Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Zechariah

36 ẹsẹ · 16 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nínú ìran Elamu: Mattaniah, Sekariah, Jehieli, Abdi, Jerimoti àti Elijah.

  2. Akọ̀wé Esra dìde dúró lórí i pẹpẹ ìdúrólé tí a fi igi kàn fún ètò yìí. Ní ẹ̀gbẹ́ rẹ̀ ọ̀tún ni Mattitiah, Ṣema, Anaiah, Uriah, Hilkiah àti Maaseiah gbé dúró sí, ní ẹ̀gbẹ́ òsì rẹ̀ ní Pedaiah, Misaeli, Malkiah, Haṣumu, Haṣabadana, Sekariah àti Meṣullamu dúró sí.

  3. Nígbà tí àwọn ènìyàn tókù nínú àwọn Juda àti Benjamini ń gbé ní Jerusalẹmu). Nínú àwọn ọmọ Juda: Ataiah ọmọ Ussiah ọmọ Sekariah, ọmọ Amariah, ọmọ Ṣefatia, ọmọ Mahalaleli, ìran Peresi;

  4. àti Maaseiah ọmọ Baruku, ọmọ Koli-Hose, ọmọ Hasaiah, ọmọ Adaiah, ọmọ Joiaribu, ọmọ Sekariah, ọmọ Ṣilo.

  5. àti àwọn ẹlẹgbẹ́ wọn, ẹni tí ó ń ṣe iṣẹ́ ní tẹmpili jẹ́ ẹgbẹ̀rin ó lé mẹ́rìnlélógún (822) ọkùnrin: Adaiah ọmọ Jerohamu, ọmọ Pelaiah, ọmọ Amisi, ọmọ Sekariah, ọmọ Paṣuri, ọmọ Malkiah,

  6. ti ìdílé Iddo, Sekariah; ti ìdílé Ginetoni, Meṣullamu;

  7. pẹ̀lú àwọn àlùfáà díẹ̀ pẹ̀lú ìpè, pẹ̀lú u Sekariah ọmọ Jonatani, ọmọ Ṣemaiah, ọmọ Mattaniah, ọmọ Mikaiah, ọmọ Sakkuri, ọmọ Asafu,

  8. àti àwọn àlùfáà Eliakimu, Maaseiah, Miniamini, Mikaiah, Elioenai, Sekariah àti Hananiah pẹ̀lú àwọn ìpè wọn.

  9. Èmi yóò sì mú Uriah àlùfáà àti Sekariah ọmọ Jeberekiah gẹ́gẹ́ bí ẹlẹ́rìí òtítọ́ wá sí ọ̀dọ̀ mi.

  10. Kí ẹ̀yin lè jẹ̀bi gbogbo ẹ̀jẹ̀ àwọn olódodo tí ẹ ta sílẹ̀ ní ayé, láti ẹ̀jẹ̀ Abeli títí dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah ọmọ Berekiah ẹni tí ẹ pa nínú tẹmpili láàrín ibi pẹpẹ àti ibi ti ẹ yà sí mímọ́ fún Ọlọ́run.

  11. láti ẹ̀jẹ̀ Abeli wá, títí ó sì fi dé ẹ̀jẹ̀ Sekariah, tí ó ṣègbé láàrín pẹpẹ àti tẹmpili. Lóòótọ́ ni mo wí fún yín ìran yìí ni yóò ru gbogbo ẹ̀bi àwọn nǹkan wọ̀nyí.