Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa The Apostles

43 ẹsẹ · 26 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ohun tí mo bá wí fún yín ní òkùnkùn, òun ni kí ẹ sọ ní ìmọ́lẹ̀. Èyí tí mo sọ kẹ́lẹ́kẹ́lẹ́ sì etí yín ni kí ẹ kéde rẹ́ lórí òrùlé.

  2. Ẹ má ṣe bẹ̀rù àwọn tí ó le pa ara nìkan; ṣùgbọ́n tí wọn kò lè pa ẹ̀mí. Ẹ bẹ̀rù Ẹni tí ó le pa ẹ̀mí àti ara run ní ọ̀run àpáàdì.

  3. Ológoṣẹ́ méjì kọ́ ni à ń tà ní owó idẹ wẹ́wẹ́ kan? Síbẹ̀ kò sí ọ̀kan nínú wọn tí yóò ṣubú lu ilẹ̀ lẹ́yìn Baba yin.

  4. Àti pé gbogbo irun orí yín ni a ti kà pé.

  5. Nítorí náà, ẹ má ṣe fòyà; ẹ̀yin ní iye lórí ju ọ̀pọ̀ ológoṣẹ́ lọ.

  6. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá jẹ́wọ́ mi níwájú ènìyàn, òun náà ni èmi yóò jẹ́wọ́ rẹ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

  7. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sẹ́ mí níwájú àwọn ènìyàn, òun náà ni èmi náà yóò sọ wí pé n kò mọ̀ níwájú Baba mi ní ọ̀run.

  8. “Ẹni tí ó bá fẹ́ baba rẹ̀ tàbí ìyá rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi, ẹni tí ó ba fẹ́ ọmọkùnrin tàbí ọmọbìnrin rẹ̀ jù mí lọ, kò yẹ ní tèmi.

  9. Ẹni tí kò bá gbé àgbélébùú rẹ̀ kí ó tẹ̀lé mi kò yẹ ní tèmi.

  10. Ẹni tí ó bá wa ẹ̀mí rẹ̀ yóò sọ ọ́ nù, ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá sọ ẹ̀mí rẹ̀ nú nítorí tèmi ni yóò rí i.

  11. Wọ́n dé sí Kapernaumu. Lẹ́yìn tí wọ́n sinmi tán nínú ilé tí wọ́n wọ̀, Jesu béèrè lọ́wọ́ wọn pé, “Kí ni ohun tí ẹ́ ń bá ara yín jiyàn lé lórí?”

  12. Ṣùgbọ́n wọ́n dákẹ́; nítorí wọn ti ń bá ara wọn jiyàn pé, ta ni ẹni tí ó pọ̀jù?

  13. Ó jókòó, ó sì pè àwọn méjìlá náà, ó sọ fún wọn pé, “Bí ẹnikẹ́ni bá fẹ́ ṣe ẹni ìṣáájú, òun ni yóò ṣe ẹni ìkẹyìn gbogbo wọn. Ó ní láti jẹ́ ìránṣẹ́ gbogbo ènìyàn.”

  14. Ó sì mú ọmọ kékeré kan, ó fi sáàárín wọn, nígbà tí ó sì gbé e sí apá rẹ̀, ó wí fún wọn pé,

  15. “Ẹnikẹ́ni tí ó bá tẹ́wọ́gbà ọmọ kékeré bí èyí ní orúkọ mi, òun gbà mí. Ẹnikẹ́ni tí ó bá sì gbà mi, ó gba Baba mi, tí ó rán mi.”

  16. Ìjà kan sì ń bẹ láàrín wọn, ní ti ẹni tí a kà sí olórí nínú wọn.

  17. Ó sì wí fún wọn pé, “Àwọn ọba aláìkọlà a máa fẹlá lórí wọn, a sì máa pe àwọn aláṣẹ wọn ní olóore.

  18. Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kì yóò rí bẹ́ẹ̀; ṣùgbọ́n ẹni tí ó ba pọ̀jù nínú yín kí ó jẹ́ bí ẹni tí o kéré ju àbúrò; ẹni tí ó sì ṣe olórí, bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.

  19. Nítorí ta ni ó pọ̀jù, ẹni tí ó jókòó tí oúnjẹ, tàbí ẹni tí ó ń ṣe ìránṣẹ́. Ẹni tí ó jókòó ti oúnjẹ kọ́ bí? Ṣùgbọ́n èmi ń bẹ láàrín yín bí ẹni tí ń ṣe ìránṣẹ́.

  20. Ẹ̀yin ni àwọn tí ó ti dúró tì mí nínú ìdánwò mi.

  21. Mo sì yan ìjọba fún yín, gẹ́gẹ́ bí Baba mi ti yàn fún mi.

  22. Kí ẹ̀yin lè máa jẹ, kí ẹ̀yin sì lè máa mu lórí tábìlì mi ní ìjọba mi, kí ẹ̀yin lè jókòó lórí ìtẹ́, àti kí ẹ̀yin lè máa ṣe ìdájọ́ fún àwọn ẹ̀yà Israẹli méjìlá.”

  23. Wọ́n sì dìde ní wákàtí kan náà, wọ́n padà lọ sí Jerusalẹmu, wọ́n sì bá àwọn mọ́kànlá péjọ, àti àwọn tí ń bẹ lọ́dọ̀ wọn.

  24. Wọn si wí pé, “Olúwa jíǹde nítòótọ́, ó sì ti fi ara hàn fún Simoni!”

  25. Àwọn náà sì ròyìn nǹkan tí ó ṣe ní ọ̀nà, àti bí ó ti di mí mọ̀ fún wọn ní bíbu àkàrà.