Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Moon

44 ẹsẹ · 12 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ọlọ́run dá ìmọ́lẹ̀ ńlá ńlá méjì, ìmọ́lẹ̀ tí ó tóbi láti ṣe àkóso ọ̀sán àti ìmọ́lẹ̀ tí ó kéré láti ṣe àkóso òru. Ó sì dá àwọn ìràwọ̀ pẹ̀lú.

  2. O sì tún lá àlá mìíràn, ó sì tún sọ ọ́ fún àwọn arákùnrin rẹ̀. Ó wí pé, ẹ tẹ́tí sí mi, “Mo tún lá àlá mìíràn, wò ó, oòrùn, òṣùpá àti ìràwọ̀ mọ́kànlá ń foríbalẹ̀ fún mi.”

  3. Bí ẹ bá wòkè tí ẹ rí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀: àwọn ohun tí a ṣe lọ́jọ̀ sójú ọ̀run, ẹ má ṣe jẹ́ kí wọ́n tàn yín jẹ dé bi pé ẹ̀yin yóò foríbalẹ̀ fún wọn, àti láti máa sin ohun tí Olúwa Ọlọ́run yín dá fún gbogbo orílẹ̀-èdè lábẹ́ ọ̀run.

  4. èyí tí ó lòdì sí òfin mi, ó ń sin ọlọ́run mìíràn, ó ń foríbalẹ̀ fún wọn: àní sí oòrùn, òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run,

  5. àti fún èso iyebíye tí ọ̀run mú wá àti ti ohun iyebíye tí ń dàgbà ní oṣooṣù;

  6. Ní ọjọ́ tí Olúwa fi àwọn ọmọ Amori lé Israẹli lọ́wọ́, Joṣua sọ fún Olúwa níwájú àwọn ará Israẹli, “Ìwọ oòrùn, dúró jẹ́ẹ́ ní orí Gibeoni, Ìwọ òṣùpá, dúró jẹ́ẹ́ lórí àfonífojì Aijaloni.”

  7. Bẹ́ẹ̀ ni oòrùn náà sì dúró jẹ́ẹ́, òṣùpá náà sì dúró, títí tí ìlú náà fi gbẹ̀san lára àwọn ọ̀tá rẹ̀, gẹ́gẹ́ bí a ti kọ́ nínú ìwé Jaṣari. Oòrùn sì dúró ní agbede-méjì ọ̀run, kò sì wọ̀ ní ìwọ̀n odindi ọjọ́ kan.

  8. Ó sì kúrò pẹ̀lú àwọn àlùfáà abọ̀rìṣà tí a yàn láti ọwọ́ ọba Juda láti sun tùràrí ní ibi gíga ti ìlú Juda àti àwọn tí ó yí Jerusalẹmu ká. Àwọn tí ó ń sun tùràrí sí Baali, sí oòrùn àti òṣùpá, sí àwọn àmì ìràwọ̀ àti sí gbogbo ẹgbẹ́ ogun ọ̀run.

  9. Kíyèsi i, òṣùpá kò sì lè tàn ìmọ́lẹ̀, àní àwọn ìràwọ̀ kò mọ́lẹ̀ ní ojú rẹ̀,

  10. bí mo bá bojú wo oòrùn nígbà tí ń ràn, tàbí òṣùpá tí ń ràn nínú ìtànmọ́lẹ̀,

  11. bí a bá tàn ọkàn mi jẹ láti fi ẹnu mi kò ọwọ́ mi,

  12. Nígbà tí mo ro ọ̀run rẹ, iṣẹ́ ìka rẹ, òṣùpá àti ìràwọ̀, tí ìwọ tí gbé kalẹ̀,

  13. Òṣùpá jẹ́ àmì fún àkókò oòrùn sì mọ ìgbà tí yóò wọ̀.

  14. Oòrùn kì yóò pa ọ́ ní ìgbà ọ̀sán tàbí òṣùpá ní ìgbà òru.

  15. Fún ẹni tí ó dá àwọn ìmọ́lẹ̀ ńlá; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  16. Òòrùn láti jẹ ọba ọ̀sán; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  17. Òṣùpá àti ìràwọ̀ láti jẹ ọba òru; nítorí tí àánú rẹ̀ dúró láéláé.

  18. kí oòrùn àti ìmọ́lẹ̀ àti òṣùpá àti àwọn ìràwọ̀ tó ṣókùnkùn, àti kí àwọsánmọ̀ tó padà lẹ́yìn òjò;

  19. Ta ni èyí tí ó tàn jáde bí i ìràwọ̀ òwúrọ̀, tí ó dára bí òṣùpá, tí ó mọ́lẹ̀ bí oòrùn, tí ó ní ẹ̀rù bí i jagunjagun pẹ̀lú ọ̀págun?

  20. Àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run àti ìkójọpọ̀ wọn kò sì ní fi ìmọ́lẹ̀ wọn hàn. Àṣẹ̀ṣẹ̀yọ oòrùn yóò di òkùnkùn àti òṣùpá kò ní fi ìmọ́lẹ̀ rẹ̀ hàn.

  21. A ó rẹ òṣùpá sílẹ̀, ojú yóò sì ti oòrùn; nítorí Olúwa àwọn ọmọ-ogun yóò jẹ ọba ní orí òkè Sioni àti ní Jerusalẹmu, àti níwájú àwọn àgbàgbà rẹ ní ògo.

  22. Òṣùpá yóò sì tàn bí oòrùn, àti ìtànṣán oòrùn yóò mọ́lẹ̀ ní ìlọ́po méje, gẹ́gẹ́ bí ìmọ́lẹ̀ odidi ọjọ́ méje, nígbà tí Olúwa yóò di ojú ọgbẹ́ àwọn ènìyàn rẹ̀ tí yóò sì wo ọgbẹ́ tí ó ti dá sí wọn lára sàn.

  23. Òòrùn kì yóò sì jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ní ọ̀sán mọ́, tàbí kí ìtànṣán òṣùpá tún ràn sí ọ mọ́, nítorí Olúwa ni yóò jẹ́ ìmọ́lẹ̀ rẹ ayérayé, àti Ọlọ́run rẹ yóò jẹ́ ògo rẹ.

  24. Àwọn ọmọ ṣa igi jọ, àwọn baba fi iná sí i, àwọn ìyá sì po ìyẹ̀fun láti ṣe àkàrà fún ayaba ọ̀run, wọ́n tú ẹbọ ọrẹ mímu sí àwọn ọlọ́run àjèjì láti ru bínú mi sókè.

  25. A ó yọ wọ́n síta fún oòrùn àti òṣùpá àti gbogbo àwọn ìràwọ̀ ojú ọ̀run tí wọ́n ti fẹ́ràn tí wọ́n sì ti sìn, àti àwọn tí wọ́n ti tọ̀ lẹ́yìn tí wọ́n ti wá tí wọ́n sì ti foríbalẹ̀ fún. Kì yóò ṣà wọ́n jọ tàbí sìn wọ́n, wọn yóò dàbí ìdọ̀tí tó wà lórí ilẹ̀.