Fò sí àkóónú

God

11,427 ẹsẹ · 2 ọmọ ẹbí

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan God

Sẹ́ nípa ìwé
  1. àti ẹ̀yin tí ó wà ní ẹgbẹ́ kejì yòókù tí kì í lọ ibi iṣẹ́ ìsìn ní ọjọ́ ìsinmi gbogbo ni kí ó ṣọ́ ilé tí a kọ́ fún Olúwa fún ọba.

  2. Nígbà náà, ó fún àwọn olórí ní àwọn ọ̀kọ̀ àti àwọn àpáta tí ó ti jẹ́ ti ọba Dafidi tí ó sì wà nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  3. Jehoiada mú ọmọkùnrin ọba jáde, ó sì gbé adé náà lé e: ó fún un ní ẹ̀dà májẹ̀mú, wọ́n sì kéde ọba rẹ̀. Wọ́n fi àmì òróró yàn án, àwọn ènìyàn pa àtẹ́wọ́, wọ́n sì kígbe, “Kí ẹ̀mí ọba kí ó gùn.”

  4. Nígbà tí Ataliah gbọ́ ariwo tí àwọn olùṣọ́ àti àwọn ènìyàn ń pa, ó lọ sí ọ̀dọ̀ àwọn ènìyàn nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  5. Jehoiada àlùfáà pàṣẹ fún olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún, ta ni ó wà ní ìkáwọ́ ọ̀wọ́ ogun: “Mú u jáde láàrín àwọn ẹgbẹ́ ogun yìí kí o sì fi sí ipa idà ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ̀lé.” Nítorí àlùfáà ti sọ, “A kò gbọdọ̀ pa á nínú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.”

  6. Nígbà náà ni Jehoiada dá májẹ̀mú láàrín Olúwa àti ọba àti àwọn ènìyàn tí yóò jẹ́ ènìyàn Olúwa. Ó dá májẹ̀mú láàrín ọba àti àwọn ènìyàn pẹ̀lú.

  7. Gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà lọ sí ilé tí a kọ́ fún òrìṣà Baali wọ́n sì ya á bolẹ̀. Wọ́n fọ́ àwọn pẹpẹ àti òrìṣà sí wẹ́wẹ́. Wọ́n sì pa Mattani àlùfáà Baali níwájú àwọn pẹpẹ. Nígbà náà, Jehoiada àlùfáà náà sì yan àwọn olùṣọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  8. Ó mú pẹ̀lú u rẹ̀ àwọn olórí ọ̀rọ̀ọ̀rún àti gbogbo balógun àti àwọn olùṣọ́ àti gbogbo àwọn ènìyàn ilẹ̀ náà àti lápapọ̀, wọ́n mú ọba sọ̀kalẹ̀ wá láti ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọ́n sì wọ inú ààfin lọ, wọ́n sì wọlé nípa ìlẹ̀kùn ti àwọn olùṣọ́. Ọba sì mú ààyè rẹ̀ ní orí ìtẹ́ ọba.

  9. Jehoaṣi ṣe ohun tí ó tọ́ ní ojú Olúwa ní gbogbo ọdún tí Jehoiada àlùfáà fi àṣẹ fún un.

  10. Jehoaṣi sọ fún àwọn àlùfáà pé, “Gba gbogbo owó tí wọ́n mú wá gẹ́gẹ́ bí ọrẹ mímọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa owó tí a gbà ní ìgbà kíka àwọn ènìyàn ìlú, owó tí a gbà láti ọwọ́ olúkúlùkù bí wọ́n ti ṣe jẹ́ ẹ̀yà àti owó tí ó ti ọkàn olúkúlùkù wá tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  11. Jehoiada àlùfáà mú àpótí kan, ó sì lu ihò sí ìdérí rẹ̀. Ó gbé e sí ẹ̀gbẹ́ pẹpẹ ní apá ọ̀tún bí ẹnìkan ti wọlé tí a kọ́ fún Olúwa. Àwọn àlùfáà tí ó ṣọ́ ẹnu-ọ̀nà àbáwọlé fi sínú àpótí náà gbogbo owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  12. Ìgbàkígbà tí wọ́n bá ti rí wí pé owó púpọ̀ wà nínú àpótí, akọ̀wé ọba àti olórí àlùfáà yóò wá, wọ́n á ka owó náà tí wọ́n ti mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Wọn a sì kó o sínú àwọn àpò.

