Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Canaanites

62 ẹsẹ · 30 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n nítorí àwọn ará Aṣeri ń gbé láàrín àwọn ará Kenaani tí wọ́n ni ilẹ̀ náà.

  2. Àwọn ẹ̀yà Naftali pẹ̀lú kò lé àwọn ará Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati jáde; ṣùgbọ́n àwọn ẹ̀yà Naftali náà ń gbé àárín àwọn ará Kenaani tí ó ti ní ilẹ̀ náà rí, ṣùgbọ́n àwọn tí ń gbé Beti-Ṣemeṣi àti Beti-Anati ń sìn ìsìn tipátipá.

  3. Àwọn ará Amori fi agbára dá àwọn ẹ̀yà Dani dúró sí àwọn ìlú orí òkè, wọn kò sì jẹ́ kí wọn sọ̀kalẹ̀ wá sí pẹ̀tẹ́lẹ̀.

  4. Àwọn ará Amori ti pinnu láti dúró lórí òkè Heresi àti òkè Aijaloni àti ti Ṣaalbimu, ṣùgbọ́n nígbà tí ẹ̀yà Josẹfu di alágbára wọ́n borí Amori wọ́n sì mú wọn sìn.

  5. Ààlà àwọn ará Amori sì bẹ̀rẹ̀ láti ìgòkè Akrabbimu kọjá lọ sí Sela àti síwájú sí i.

  6. Àwọn wọ̀nyí ni àwọn orílẹ̀-èdè tí Olúwa fi sílẹ̀ láti dán àwọn ìran tuntun ní Israẹli wò, àwọn ìran tí kò ì tí ì ní ìrírí ogun àwọn ará Kenaani.

  7. (Ó ṣe èyí láti fi kọ́ àwọn ìran Israẹli tí kò rí ogun rí níbí a ti ṣe ń jagun).

  8. Àwọn ìjòyè ìlú Filistini márààrún, gbogbo àwọn ará Kenaani, àwọn ará Sidoni, àti àwọn ará Hifi tí ń gbé ní àwọn òkè Lebanoni bẹ̀rẹ̀ láti òkè Baali-Hermoni títí dé Lebo-Hamati.

  9. A fi àwọn ènìyàn náà sílẹ̀ láti dán àwọn Israẹli wò bóyá wọn yóò gbọ́rọ̀ sí àwọn òfin Olúwa, èyí tí ó ti fi fún àwọn baba wọn láti ipasẹ̀ Mose.

  10. Wọ́n sì sin àwọn òrìṣà wọn tí ó di ìkẹ́kùn fún wọn.

  11. Wọ́n fi àwọn ọmọkùnrin wọn rú ẹbọ àti àwọn ọmọbìnrin fún òrìṣà.

  12. Wọ́n ta ẹ̀jẹ̀ aláìṣẹ̀ sílẹ̀, ẹ̀jẹ̀ àwọn ọmọkùnrin àti àwọn ọmọbìnrin wọ. Wọ́n fi wọ́n rú ẹbọ sí ère Kenaani, ilẹ̀ náà sì di àìmọ́ fún ẹ̀jẹ̀.