Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sea: Set bounds to, by a perpetual decree
Àwọn ẹsẹ nípa Set bounds to, by a perpetual decree
Ó fi ìdè yí omi òkun ká, títí dé ààlà ìmọ́lẹ̀ àti òkùnkùn.
“Tàbí ta ni ó fi ìlẹ̀kùn sé omi òkun mọ́, nígbà tí ó ya padà bí ẹni pé ó ti inú jáde wá.
Nígbà tí mo ti pàṣẹ ìpinnu mi fún un, tí mo sì ṣe bèbè àti ìlẹ̀kùn.
Tí mo sì wí pé níhìn-ín ni ìwọ ó dé, kí o má sì rékọjá, níhìn-ín sì ni ìgbéraga rẹ yóò gbé dúró mọ?
Mo wà níbẹ̀ nígbà tí ó fi àwọn ọ̀run sí ipò wọn, nígbà tí ó fi òsùwọ̀n àyíká sórí ibú omi,
nígbà tí ó ṣe ààlà fún omi Òkun kí omi má ba à kọjá ààlà àṣẹ rẹ̀, àti nígbà tí ó pààlà ìpìlẹ̀ ayé.