  13. Nígbà tí wọ́n bá ti pinnu iye rẹ̀, wọn a kó owó náà fún àwọn tí a ti yàn láti bojútó iṣẹ́ náà lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa. Pẹ̀lú u rẹ̀, wọ́n sọ fún àwọn tí ó ń ṣiṣẹ́ lórí ilé tí a kọ́ fún Olúwa; àwọn gbẹ́nàgbẹ́nà àti àwọn olùkọ́lé.

  14. Àwọn ilé ńlá àti àwọn agékúta. Wọ́n ra igi gẹdú àti òkúta tí wọ́n tọ́jú fún tuntun ilé tí a kọ́ fún Olúwa ṣe. Wọ́n tún ohun gbogbo tí wọ́n ná fún títún tẹmpili ṣe.

  15. Owó tí a mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa kò jẹ́ níná fún ṣíṣe òpó fàdákà, ohun èlò ta fi ń fa ẹnu fìtílà, àwokòtò, ìpè, ohun èlò wúrà tàbí ohun èlò fàdákà kan fún ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  16. A sì san án fún àwọn ọkùnrin tí ó ń ṣiṣẹ́, tí wọ́n ń tọ́jú ilé tí a kọ́ fún Olúwa.

  17. Owó láti ibi ọrẹ ẹ̀bi àti ọrẹ ẹ̀ṣẹ̀ ní a kò mú wá sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa, ó jẹ́ ti àwọn àlùfáà.

  18. Ṣùgbọ́n Jehoaṣi ọba Juda mú gbogbo ohun mímọ́ tí a gbé ka iwájú tí a yà sọ́tọ̀ nípasẹ̀ baba rẹ̀ Jehoṣafati, Jehoramu àti Ahasiah, àwọn ọba Juda, àti àwọn ẹ̀bùn tí òun tìkára rẹ̀ ti yà sọ́tọ̀ àti gbogbo wúrà, tí ó rí nínú ibi ìfowópamọ́ sí ilé tí a kọ́ fún Olúwa àti ní ti ààfin ọba, ó sì fi wọ́n ránṣẹ́ sí Hasaeli; ọba Siria, tí ó sì fà padà kúrò ní Jerusalẹmu.

  19. Ó ṣe búburú níwájú Olúwa nípa títẹ̀lé ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati, èyí tí ó ti fa Israẹli láti dá, kò sì yípadà kúrò nínú wọn.

  20. Bẹ́ẹ̀ ni ìbínú Olúwa ru sí àwọn ọmọ Israẹli, àti fún ìgbà pípẹ́, ó fi wọ́n pamọ́ sí abẹ́ agbára ọba Hasaeli ọba Siria àti Beni-Hadadi ọmọ rẹ̀.

  21. Nígbà náà Jehoahasi kígbe ó wá ojúrere Olúwa, Olúwa sì tẹ́tí sí i. Nítorí ó rí bí ọba Siria ti ń ni Israẹli lára gidigidi.

  22. Olúwa pèsè olùgbàlà fún Israẹli, wọ́n sì sá kúrò lọ́wọ́ agbára Siria. Bẹ́ẹ̀ ni àwọn ọmọ Israẹli gbé nínú ilé ara wọn gẹ́gẹ́ bí wọ́n ti wà tẹ́lẹ̀.

  23. Ó ṣe búburú ní ojú Olúwa, kò sì yípadà kúrò nínú ọ̀kankan nínú ẹ̀ṣẹ̀ Jeroboamu ọmọ Nebati èyí tí ó ti ti Israẹli láti fà. Ó sì tẹ̀síwájú nínú wọn.

  24. “Ṣí fèrèsé apá ìlà-oòrùn,” ó wí, pẹ̀lú ó sì ṣí i: “Ta á!” Eliṣa wí, ó sì ta á. “Ọfà ìṣẹ́gun Olúwa; ọfà ìṣẹ́gun lórí Siria!” Eliṣa kéde. “Ìwọ yóò pa àwọn ará Siria run pátápátá ní Afeki.”

  25. Ènìyàn Ọlọ́run sì bínú sí i, ó sì wí pé, “Ìwọ kò bá ti lu ilẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀márùn ún tàbí ní ẹ̀ẹ̀mẹ́fà, nígbà náà, ìwọ kò bá ti ṣẹ́gun Siria àti pa á run pátápátá ṣùgbọ́n nísinsin yìí, ìwọ yóò ṣẹ́gun rẹ̀ ní ẹ̀ẹ̀mẹ́ta péré.”