Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Unfaithfulness

106 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Lákokò ìkórè, ọkùnrin náà rán ọ̀kan nínú àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ sí àwọn olùṣọ́gbà náà, kí ó gbà nínú èso ọgbà àjàrà náà lọ́wọ́ àwọn olùṣọ́gbà.

  2. Ṣùgbọ́n àwọn àgbẹ̀ wọ̀n-ọn-nì lu ìránṣẹ́ ọkùnrin náà, wọ́n sì rán an padà lọ́wọ́ òfo.

  3. Ó sì tún rán ọmọ ọ̀dọ̀ mìíràn sí wọn. Bí àwọn àgbẹ̀ ti tún rí ọmọ ọ̀dọ̀ tí ó rán sí wọn; wọ́n lù ú. Àní, wọ́n tilẹ̀ dá ọgbẹ́ sí i lórí, wọn rán an lọ ni ìtìjú.

  4. Ó sì tún rán òmíràn, èyí n nì wọ́n sì pa, àti ọ̀pọ̀ mìíràn, wọ́n lu òmíràn wọ́n sì pa òmíràn.

  5. “Ìránṣẹ́ kan ṣoṣo ló kù tí Baba olóko kò ì tí ì rán níṣẹ́, èyí ni ọmọ òun tìkára rẹ̀. Níkẹyìn ó ran an sí àwọn olùṣọ́gbà náà, pẹ̀lú èrò pé, ‘Wọn yóò bu ọlá fún ọmọ òun.’

  6. “Ṣùgbọ́n àwọn olùṣọ́gbà wọ̀n-ọn-nì wí fún ara wọn pé, ‘Èyí yìí ni àrólé. Ẹ wá, ẹ jẹ́ kí a pa á, ogún rẹ̀ yóò sì jẹ́ tiwa.’

  7. Báyìí ni wọ́n mú ọmọ náà tí wọ́n pa á. Wọ́n sì wọ́ òkú rẹ̀ jáde kúrò nínú ọgbà àjàrà náà.

  8. “Kí ni olúwa ọgbà àjàrà yóò ṣe nígbà tí ó bá gbọ́ ohun tí ó ṣẹlẹ̀. Dájúdájú yóò pa àwọn ẹni ibi wọ̀nyí. Yóò sì gba àwọn olùtọ́jú mìíràn sínú oko rẹ̀.

  9. Ó sì pa òwe yìí fún wọn pé, “Ọkùnrin kan ní igi ọ̀pọ̀tọ́ kan tí a gbìn sí ọgbà àjàrà rẹ̀; ó sì dé, ó ń wá èso lórí rẹ̀, kò sì rí nǹkan.

  10. Ó sì wí fún olùṣọ́gbà rẹ̀ pé, ‘Sá à wò ó, láti ọdún mẹ́ta ni èmi ti ń wá í wo èso lórí igi ọ̀pọ̀tọ́ yìí, èmi kò sì rí nǹkan: ké e lulẹ̀; èéṣe tí ó fi ń gbilẹ̀ lásán pẹ̀lú?’

  11. “Ó sì dáhùn ó wí fún un pé, ‘Olúwa, jọ̀wọ́ rẹ̀ ní ọdún yìí pẹ̀lú, títí èmi ó fi tu ilẹ̀ ìdí rẹ̀ yíká, títí èmi ó sì fi bu ìlẹ̀dú sí i.

  12. Bí ó bá sì so èso, o dara bẹ́ẹ̀: bí kò bá sì so, ǹjẹ́ lẹ́yìn èyí nì kí ìwọ kí ó ké e lulẹ̀.’ ”

  13. Ó sì wí pé, “Ọkùnrin ọlọ́lá kan lọ sí ìlú òkèrè láti gba ìjọba kí ó sì padà.

  14. Ó sì pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ rẹ̀ mẹ́wàá, ó fi owó mina mẹ́wàá fún wọn, ó sì wí fún wọn pé, ‘Ẹ máa ṣòwò títí èmi ó fi dé!’

  15. “Ṣùgbọ́n àwọn ará ìlù rẹ̀ kórìíra rẹ̀, wọ́n sì rán ikọ̀ tẹ̀lé e, wí pé, ‘Àwa kò fẹ́ kí ọkùnrin yìí jẹ ọba lórí wa.’

  16. “Nígbà tí ó gba ìjọba tan, tí ó padà dé, ó pàṣẹ pé, kí a pe àwọn ọmọ ọ̀dọ̀ wọ̀nyí tí òun ti fi owó fún wá sọ́dọ̀ rẹ̀, nítorí kí ó le mọ iye èrè tí olúkúlùkù ti jẹ nínú iṣẹ́ òwò wọn.

  17. “Èyí èkínní sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina mẹ́wàá sí i.’

  18. “Olúwa rẹ̀ sì wí fún un pé, ‘O ṣeun, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ rere! Nítorí tí ìwọ ṣe olóòtítọ́ ní ohun kínkínní, gba àṣẹ lórí ìlú mẹ́wàá.’

  19. “Èyí èkejì sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, owó mina rẹ jèrè owó mina márùn.’

  20. “Olúwa rẹ sì wí fún un pẹ̀lú pé, ‘Ìwọ pẹ̀lú joyè ìlú márùn-ún!’

  21. “Òmíràn sì wá, ó wí pé, ‘Olúwa, wò ó owó mina rẹ tí ń bẹ lọ́wọ́ mi ni mo dì sínú aṣọ pélébé kan;

  22. nítorí mo bẹ̀rù rẹ, àti nítorí tí ìwọ ṣe òǹrorò ènìyàn, ìwọ a máa mú èyí tí ìwọ kò fi lélẹ̀, ìwọ a sì máa ká èyí tí ìwọ kò gbìn!’

  23. “Olúwa rẹ sì wí fún un pé, ‘Ní ẹnu ara rẹ náà ni èmi ó ṣe ìdájọ́ rẹ, ìwọ ọmọ ọ̀dọ̀ búburú, ìwọ mọ̀ pé òǹrorò ènìyàn ni mí, pé, èmi a máa mú èyí tí èmi kò fi lélẹ̀ èmi a sì máa ká èyí tí èmi kò gbìn.

  24. Èéha sì ti ṣe tí ìwọ kò fi owó mi pamọ́ sí ilé ìfowópamọ́, pé nígbà tí mo bá dé, èmi ìbá ti béèrè rẹ̀ pẹ̀lú èlé?’

  25. “Ó sì wí fún àwọn tí ó dúró létí ibẹ̀ pé, ‘Ẹ gba owó mina náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí ẹ sì fi í fún ẹni tí ó ní owó mina mẹ́wàá.’