Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Shoes: Never wore, in mourning

5 ẹsẹ · 23 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Never wore, in mourning

  1. Dafidi sì ń gòkè lọ ní òkè igi olifi, o sì ń sọkún bí ó ti ń gòkè lọ, ó sì bo orí rẹ̀, ó ń lọ láìní bàtà ní ẹsẹ̀, gbogbo ènìyàn tí o wà lọ́dọ̀ rẹ̀, olúkúlùkù ọkùnrin sì bo orí rẹ̀, wọ́n sì ń gòkè lọ, wọ́n ń sọkún bí wọ́n ti ń gòkè lọ.

  2. ní àkókò náà ni ọ̀rọ̀ Olúwa ti ẹnu Isaiah ọmọ Amosi jáde. Ó sọ fún un pé, “Mú aṣọ ọ̀fọ̀ kúrò ní ara rẹ kí o sì bọ́ sálúbàtà kúrò ní ẹsẹ̀ rẹ.” Ó sì ṣe bẹ́ẹ̀, ó ń lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà.

  3. Lẹ́yìn náà ni Olúwa wí pé, “Gẹ́gẹ́ bí ìránṣẹ́ mi Isaiah ti lọ káàkiri ní ìhòhò àti láì wọ bàtà fún ọdún mẹ́ta, gẹ́gẹ́ bí àmì àti àpẹẹrẹ sí Ejibiti àti Kuṣi,

  4. Má ṣe sọkún, má ṣe gbààwẹ̀ fún òkú. Wé ọ̀já sí orí rẹ, sì bọ bàtà sí ẹsẹ̀ rẹ, má ṣe bo ètè ìsàlẹ̀ rẹ, ma ṣe jẹ oúnjẹ tí àwọn tí ń ṣọ̀fọ̀ ń jẹ gẹ́gẹ́ bí àṣà.”

  5. Ẹ̀yin yóò fi àwọn ọ̀já wé àwọn orí yín àti àwọn bàtà ni ẹsẹ̀ yín, ẹ̀yin kì yóò ṣọ̀fọ̀ tàbí sọkún, ṣùgbọ́n ẹ̀yin yóò ṣòfò dànù nítorí àwọn àìṣedéédéé yín, ẹ̀yin yóò sì máa kérora láàrín ara yín.