sí Babeli, kò sí ohun tí yóò kù, ni Olúwa wí.

  22. Hesekiah wí fún Isaiah pé. “Rere ni ọ̀rọ̀ Olúwa tí ìwọ sọ.” Nítorí ó rò wí pé, “Kò ha dára àlàáfíà àti òtítọ́ ní ọjọ́ ayé mi?”

  23. Ó sì ṣe búburú ní ojú Olúwa, ó sì tẹ̀lé iṣẹ́ ìríra tí àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa lé jáde níwájú àwọn ọmọ Israẹli.

  24. Ó sì kọ́ pẹpẹ nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa, èyí tí Olúwa ti sọ pé, “Ní Jerusalẹmu ni èmi yóò kọ orúkọ mi sí.”

  25. Ní àgbàlá méjèèjì ilé Olúwa, ó sì kọ́ pẹpẹ fún gbogbo àwọn ìrúbọ nínú ilé, ṣe iṣẹ́ àkíyèsí àfọ̀ṣẹ, ó sì béèrè lọ́wọ́ àwọn òkú àti àwọn oṣó. Ó sì ṣe ọ̀pọ̀ búburú ní ojú Olúwa, ó sì mú un bínú.