Skip to content

Ashtoreth

3 ẹsẹ

Àwọn ẹsẹ tí ó mẹ́nu kan Ashtoreth

  1. Solomoni tọ Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni lẹ́yìn, àti Moleki òrìṣà ìríra àwọn ọmọ Ammoni.

  2. Èmi yóò ṣe èyí nítorí tí wọ́n ti kọ̀ mí sílẹ̀, wọ́n sì ti sin Aṣtoreti òrìṣà àwọn ará Sidoni, Kemoṣi òrìṣà àwọn ará Moabu, àti Moleki òrìṣà àwọn ọmọ Ammoni, wọn kò sì rìn ní ọ̀nà mi, tàbí ṣe èyí tí ó dára lójú mi, tàbí pa àṣẹ àti òfin mi mọ́ bí Dafidi baba Solomoni ti ṣe.

  3. Ọba pẹ̀lú ba ohun mímọ́ àwọn ibi gíga jẹ́ tí ó wà ní ìhà ìlà-oòrùn Jerusalẹmu ní ìhà gúúsù ti òkè ìbàjẹ́—èyí tí Solomoni ọba Israẹli ti kọ́ fún Aṣtoreti ọlọ́run ìríra àwọn ará Sidoni, fún Kemoṣi ọlọ́run ìríra àwọn ará Moabu àti fún Moleki, ọlọ́run ìríra àwọn ènìyàn Ammoni.