Fò sí àkóónú
Jobu 30:1-15

Jobu 30:1-15

1
“Ṣùgbọ́n nísinsin yìí, àwọn tí mo gbà ní àbúrò ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà baba ẹni tí èmi kẹ́gàn láti tò pẹ̀lú àwọn ajá nínú agbo ẹran mi.
2
Kí ni ìwúlò agbára ọwọ́ wọn sí mi, níwọ̀n ìgbà tí agbára wọn ti fi wọ́n sílẹ̀?
3
Wọ́n rù nítorí àìní àti ìyàn wọ́n ń rìn káàkiri ní ilẹ̀ gbígbẹ ní ibi ìkọ̀sílẹ̀ ní òru.
4
Àwọn ẹni tí ń já ewé iyọ̀ ní ẹ̀bá igbó; gbogbo igikígi ni oúnjẹ jíjẹ wọn.
5
A lé wọn kúrò láàrín ènìyàn, àwọn ènìyàn sì pariwo lé wọn lórí bí ẹní pariwo lé olè lórí.
6
A mú wọn gbe inú pàlàpálá òkúta àfonífojì, nínú ihò ilẹ̀ àti ti òkúta.
7
Wọ́n ń dún ní àárín igbó wọ́n kó ara wọn jọ pọ̀ ní abẹ́ ẹ̀gún neteli.
8
Àwọn ọmọ ẹni tí òye kò yé, àní àwọn ọmọ lásán, a sì lé wọn jáde kúrò ní orí ilẹ̀.
9
“Ǹjẹ́ nísinsin yìí, àwọn ọmọ wọn ń fi mí ṣe ẹlẹ́yà nínú orin; àní èmi di ẹni ìṣọ̀rọ̀ sí láàrín wọn.
10
Wọ́n kórìíra mi; wọ́n sá kúrò jìnnà sí mi, wọn kò sì bìkítà láti tutọ́ sí mi lójú.
11
Nítorí Ọlọ́run ti tú okùn ìyè mi, ó sì pọ́n mi lójú; àwọn pẹ̀lú sì dẹ ìdẹ̀kùn níwájú mi.
12
Àwọn ènìyàn lásán dìde ní apá ọ̀tún mi; wọ́n tì ẹsẹ̀ mi kúrò, wọ́n sì la ipa ọ̀nà ìparun sílẹ̀ dè mí.
13
Wọ́n da ipa ọ̀nà mi rú; wọ́n sì sọ ìparun mi di púpọ̀, àwọn tí kò ní olùrànlọ́wọ́.
14
Wọ́n ya sí mi bí i omi tí ó ya gbuuru; ní ariwo ńlá ni wọ́n rọ́ wá.
15
Ẹ̀rù ńlá bà mí; wọ́n lépa ọkàn mi bí ẹ̀fúùfù, àlàáfíà mi sì kọjá lọ bí àwọ̀ sánmọ̀.
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options