Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Miracles of Christ: The blind restored to sight

15 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ nípa The blind restored to sight

  1. Nígbà tí Jesu sì jáde níbẹ̀, àwọn ọkùnrin afọ́jú méjì tọ̀ ọ́ lẹ́yìn, wọ́n ń kígbe sókè wí pé, “Ṣàánú fún wa, ìwọ ọmọ Dafidi.”

  2. Nígbà tí ó sì wọ̀ ilé, àwọn afọ́jú náà tọ̀ ọ́ wá, Jesu bi wọ́n pé, “Ẹ̀yin gbàgbọ́ pé mo le ṣe èyí?” Wọn sì wí fún un pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, ìwọ lè ṣe é.”

  3. Ó sì fi ọwọ́ bà wọ́n ní ojú, ó wí pé, “Kí ó rí fún yín gẹ́gẹ́ bí ìgbàgbọ́ yín.”

  4. Ojú wọn sì là; Jesu sì kìlọ̀ fún wọn gidigidi, wí pé, “Kíyèsi i, kí ẹ má ṣe jẹ́ kí ẹnìkan kí ó mọ̀ nípa èyí.”

  5. Nígbà tí wọ́n dé Betisaida, àwọn ènìyàn kan mú afọ́jú kan wá sọ́dọ̀ rẹ̀. Wọ́n bẹ̀ ẹ́ kí ó fi ọwọ́ kàn án, kí ó sì wò ó sàn.

  6. Jesu fa ọkùnrin náà lọ́wọ́, ó sì mú un jáde lọ sí ẹ̀yìn ìlú. Ó tu itọ́ sí i lójú. Ó sì gbé ọwọ́ rẹ̀ lé ojú náà. Ó sì bi í léèrè pé, “Ǹjẹ́ ìwọ lè rí ohunkóhun nísinsin yìí?”

  7. Ọkùnrin náà wo àyíká rẹ̀, ó sì dáhùn pé, “Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa, mo rí àwọn ènìyàn, ṣùgbọ́n n kò rí wọn kedere, wọ́n n rìn kiri bí àgékù igi.”

  8. Nígbà náà, Jesu tún gbé ọwọ́ rẹ̀ méjèèjì lé àwọn ojú ọkùnrin náà, bí ọkùnrin náà sì ti ranjú mọ́ ọn, a dá ìran rẹ̀ padà, ó sì rí gbogbo nǹkan kedere.

  9. Bí ó sì ti ń kọjá lọ, ó rí ọkùnrin kan tí ó fọ́jú láti ìgbà ìbí rẹ̀ wá.

  10. Àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ sì bi í léèrè, pé, “Rabbi, ta ní ó dẹ́ṣẹ̀, ọkùnrin yìí tàbí àwọn òbí rẹ̀, tí a fi bí i ní afọ́jú?”

  11. Jesu dáhùn pé, “Kì í ṣe nítorí pé ọkùnrin yìí dẹ́ṣẹ̀, tàbí àwọn òbí rẹ̀: ṣùgbọ́n kí a ba à lè fi iṣẹ́ Ọlọ́run hàn lára rẹ̀.

  12. Èmi ní láti ṣe iṣẹ́ ẹni tí ó rán mi, níwọ̀n ìgbà tí ó bá ti jẹ́ ọ̀sán, òru ń bọ̀ wá nígbà tí ẹnìkan kì yóò lè ṣe iṣẹ́.

  13. Níwọ́n ìgbà tí mo wà láààyè, èmi ni ìmọ́lẹ̀ ayé.”

  14. Nígbà tí ó ti wí bẹ́ẹ̀ tan, ó tutọ́ sílẹ̀, ó sì fi itọ́ náà ṣe amọ̀, ó sì fi amọ̀ náà ra ojú afọ́jú náà.

  15. Ó sì wí fún un pé, “Lọ wẹ̀ nínú adágún Siloamu!” (Ìtumọ̀ ọ̀rọ̀ yìí ni “rán”). Nítorí náà ó gba ọ̀nà rẹ̀ lọ, ó wẹ̀, ó sì dé, ó ń ríran.