Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Milcah

30 ẹsẹ · 2 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nígbà náà, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ṣe gẹ́gẹ́ bí Olúwa ti pa á láṣẹ fún Mose.

  2. Nítorí pé a gbé Mahila, Tirsa, Hogla, Milka, àti Noa, àwọn ọmọbìnrin Selofehadi ní ìyàwó fún àwọn ọmọ arákùnrin baba wọn.

  3. Wọ́n fẹ́ ọkọ nínú ìdílé ìran Manase, ọmọ Josẹfu ogún wọn kù nínú ìdílé àti ẹ̀yà baba wọn.

  4. Nísinsin yìí Selofehadi ọmọ Heferi, ọmọ Gileadi, ọmọ Makiri, ọmọ Manase, kò ní ọmọkùnrin, bí kò ṣe àwọn ọmọbìnrin, tí orúkọ wọn jẹ́: Mahila, Noa, Hogla, Milka àti Tirsa.

  5. Wọ́n sì lọ bá Eleasari àlùfáà, Joṣua ọmọ Nuni, àti àwọn olórí wí pé, “Olúwa pàṣẹ fún Mose láti fún wa ní ìní ní àárín àwọn arákùnrin wa.” Bẹ́ẹ̀ ni Joṣua fún wọn ní ìní pẹ̀lú àwọn arákùnrin baba wọn, gẹ́gẹ́ bí àṣẹ Olúwa.