Fò sí àkóónú

Jobu39

Ìpèsè Ọlọ́run fún àwọn ẹranko inú igbó

1
“Ìwọ mọ àkókò ìgbà tí àwọn ewúrẹ́ orí àpáta ń bímọ? Ìwọ sì lè kíyèsi ìgbà tí abo àgbọ̀nrín ń bímọ?
2
Ìwọ lè ka iye òṣùpá tí wọn ń pé, ìwọ sì mọ àkókò ìgbà tí wọn ń bímọ.
3
Wọ́n tẹ ara wọn ba, wọ́n bímọ, wọ́n sì mú ìkáàánú wọn jáde.
4
Àwọn ọmọ wọn rí dáradára, wọ́n dàgbà nínú ọ̀dàn; wọ́n jáde lọ, wọn kò sì tún padà wá sọ́dọ̀ wọn.

Kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ inú igbó tí a kò lè tọ́

5
“Ta ni ó jọ̀wọ́ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ oko lọ́wọ́? Tàbí ta ní ó tú ìdè kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ igbó,
6
èyí tí mo fi aginjù ṣe ilé fún, àti ilẹ̀ iyọ̀ ní ibùgbé rẹ̀.
7
Ó rẹ́rìn-ín sí ariwo ìlú, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbọ́ igbe darandaran.
8
Orí àtòlé òkè ńlá ni ibùjẹ oko rẹ̀, òun a sì máa wá ewé tútù gbogbo rí.

Agbára akọ màlúù inú igbó tí kò wúlò fún iṣẹ́

9
“Àgbáǹréré ha jẹ́ sìn ọ́ bí? Tàbí ó jẹ́ dúró ní ibùjẹ ẹran rẹ ní òru?
10
Ìwọ le fi òkun tata de àgbáǹréré nínú aporo? Tàbí ó jẹ́ máa fa ìtulẹ̀ nínú aporo oko tọ̀ ọ́ lẹ́yìn?
11
Ìwọ ó gbẹ́kẹ̀lé e nítorí agbára rẹ̀ pọ̀? Ìwọ ó sì fi iṣẹ́ rẹ lé e lọ́wọ́?
12
Ìwọ le gbẹ́kẹ̀lé pé, yóò mú èso oko rẹ̀ wá sílé, àti pé yóò sì kó ọ jọ sínú àká rẹ?

Ògòǹgò tí kò ní ọgbọ́n

13
“Ìwọ ni yóò ha fi ìyẹ́ dáradára fún ọ̀kín bí, tàbí ìyẹ́ àti ìhùhù bo ògòǹgò?
14
Ó yé ẹ̀yìn rẹ̀ sílẹ̀ lórí ilẹ̀, a sì mú wọn gbóná nínú ekuru;
15
tí ó sì gbàgbé pé, ẹsẹ̀ lè tẹ̀ wọ́n fọ́, tàbí pé ẹranko igbó lè tẹ̀ wọ́n fọ́.
16
Kò ní àánú sí àwọn ọmọ rẹ̀ bí ẹni pé wọn kì í ṣe tirẹ̀; asán ni iṣẹ́ rẹ̀ láìní ìbẹ̀rù;
17
nítorí pé Ọlọ́run kò fún un ní ọgbọ́n, bẹ́ẹ̀ ni kò sì fi ìpín òye fún un.
18
Nígbà tí ó gbé ara sókè, ó gan ẹṣin àti ẹlẹ́ṣin.

Agbára àti ẹ̀rù ẹṣin ogun

19
“Ìwọ ni ó fi agbára fún ẹṣin bí, tàbí ṣé ìwọ ni ó fi gọ̀gọ̀ wọ ọrùn rẹ̀ ní aṣọ?
20
Ìwọ le mú fò sókè bí ẹlẹ́ǹgà? Ògo èémí imú rẹ ní ẹ̀rù ńlá.
21
Ó fi ẹsẹ̀ halẹ̀ nínú àfonífojì, ó sì yọ̀ nínú agbára rẹ̀; ó lọ jáde láti pàdé àwọn ìhámọ́ra ogun.
22
Ó fi ojú kékeré wo ẹ̀rù, àyà kò sì fò ó; bẹ́ẹ̀ ni kì í sì í padà sẹ́yìn kúrò lọ́wọ́ idà.
23
Lọ́dọ̀ rẹ ni apó-ọfà ń mì pẹkẹpẹkẹ, àti ọ̀kọ̀ dídán àti àpáta.
24
Ó fi kíkorò ojú àti ìbínú ńlá gbé ilé mi, bẹ́ẹ̀ ni òun kò sì gbà á gbọ́ pé, ìró ìpè ni.
25
Ó wí nígbà ìpè pé, Háà! Háà! Ó sì gbóhùn ogun lókèèrè réré, igbe àwọn balógun àti ìhó ayọ̀ ogun wọn.

Ìfòfò àdánidá àwọn ẹyẹ ọdẹ

26
“Àwòdì ha máa ti ipa ọgbọ́n rẹ̀ fò sókè, tí ó sì na ìyẹ́ apá rẹ̀ sí ìhà gúúsù?
27
Idì ha máa fi àṣẹ rẹ̀ fò sókè, kí ó sì lọ tẹ́ ìtẹ́ rẹ̀ sí òkè gíga?
28
Ó ń gbé, ó sì ń wò ní orí àpáta, lórí pàlàpálá òkúta àti ibi orí òkè.
29
Láti ibẹ̀ lọ ni ó ti ń wá oúnjẹ kiri, ojú rẹ̀ sì ríran rí òkè réré.
30
Àwọn ọmọ rẹ̀ pẹ̀lú a máa mu ẹ̀jẹ̀, níbi tí òkú bá gbé wà, níbẹ̀ ni òun wà pẹ̀lú.”
Use arrow keys to navigate
Settings

Reading Style

Typeface

Font Size 19px

Reading Width 45 chars

Options