Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Missionary Work By Ministers: Warranted by predictions concerning the heathen, &c

4 ẹsẹ · 32 abala

Àwọn ẹsẹ nípa Warranted by predictions concerning the heathen, &c

  1. Kọ orin tuntun sí Olúwa ìyìn rẹ̀ láti òpin ilẹ̀ ayé wá, ẹ̀yin tí ó sọ̀kalẹ̀ lọ sínú Òkun, àti ohun gbogbo tí ń bẹ nínú rẹ̀, ẹ̀yin erékùṣù, àti gbogbo àwọn tí ń gbé inú wọn.

  2. Jẹ́ kí aginjù àti àwọn ìlú rẹ̀ kí ó gbé ohùn wọn sókè; jẹ́ kí ibùdó ti àwọn ìlú Kedari ń gbé máa yọ̀. Jẹ́ kí àwọn ènìyàn Sela kọrin fún ayọ̀; jẹ́ kí wọn pariwo láti orí òkè.

  3. Jẹ́ kí wọn fi ògo fún Olúwa àti kí wọn sì kéde ìyìn rẹ̀ ní erékùṣù.

  4. “Èmi yóò sì gbé àmì kan kalẹ̀ láàrín wọn, èmi yóò sì rán díẹ̀ nínú àwọn tí ó sálà lọ sí àwọn orílẹ̀-èdè Tarṣiṣi, sí àwọn ará Libia àti Ludi, sí Tubali àti ará Giriki, àti sí àwọn erékùṣù tí ó jìnnà réré tí kò tí ìgbọ́ nípa òkìkí mi tàbí kí ó rí ògo mi. Wọn yóò kéde ògo mi láàrín àwọn orílẹ̀-èdè.