Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sidonians: Hostile and oppressive to God's people

5 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Hostile and oppressive to God's people

  1. àwọn ará Sidoni, Amaleki pẹ̀lú Maoni ni yín lára, tí ẹ sì ké pè mí fún ìrànlọ́wọ́, ǹjẹ́ èmi kò gbà yín sílẹ̀ kúrò ní ọwọ́ wọn?

  2. kí ó sì wí pé, ‘Báyìí ni Olúwa Olódùmarè wí: “ ‘Èmi lòdì sí ọ, ìwọ Sidoni, a ó sì ṣe mí lógo láàrín rẹ. Wọn yóò mọ̀ pé èmi ní Olúwa, nígbà tí mo bá mú ìdájọ́ mi ṣẹ nínú rẹ, tí a sì yá mí sí mímọ́ nínú rẹ.

  3. “ ‘Kì yóò sì ṣí ẹ̀gún tí ń gun ni ní ilẹ̀ Israẹli mọ́, tàbí ẹ̀gún bíbani nínú jẹ́ ti gbogbo àwọn tí wọn wà ní àyíká wọn, tí wọ́n sì ń fi ojú yẹpẹrẹ wò wọ́n, nígbà náà ni wọn yóò mọ́ wí pé èmi ni Olúwa Olódùmarè.

  4. Nítorí tí ẹ̀yin tí mú fàdákà mi àti wúrà mi, ẹ̀yin si tí mú ohun rere dáradára mi lọ sínú tẹmpili yín.

  5. Àti àwọn ọmọ Juda, àti àwọn ọmọ Jerusalẹmu ní ẹ̀yin ti tà fún àwọn ará Giriki, kí ẹ̀yin bá à lè sí wọn jìnnà kúrò ní agbègbè ilẹ̀ ìní wọn.