Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Precious Stones

64 ẹsẹ · 52 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Wọ́n sì rí Ọlọ́run Israẹli. Ní abẹ́ ẹsẹ̀ rẹ̀ ni ohun kan bí i pèpéle ti a fi òkúta safire ṣe wà. Èyí ti ó mọ́ nigínnigín bí àwọ̀ sánmọ̀ fúnra rẹ̀.

  2. àti òkúta óníkìsì àti òkúta olówó iyebíye ti a fi ṣe ọ̀ṣọ́ sí ara ẹ̀wù efodu àti ẹ̀wù ìgbàyà.

  3. “Ìwọ yóò sì mú òkúta óníkìsì méjì, ìwọ yóò sì fín orúkọ àwọn ọmọ Israẹli sára wọn.

  4. Iṣẹ́ ọnà òkúta fínfín, bí ìfín èdìdì àmì, ni ìwọ yóò fún òkúta méjèèjì gẹ́gẹ́ bí orúkọ àwọn ọmọ Israẹli: ìwọ yóò sì dè wọ́n sí ojú ìdè wúrà.

  5. Ìwọ yóò sì so wọ́n pọ̀ mọ́ èjìká efodu náà ní òkúta ìrántí fún àwọn ọmọ Israẹli. Aaroni yóò sì máa ní orúkọ wọn níwájú Olúwa ní èjìká rẹ̀ méjèèjì fún ìrántí.

  6. Nígbà náà ni ìwọ yóò de òkúta oníyebíye mẹ́rin sára ẹsẹ̀ rẹ̀. Ní ẹsẹ̀ àkọ́kọ́ ni kí rúbì, topasi àti berili wà;

  7. ní ẹsẹ̀ kejì turikuose, emeradi, safire, àti diamọndi;

  8. ní ẹsẹ̀ kẹta, jasiniti, agate, àti ametisiti;

  9. ní ẹsẹ̀ kẹrin, topasi, àti óníkìsì àti jasperi. A ó sì tò wọ́n sí ojú wúrà ní dìde wọn.

  10. Òkúta méjìlá yóò wà, ọ̀kọ̀ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli olúkúlùkù èdìdì àmì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan bí ẹ̀yà Israẹli méjìlá.

  11. Ó sì to ipele òkúta oníyebíye mẹ́rin sí i. Ní ipele kìn-ín-ní ní rúbì wà, topasi àti berili;

  12. ní ipele kejì, turikuose, safire, emeradi àti diamọndi;

  13. ní ipele kẹta, jasiniti, agate àti ametisiti;

  14. ní ipele kẹrin, karisoliti, óníkìsì, àti jasperi. Ó sì tò wọ́n ní ojú ìdè wúrà ní títò wọn.

  15. Wọ́n jẹ́ òkúta méjìlá, ọ̀kan fún orúkọ àwọn ọmọ Israẹli kọ̀ọ̀kan, a fín ọ̀kọ̀ọ̀kan gẹ́gẹ́ bí èdìdì pẹ̀lú orúkọ ẹnìkọ̀ọ̀kan ẹ̀yà méjèèjìlá.

  16. Òun sì gba adé ọba wọn kúrò lórí rẹ̀, ìwúwo rẹ̀ sì jẹ́ tálẹ́ǹtì wúrà kan, ó sì ní òkúta oníyebíye lára rẹ̀; a sì fi dé Dafidi lórí. Òun sì kó ìkógun ìlú náà ni ọ̀pọ̀lọpọ̀.

  17. Nígbà tí ayaba Ṣeba gbọ́ òkìkí Solomoni àti ì bà ṣe pọ̀ rẹ̀ ní ti orúkọ Olúwa, ó sì wá láti dán an wò pẹ̀lú ìbéèrè líle.

  18. Ó sì wá sí Jerusalẹmu pẹ̀lú ẹgbẹ́ èrò ńlá ńlá, pẹ̀lú ìbákasẹ tí ó ru tùràrí, àti ọ̀pọ̀lọpọ̀ wúrà, àti òkúta iyebíye, ó sì wá sí ọ̀dọ̀ Solomoni, ó sì bá a sọ gbogbo èyí tí ń bẹ ní ọkàn rẹ̀.

  19. Ó sì fún ọba ní ọgọ́fà tálẹ́ǹtì wúrà, tùràrí olóòórùn dídùn lọ́pọ̀lọ́pọ̀, àti òkúta iyebíye. Kò sí irú ọ̀pọ̀lọpọ̀ tùràrí tí a mú wá tí ó dàbí irú èyí tí ayaba Ṣeba fi fún Solomoni ọba.

  20. (Pẹ̀lúpẹ̀lú àwọn ọ̀wọ́-ọkọ̀ Hiramu tí ó mú wúrà láti Ofiri wá, wọ́n mú igi algumu lọ́pọ̀lọ́pọ̀ àti òkúta oníyebíye láti Ofiri wá.

  21. Pẹ̀lú gbogbo ìrànlọ́wọ́ mi èmi ti pèsè fún ilé Ọlọ́run mi wúrà fún iṣẹ́ wúrà, fàdákà fún ti fàdákà, idẹ fún ti idẹ, irin fún ti irin àti igi fún ti igi àti òkúta oníyebíye fún títọ́ rẹ̀, òkúta lóríṣìíríṣìí, àwọ̀ àti oríṣìíríṣìí ẹ̀yà òkúta àti òkúta dáradára kan gbogbo wọ̀nyí ní iye púpọ̀.

  22. Ẹnikẹ́ni tí ó ní òkúta iyebíye fi wọn sí ilé ìṣúra ilé Olúwa ní abẹ́ ìtọ́jú Jehieli ará Gerṣoni.

  23. Ó ṣe ilé Olúwa náà lọ́ṣọ̀ọ́ pẹ̀lú òkúta iyebíye. Wúrà tí ó lò jẹ́ wúrà parifaimu.

  24. Àwọn ènìyàn Hiramu àti àwọn ọkùnrin Solomoni gbé wúrà wá láti Ofiri, wọ́n sì tún gbé igi algumu pẹ̀lú àti òkúta iyebíye wá.

  25. Bẹ́ẹ̀ ni Jehoṣafati àti àwọn ènìyàn rẹ̀ lọ láti kó ìkógun wọn, wọ́n sì rí lára wọn ọ̀pọ̀ iyebíye ọrọ̀ púpọ̀, ó sì ju èyí tí wọ́n lè kó lọ. Ọ̀pọ̀ ìkógun sì wà níbẹ̀, èyí tí ó gbà wọ́n ní ọjọ́ mẹ́ta láti gbà pọ̀.