Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Missions

60 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà ọba Asiria pàṣẹ yìí wí pé, “Mú ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó mú láti Samaria lọ padà gbé níbẹ̀ kí ó sì kọ́ àwọn ènìyàn ní, ohun tí ọlọ́run ilẹ̀ náà béèrè.”

  2. Bẹ́ẹ̀ ni ọ̀kan lára àwọn àlùfáà tí ó ti kúrò ní Samaria wá gbé ní Beteli ó sì kọ́ wọn bí a ti ń sin Olúwa.

  3. Kọrin sí Olúwa gbogbo ayé; ẹ máa fi ìgbàlà rẹ̀ hàn láti ọjọ́ dé ọjọ́.

  4. Kéde ògo à rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ohun ìyàlẹ́nu tí ó ṣe láàrín gbogbo ènìyàn.

  5. Títí láéláé, èmi yóò máa yìn ọ́ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, ìwọ Olúwa; èmi yóò sì máa kọ orin ìyìn sí orúkọ rẹ.

  6. Ẹ kọrin tuntun sí Olúwa, ẹ kọrin sí Olúwa gbogbo ayé.

  7. Ẹ kọrin sí Olúwa, yin orúkọ rẹ̀ ẹ sọ ti ìgbàlà rẹ̀ ní ọjọ́ dé ọjọ́.

  8. Ẹ sọ ti ògo rẹ̀ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ láàrín gbogbo ènìyàn.

  9. Nítorí títóbi ní Olúwa ẹni tí ìyìn tọ́ sí; òun ní o yẹ kí a bẹ̀rù ju gbogbo òrìṣà lọ.

  10. Nítorí asán ni gbogbo àwọn òrìṣà orílẹ̀-èdè ṣùgbọ́n Olúwa dá àwọn ọ̀run.

  11. Ọlá àti ọláńlá wà ní iwájú rẹ̀ agbára àti ògo wà ní ibi mímọ́ rẹ̀.

  12. Ẹ fi fún Olúwa, ẹ̀yin ìbátan ènìyàn, ẹ fi agbára àti ògo fún Olúwa.

  13. Ẹ fi ògo tí ó tọ́ sí Olúwa fún un; ẹ mú ọrẹ wá, kí ẹ sì wá sí àgbàlá rẹ̀.

  14. Ẹ máa sin Olúwa nínú ẹwà ìwà mímọ́ rẹ̀; ẹ wárìrì níwájú rẹ̀ gbogbo ayé.

  15. Sọ láàrín àwọn orílẹ̀-èdè, “Olúwa jẹ ọba.” A fi ìdí ayé múlẹ̀, tí kò sì lè yí; ẹni tí yóò fi òtítọ́ ṣe ìdájọ́ ènìyàn.

  16. Jẹ́ kí àwọn ọ̀run kí ó yọ̀, kí ayé sì pariwo jẹ́ kí pápá òkun kí ó hó pẹ̀lú ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀.

  17. Jẹ́ kí oko kún fún ayọ̀, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀; nígbà náà ni gbogbo igi igbó yóò máa yọ̀.

  18. Wọn yóò kọrin níwájú Olúwa, nítorí tí ó ń bọ̀ wá, ó ń bọ̀ wá ṣe ìdájọ́ ayé. Yóò fi òdodo ṣe ìdájọ́ ayé àti ti àwọn ènìyàn ni yóò fi òtítọ́ rẹ̀ ṣe.

  19. Èmi yóò sọ fún àríwá pé, ‘Fi wọ́n sílẹ̀!’ Àti fún gúúsù, ‘Má ṣe dá wọn dúró.’ Mú àwọn ọmọkùnrin mi láti ọ̀nà jíjìn wá àti àwọn ọ̀dọ́mọbìnrin mi láti ìpẹ̀kun ilẹ̀ ayé—

  20. ẹnikẹ́ni tí a ń pe orúkọ mi mọ́, tí mo dá fún ògo mi, tí mo mọ̀ àti tí mo ṣe.”

  21. Ọ̀rọ̀ Olúwa sì tọ Jona wá nígbà kejì wí pé:

  22. “Dìde lọ sí Ninefe, ìlú ńlá a nì, kí o sì kéde sí i, ìkéde tí mo sọ fún ọ.”

  23. Jona sì dìde ó lọ sí Ninefe gẹ́gẹ́ bí ọ̀rọ̀ Olúwa. Ninefe jẹ́ ìlú títóbi gidigidi, ó tó ìrìn ọjọ́ mẹ́ta.

  24. Jona sì bẹ̀rẹ̀ sí wọ ìlú náà lọ ní ìrìn ọjọ́ kan, ó sì ń kéde, ó sì wí pé, “Níwọ́n ogójì ọjọ́ sí i, a ó bi Ninefe wó.”

  25. Àwọn ènìyàn Ninefe sì gba Ọlọ́run gbọ́. Wọ́n sì kéde àwẹ̀, gbogbo wọ́n sì wọ aṣọ ọ̀fọ̀, bẹ̀rẹ̀ láti orí ọmọdé títí dé orí àgbà wọn.