Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Sea: Red Sea

3 ẹsẹ · 55 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Red Sea

  1. Olúwa sì yí afẹ́fẹ́ náà padà di afẹ́fẹ́ líle láti apá ìwọ̀-oòrùn wá láti gbá àwọn eṣú náà kúrò ní orí ilẹ̀ Ejibiti lọ sínú Òkun Pupa. Bẹ́ẹ̀ ni ẹyọ eṣú kan kò ṣẹ́kù sí orí ilẹ̀ Ejibiti.

  2. Nítorí náà Ọlọ́run darí àwọn ènìyàn rọkọ gba ọ̀nà aginjù ní apá Òkun Pupa. Àwọn ọmọ Israẹli jáde kúrò ní ilẹ̀ Ejibiti pẹ̀lú ìmúra fún ogun.

  3. “Èmi yóò fi ìdí òpin ààlà ilẹ̀ rẹ lélẹ̀ láti etí Òkun Pupa títí dé òkun àwọn ara Filistini, láti aṣálẹ̀ títí dé etí odò Eufurate, Èmi yóò fa àwọn ènìyàn ti ń gbé ilẹ̀ náà lé ọ lọ́wọ́, ìwọ yóò sì lé wọn jáde kúrò ní iwájú rẹ.