Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Procrastination

64 ẹsẹ · 15 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ṣùgbọ́n ẹ máa gba ara yín ní ìyànjú ní ojoojúmọ́, níwọ̀n ìgbà tí a bá ń pè ní “Òní,” kí a má ba à sé ọkàn ẹnikẹ́ni nínú yín le nípa ẹ̀tàn ẹ̀ṣẹ̀.

  2. Nítorí àwa di alábápín pẹ̀lú Kristi, bí àwa bá di ìpilẹ̀ṣẹ̀ ìgbẹ́kẹ̀lé wa mú ṣinṣin títí dé òpin.

  3. Nígbà tí a ń wí pé, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má sé ọkàn yin le, bí ìgbà ìṣọ̀tẹ̀.”

  4. Àwọn ta ni ó gbọ́ tí ó sì tún ṣọ̀tẹ̀? Kì í ha ṣe gbogbo àwọn tí o jáde kúrò ní Ejibiti ní abẹ́ àkóso Mose?

  5. Àwọn ta ni ó sì bínú sí fún ogójì ọdún? Kì í ha ṣe sí àwọn tí ó dẹ́ṣẹ̀, òkú àwọn tí ó sùn ní aginjù?

  6. Àwọn wo ni ó búra fún pé wọn kì yóò wọ inú ìsinmi òun, bí kò ṣe fún àwọn tí ó ṣe àìgbọ́ràn?

  7. Àwa sì rí i pé wọn kò lè wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbàgbọ́.

  8. Nítorí náà, gẹ́gẹ́ bí Ọlọ́run ti ṣe ìlérí àtiwọ inú ìsinmi rẹ̀ fún wa, ẹ jẹ́ kí á bẹ̀rù, kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ba à dàbí ẹni pé ó tí kùnà rẹ̀.

  9. Nítorí tí àwa gbọ́ ìwàásù ìyìnrere, gẹ́gẹ́ bí a ti wàásù rẹ̀ fún àwọn náà pẹ̀lú, ṣùgbọ́n ọ̀rọ̀ tí wọ́n gbọ́ kò ṣe wọ́n ní àǹfààní, nítorí tí kò dàpọ̀ mọ́ ìgbàgbọ́ nínú àwọn tí ó gbọ́ ọ.

  10. Nítorí pé àwa tí ó ti gbàgbọ́ wọ inú ìsinmi gẹ́gẹ́ bí ó tí wí, “Bí mo tí búra nínú ìbínú mi, ‘Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.’ ” Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé a tí parí iṣẹ́ wọ̀nyí láti ìpìlẹ̀ ayé.

  11. Nítorí ó ti sọ níbìkan ní ti ọjọ́ keje báyìí pé, “Ọlọ́run sì sinmi ní ọjọ́ keje kúrò nínú iṣẹ́ rẹ̀ gbogbo.”

  12. Àti níhìn-ín yìí pẹ̀lú ó wí pé, “Wọn kì yóò wọ inú ìsinmi mi.”

  13. Nítorí náà bí ó tí jẹ́ pé, ó ku kí àwọn kan wọ inú rẹ̀, àti àwọn tí a ti wàásù ìyìnrere náà fún ní ìṣáájú kò wọ inú rẹ̀ nítorí àìgbọ́ràn.

  14. Àti pé, ó yan ọjọ́ kan, ó wí nínú ìwé Dafidi pé, “Lónìí,” lẹ́yìn ìgbà pípẹ́ bẹ́ẹ̀; bí a tí wí níṣàájú, “Lónìí bí ẹ̀yin bá gbọ́ ohùn rẹ̀, ẹ má ṣe sé ọkàn yín le.”