Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Uncharitableness

44 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí ìdí èyí náà ni Kristi ṣe kú, tí ó sì tún yè, kí ó bá le jẹ́ Olúwa òkú àti alààyè.

  2. Èéṣe nígbà náà tí ìwọ fi ń dá arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ lẹ́jọ́? Tàbí èéṣe tí ìwọ fi ń gàn wọn? Nítorí gbogbo wa ni yóò dúró níwájú ìtẹ́ ìdájọ́ Ọlọ́run.

  3. A ti kọ ìwé rẹ̀ pé: “ ‘Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè,’ ni Olúwa wí, ‘gbogbo eékún ni yóò wólẹ̀ fún mi; gbogbo ahọ́n ni yóò jẹ́wọ́ fún Ọlọ́run.’ ”

  4. Ǹjẹ́ nítorí náà, olúkúlùkù wa ni yóò jíyìn ara rẹ̀ fún Ọlọ́run.

  5. Nítorí náà, ẹ má ṣe tún jẹ́ kí a máa dá ara wa lẹ́jọ́ mọ́. Ṣùgbọ́n dípò bẹ́ẹ̀, ẹ pinu nínú ọkàn yín láti má ṣe fi ohun ìkọ̀sẹ̀ tàbí òkúta ìdìgbòlù kankan sí ọ̀nà arákùnrin tàbí arábìnrin yín.

  6. Mo mọ̀ dájú gbangba bí ẹni tí ó wà nínú Jesu Olúwa pé, kò sí ohun tó ṣe àìmọ́ fún ara rẹ̀. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ka ohunkóhun sí àìmọ́, òun ni ó ṣe àìmọ́ fún.

  7. Bí inú arákùnrin tàbí arábìnrin rẹ ba bàjẹ́ nítorí oúnjẹ rẹ, ìwọ kò rìn nínú ìfẹ́ mọ́. Má ṣe fi oúnjẹ rẹ sọ ẹni tí Kristi kú fún di ẹni ègbé.

  8. Ṣùgbọ́n ohun kíkíní ni fún mi pé, kí ẹ máa ṣe ìdájọ́ mi, tàbí kí a máa ṣe ìdájọ́ nípa ìdájọ́ ènìyàn; nítòótọ́, èmi kò tilẹ̀ dá ara mi lẹ́jọ́.

  9. Nítorí tí ẹ̀rí ọkàn mi kò dá mi ní ẹ̀bi; ṣùgbọ́n a kò ti ipa èyí dá mi láre, ṣùgbọ́n Olúwa ni ẹni tí ń ṣe ìdájọ́ mi.

  10. Nítorí náà, kí ẹ má ṣe ṣe ìdájọ́ ohunkóhun, kí Olúwa tó padà dé, ẹni tí yóò mú ohunkóhun tí ó fi ara sin wá sí ìmọ́lẹ̀, tí yóò sì fi ìmọ̀ ọkàn ènìyàn hàn, nígbà náà ni olúkúlùkù yóò sì ní ìyìn tirẹ̀ lọ́dọ̀ Ọlọ́run.

  11. Nítorí ta ni ó mú ọ yàtọ̀ sí àwọn ẹlòmíràn? Kí ni ìwọ ni tí ìwọ kò rí gbà? Tí ìwọ ba sì gbà á, èétiṣe tí ìwọ fi ń halẹ̀ bí ẹni pé ìwọ kò gba á?

  12. Bí èmi tilẹ̀ lè sọ oríṣìíríṣìí èdè tí ènìyàn àti ti angẹli, tí n kò bá sì ní ìfẹ́, mo kàn ń pariwo bí ago lásán ni tàbí bí i kimbali olóhùn gooro.

  13. Bí mo bá ní ẹ̀bùn ìsọtẹ́lẹ̀, tí mo sì ní òye gbogbo ohun ìjìnlẹ̀, àti gbogbo ìmọ̀, bí mo sì ni gbogbo ìgbàgbọ́ tó bẹ́ẹ̀ tí mo lè ṣí àwọn òkè ńlá nídìí, tí èmi kò sì ní ìfẹ́, èmi kò jẹ nǹkan kan.

  14. Bí mo bá fi gbogbo nǹkan tí mo ní tọrẹ fún àwọn aláìní, tí mo sì fi ara mi fún ni láti sùn ṣùgbọ́n tí n kò ní ìfẹ́, kò ní èrè kan fún mi.

  15. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  16. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

  17. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo.

  18. Ará, ẹ má ṣe sọ̀rọ̀ ibi sí ara yín. Ẹni tí ó bá ń sọ̀rọ̀ ibi sí arákùnrin rẹ̀, tí ó ń dá arákùnrin rẹ̀ lẹ́jọ́, ó ń sọ̀rọ̀ ibi sí òfin, ó sì ń dá òfin lẹ́jọ́; ṣùgbọ́n bí ìwọ bá ń dá òfin lẹ́jọ́, ìwọ kì í ṣe olùfẹ́ òfin, bí kò ṣe onídàájọ́.

  19. Aṣòfin àti onídàájọ́ kan ṣoṣo ní ó ń bẹ, àní ẹni tí ó lè gbàlà tí ó sì le parun, ṣùgbọ́n ta ni ìwọ tí ó ń dá ẹnìkejì rẹ lẹ́jọ́?