Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Zion: Restoration of, promised

21 ẹsẹ · 9 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Restoration of, promised

  1. Dájúdájú, Olúwa yóò tu Sioni nínú yóò sì bojú àánú wo gbogbo ahoro rẹ̀; Òun yóò sọ gbogbo aṣálẹ̀ rẹ̀ di Edeni, àti aṣálẹ̀ rẹ̀ yóò rí bí ọgbà Olúwa. Ayọ̀ àti inú dídùn ni a ó rí nínú rẹ̀, ọpẹ́ àti ariwo orín kíkọ.

  2. Àwọn ẹni ìràpadà Olúwa yóò padà wá. Wọn yóò wọ Sioni wá pẹ̀lú orin kíkọ; ayọ̀ ayérayé ni yóò sì bo orí wọn. Ayọ̀ àti inú dídùn yóò sì bà lé wọn ìbànújẹ́ àti ìtìjú yóò sì sá kúrò.

  3. Mo ti fi ọ̀rọ̀ mi sí ẹnu rẹ mo sì ti fi òjìji ọwọ́ mi bò ọ́, Èmi tí mo tẹ́ àwọn ọ̀run sí ààyè rẹ̀, ẹni tí ó fi ìpìlẹ̀ ilẹ̀ ayé lélẹ̀, àti ẹni tí ó sọ fún Sioni pé, ‘Ẹ̀yin ni ènìyàn mi.’ ”

  4. Jí, jí, ìwọ Sioni, wọ ara rẹ ní agbára. Gbé aṣọ ògo rẹ wọ̀, ìwọ Jerusalẹmu, ìlú mímọ́ n nì. Àwọn aláìkọlà àti aláìmọ́ kì yóò wọ inú rẹ mọ́.

  5. Gbọn eruku rẹ kúrò; dìde sókè, kí o sì gúnwà, ìwọ Jerusalẹmu. Bọ́ ẹ̀wọ̀n tí ń bẹ lọ́rùn rẹ kúrò, ìwọ ọ̀dọ́mọbìnrin ìgbèkùn Sioni.

  6. Báwo ni ó ṣe dára tó lórí òkè ẹsẹ̀ àwọn tí ó mú ìyìnrere ayọ̀ wá, tí wọ́n kéde àlàáfíà, tí ó mú ìyìnrere wá, tí ó kéde ìgbàlà, tí ó sọ fún Sioni pé, “Ọlọ́run rẹ ń jẹ ọba!”

  7. Tẹ́tí sílẹ̀! Àwọn olùṣọ́ rẹ gbé ohùn wọn sókè wọ́n kígbe papọ̀ fún ayọ̀. Nígbà tí Olúwa padà sí Sioni, wọn yóò rí i pẹ̀lú ojú u wọn.

  8. “Olùdáǹdè yóò wá sí Sioni, sí àwọn tí ó wà ní Jakọbu tí ó ronúpìwàdà ẹ̀ṣẹ̀ wọn,” ni Olúwa wí.

  9. Àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin àwọn apọ́nilójú rẹ yóò wá foríbalẹ̀ fún ọ; gbogbo àwọn tí ó ti kẹ́gàn rẹ ni wọn yóò tẹríba níwájú rẹ wọn yóò sì pè ọ́ ní ìlú Olúwa, Sioni ti Ẹni Mímọ́ Israẹli.

  10. Ṣùgbọ́n ìgbàlà yóò wà lórí òkè Sioni, wọn yóò sì jẹ́ mímọ́, àti ilé Jakọbu yóò sì ní ìní wọn.

  11. Àwọn tó ń gba ni là yóò sì gòkè Sioni wá láti jẹ ọba lé orí àwọn òkè Esau. Ìjọba náà yóò sì jẹ́ ti Olúwa.

  12. Kọrin, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, kígbe sókè, ìwọ Israẹli! Fi gbogbo ọkàn yọ̀, kí inú rẹ kí ó sì dùn, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu.

  13. Ní ọjọ́ náà, wọn yóò sọ fún Jerusalẹmu pé, “Má ṣe bẹ̀rù Sioni; má sì ṣe jẹ́ kí ọwọ́ rẹ kí ó dẹ̀.

  14. Angẹli ti ń bá mi sọ̀rọ̀ sì wí fún mi pé, “Ìwọ kígbe wí pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘Èmi ń fi ìjowú ńlá jowú fún Jerusalẹmu àti fún Sioni.

  15. “Máa ké síbẹ̀ pé, báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, ‘A o máa fi ìre kún ìlú ńlá mi síbẹ̀; Olúwa yóò sì máa tu Sioni nínú síbẹ̀, yóò sì yan Jerusalẹmu síbẹ̀.’ ”

  16. “Gbà ara rẹ̀ sílẹ̀, ìwọ Sioni, ìwọ tí ó ń bà ọmọbìnrin Babeli gbé.”

  17. “Kọrin kí o sì yọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni. Nítorí èmi ń bọ̀ àti pé èmi yóò sì gbé àárín rẹ,” ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí.

  18. Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí, “Owú ńlá ńlá ni mo jẹ fún Sioni, pẹ̀lú ìbínú ńlá ńlá ni mo fi jowú fún un.”

  19. Báyìí ni Olúwa wí, “Mo yípadà sí Sioni èmi ó sì gbé àárín Jerusalẹmu. Nígbà náà ni a ó sì pé Jerusalẹmu ni ìlú ńlá òtítọ́; àti òkè ńlá Olúwa àwọn ọmọ-ogun, ni a ó pè ní òkè ńlá mímọ́.”

  20. Kún fún ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Sioni, hó ìhó ayọ̀, ìwọ ọmọbìnrin Jerusalẹmu. Wò ó, ọba rẹ ń bọ̀ wá sọ́dọ̀ rẹ: òdodo ni òun, ó sì ní ìgbàlà; ó ní ìrẹ̀lẹ̀, ó sì ń gun kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́, àní ọmọ kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́.

  21. Èmi ó fa Juda le bí mo ṣe fa ọrun mi le, mo sì fi Efraimu kún un, Èmi yóò gbé àwọn ọmọ rẹ ọkùnrin dìde, ìwọ Sioni, sí àwọn ọmọ rẹ̀ ọkùnrin, ìwọ Giriki, mo ṣe ọ́ bí idà alágbára.