Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Missions

60 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ǹjẹ́ bí Ẹ̀mí Mímọ́ ti rán àwọn méjèèjì lọ, wọ́n sọ̀kalẹ̀ lọ sí Seleusia; láti ibẹ̀ wọ́n sì wọ ọkọ̀ ojú omi lọ sí Saipurọsi.

  2. Bẹ́ẹ̀ ni Olúwa ṣa ti pàṣẹ fún wa pé: “ ‘Mo ti gbé ọ kalẹ̀ láti tan ìmọ́lẹ̀ fún àwọn aláìkọlà, kí ìwọ lè mú ìgbàlà wá títí dé òpin ayé.’ ”

  3. Gbogbo wa sì ṣubú lulẹ̀, mo gbọ́ ohùn tí ń fọ sì mi ni èdè Heberu pé, ‘Saulu, Saulu! Èéṣe tí ìwọ fi ń ṣe inúnibíni sí mi? Ohun ìrora ní fún ọ láti tàpá sí ẹ̀gún!’

  4. “Èmi sì wí pé, ‘Ìwọ ta ni, Olúwa?’ “Olúwa sì wí pé, ‘Èmi ni Jesu tí ìwọ ń ṣe inúnibíni sí.

  5. Ṣùgbọ́n dìde, kí o sí fi ẹsẹ̀ rẹ tẹlẹ̀: nítorí èyí ni mo ṣe farahàn ọ́ láti yàn ọ́ ní ìránṣẹ́ àti ẹlẹ́rìí, fún ohun wọ̀nyí tí ìwọ tí rí nípa mi, àti àwọn ohun tí èmi yóò fi ara hàn fún ọ.

  6. Èmi yóò gbà ọ lọ́wọ́ àwọn ènìyàn rẹ àti lọ́wọ́ àwọn aláìgbàgbọ́. Èmi rán ọ sí wọn nísinsin yìí

  7. láti là wọ́n lójú, kí wọn lè yípadà kúrò nínú òkùnkùn sí ìmọ́lẹ̀, àti kúrò lọ́wọ́ agbára Satani sí Ọlọ́run, kí wọn lè gba ìdáríjì ẹ̀ṣẹ̀, àti ogún pẹ̀lú àwọn tí a sọ di mímọ́ nípa ìgbàgbọ́ nínú mi.’

  8. Nítorí pé ìlẹ̀kùn ńlá láti ṣe iṣẹ́ gidi ṣí sílẹ̀ fún mí, ọ̀pọ̀lọpọ̀ sì ni àwọn ọ̀tá tí ń bẹ.

  9. Mo sì rí angẹli mìíràn ń fò ní àárín méjì ọ̀run, pẹ̀lú ìyìnrere àìnípẹ̀kun láti wàásù fún àwọn tí ń gbé orí ilẹ̀ ayé, àti fún gbogbo orílẹ̀, àti ẹ̀yà, àti èdè, àti ènìyàn.

  10. Ó ń wí ni ohùn rara pé, “Ẹ bẹ̀rù Ọlọ́run, kí ẹ sì fi ògo fún un, nítorí tí wákàtí ìdájọ́ rẹ̀ dé: ẹ sì foríbalẹ̀ fún ẹni tí o dá ọ̀run, àti ayé, àti Òkun, àti àwọn orísun omi!”