Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Unfaithfulness

106 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. “Nítorí náà èmi wí fún yín, a ó gba ìjọba Ọlọ́run lọ́wọ́ yín, a ó sì fi fún àwọn orílẹ̀-èdè tí yóò máa mú èso rẹ̀ wá.

  2. “Nígbà náà ni ó fi ìjọba ọ̀run wé àwọn wúńdíá mẹ́wàá. Ti wọ́n gbé fìtílà wọn láti lọ pàdé ọkọ ìyàwó.

  3. Márùn-ún nínú wọn jẹ́ ọlọ́gbọ́n, márùn-ún nínú wọn ni wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n.

  4. Àwọn tí wọ́n jẹ́ aláìgbọ́n gbé fìtílà wọn ṣùgbọ́n wọn kò mú epo kankan lọ́wọ́.

  5. Àwọn ọlọ́gbọ́n mú epo sínú kólòbó lọ́wọ́ pẹ̀lú fìtílà wọn.

  6. Nígbà tí ọkọ ìyàwó pẹ́, gbogbo wọn tòògbé wọn sì sùn.

  7. “Nígbà tí ó di ọ̀gànjọ́, igbe ta sókè, ‘Wò ó, ọkọ ìyàwó ń bọ̀, ẹ jáde sóde láti pàdé rẹ̀.’

  8. “Nígbà náà ni àwọn wúńdíá sì tají, wọ́n tún fìtílà wọn ṣe.

  9. Àwọn aláìgbọ́n márùn-ún tí kò ní epo rárá bẹ àwọn ọlọ́gbọ́n pé kí wọn fún àwọn nínú èyí tí wọ́n ní nítorí fìtílà wọn ń kú lọ.

  10. “Ṣùgbọ́n àwọn ọlọ́gbọ́n márùn-ún dáhùn pé, bẹ́ẹ̀ kọ́; kí ó má ba à ṣe aláìtó fún àwa àti ẹ̀yin, ẹ kúkú tọ àwọn tí ń tà á lọ, kí ẹ sì rà fún ara yín.

  11. “Ní àsìkò tí wọ́n lọ ra epo tiwọn, ni ọkọ ìyàwó dé. Àwọn wúńdíá tí ó múra tán bá a wọlé sí ibi àsè ìgbéyàwó, lẹ́yìn náà, a sì ti ìlẹ̀kùn.

  12. “Ní ìkẹyìn ni àwọn wúńdíá márùn-ún ìyókù dé, wọ́n ń wí pé, ‘Olúwa, Olúwa, ṣílẹ̀kùn fún wa.’

  13. “Ṣùgbọ́n ọkọ ìyàwó dáhùn pé, ‘Lóòótọ́ ni mo wí fún yín èmi kò mọ̀ yín rí.’

  14. “Nítorí náà, ẹ máa ṣọ́nà. Nítorí pé ẹ̀yin kò mọ ọjọ́ tàbí wákàtí tí Ọmọ Ènìyàn yóò dé.

  15. “A sì tún fi ìjọba ọ̀run wé ọkùnrin kan tí ó ń lọ sí ìrìnàjò. Ó pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀, ó sì kó ohun ìní rẹ̀ fún wọn.

  16. Ó fún ọ̀kan ni tálẹ́ǹtì márùn-ún, ó fún èkejì ni tálẹ́ǹtì méjì, ó sì fún ẹ̀kẹta ni tálẹ́ǹtì kan, ó fún olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí agbára rẹ̀ ti mọ, ó sì lọ ìrìnàjò tirẹ̀.

  17. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún bẹ̀rẹ̀ lẹ́sẹ̀kẹsẹ̀ láti fi owó náà ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè márùn-ún mìíràn.

  18. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì náà fi tirẹ̀ ṣòwò. Láìpẹ́, ó sì jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.

  19. Ṣùgbọ́n ọkùnrin tí ò gba tálẹ́ǹtì kan, ó wa ihò ní ilẹ̀, ó sì bo owó ọ̀gá mọ́ ibẹ̀.

  20. “Lẹ́yìn ọjọ́ pípẹ́, olúwa àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ dé láti àjò rẹ̀. Ó pè wọ́n jọ láti bá wọn ṣírò owó rẹ̀.

  21. Ọkùnrin tí ó gba tálẹ́ǹtì márùn-ún, mú márùn-ún mìíràn padà wá, ó wí pé, ‘Olúwa, ìwọ ti fi tálẹ́ǹtì márùn-ún fún mi, mo sì ti jèrè márùn-ún mìíràn pẹ̀lú rẹ̀.’

  22. “Olúwa rẹ̀ wí fún un pé, ‘O ṣeun ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́: ìwọ ṣe olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ́ ṣe olórí ohun púpọ̀, bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  23. “Èyí tí ó gba tálẹ́ǹtì méjì wí pé ‘Olúwa, ìwọ fún mi ní tálẹ́ǹtì méjì láti lò, èmi sì ti jèrè tálẹ́ǹtì méjì mìíràn.’

  24. “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere àti olóòtítọ́. Ìwọ ti jẹ́ olóòtítọ́ nínú ohun díẹ̀, èmi yóò fi ọ ṣe olórí ohun púpọ̀. Ìwọ bọ́ sínú ayọ̀ olúwa rẹ.’

  25. “Níkẹyìn, ọkùnrin tí a fún ní tálẹ́ǹtì kan wá, ó wí pé, ‘Olúwa, mo mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni ìwọ ń ṣe ìwọ ń kórè níbi tí ìwọ kò gbìn sí, ìwọ ń kójọ níbi tí ìwọ kò ó ká sí.