Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Seraiah

13 ẹsẹ · 7 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Sadoku ọmọ Ahitubu, àti Ahimeleki ọmọ Abiatari, ni àwọn àlùfáà; Seraiah a sì máa ṣe akọ̀wé.

  2. Ṣefa sì jẹ́ akọ̀wé; Sadoku àti Abiatari sì ni àwọn àlùfáà.

  3. Elihorefu àti Ahijah àwọn ọmọ Ṣisa akọ̀wé; Jehoṣafati ọmọ Ahiludi ni akọ̀wé ìlú;

  4. Nígbà tí gbogbo àwọn olórí ogun àti àwọn ọkùnrin wọn gbọ́ pé ọba Babeli ti yan Gedaliah gẹ́gẹ́ bí baálẹ̀, wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ni Mispa. Iṣmaeli ọmọ Netaniah, Johanani ọmọ Karea, Seraiah ọmọ Tanhumeti ará Netofa, Jaaṣaniah ọmọ ará Maakati, àti àwọn ọkùnrin wọn.

  5. Àwọn ọmọ Kenasi: Otnieli àti Seraiah. Àwọn ọmọ Otnieli: Hatati àti Meonotai.

  6. Meonotai sì ni baba Ofira. Seraiah sì jẹ́ baba Joabu, baba Geharaṣinu. A pè báyìí nítorí àwọn ènìyàn àwọn oníṣọ̀nà ní ìwọ̀n.

  7. Joẹli, Jehu ọmọ Josibiah, ọmọ Seraiah, ọmọ Asieli,

  8. Sadoku ọmọ Ahitubu àti Abimeleki ọmọ Abiatari jẹ́ àwọn àlùfáà; Ṣafṣa jẹ́ akọ̀wé;

  9. Seraiah ọmọ Hilkiah, ọmọ Meṣullamu, ọmọ Sadoku, ọmọ Meraioti, ọmọ Ahitubu, àwọn ni olórí tó ń bojútó ilé Ọlọ́run,

  10. Dípò èyí ọba pàṣẹ fún Jerahmeeli ọmọ Hameleki, Seraiah ọmọ Asrieli àti Ṣelemiah ọmọ Abdeeli láti mú Baruku akọ̀wé àti Jeremiah wòlíì ṣùgbọ́n Olúwa fi wọ́n pamọ́.

  11. wọ́n wá sí ọ̀dọ̀ Gedaliah ní Mispa; Iṣmaeli ọmọkùnrin Netaniah, Johanani àti Jonatani ọmọkùnrin ti Karea, Seraiah ọmọkùnrin Tanhumeti tí í ṣe ọmọkùnrin Efai ará Netofa àti Jesaniah ọmọkùnrin Maakati àti àwọn ènìyàn wọn.

  12. Ọ̀rọ̀ tí Jeremiah wòlíì pàṣẹ fún Seraiah, ọmọ Neriah, ọmọ Maseiah, nígbà tí o ń lọ ni ti Sedekiah, ọba Juda, sí Babeli ní ọdún kẹrin ìjọba rẹ̀. Seraiah yìí sì ní ìjòyè ibùdó.

  13. Jeremiah sì sọ fún Seraiah pé, “Nígbà tí ìwọ bá dé Babeli, kí ìwọ kí ó sì wò, kí ìwọ kí ó sì ka gbogbo ọ̀rọ̀ wọ̀nyí.