Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Missionary Work By Ministers: Christ engaged in
Àwọn ẹsẹ nípa Christ engaged in
Láti ìgbà náà lọ ni Jesu ti bẹ̀rẹ̀ sí wàásù: “Ẹ ronúpìwàdà, nítorí tí ìjọba ọ̀run kù sí dẹ̀dẹ̀.”
Jesu sì rin káàkiri gbogbo Galili, ó ń kọ́ni ní Sinagọgu, ó ń wàásù ìyìnrere ti ìjọba ọ̀run, ó sì ń ṣe ìwòsàn ààrùn gbogbo àti àìsàn láàrín gbogbo ènìyàn.
Lẹ́yìn ìgbà tí Jesu sì ti parí ọ̀rọ̀ tí ó ń sọ fún àwọn ọmọ-ẹ̀yìn rẹ̀ méjìlá, ó ti ibẹ̀ rékọjá láti máa kọ́ni àti láti máa wàásù ní àwọn ìlú Galili gbogbo.
Jesu sì dáhùn wí pé, “Ẹ jẹ́ kí a lọ sí àwọn ìlú mìíràn, kí ń lè wàásù níbẹ̀ pẹ̀lú. Nítorí èyí ni èmi sá à ṣe wá.”
Nítorí náà, ó ń kiri gbogbo agbègbè Galili, ó ń wàásù nínú Sinagọgu. Ó sì ń lé àwọn ẹ̀mí àìmọ́ jáde.
Ó sì ṣe lẹ́yìn náà, tí ó ń lá gbogbo ìlú àti ìletò kọjá lọ, ó ń wàásù, ó ń ròyìn ayọ̀ ìjọba Ọlọ́run. Àwọn méjìlá sì ń bẹ lọ́dọ̀ rẹ̀,