Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Mariner

36 ẹsẹ · 3 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Àwọn tí ń sọ̀kalẹ̀ lọ sí Òkun nínú ọkọ̀ ojú omi, wọ́n jẹ́ oníṣòwò nínú omi ńlá.

  2. Wọ́n rí iṣẹ́ Olúwa, àti iṣẹ́ ìyanu rẹ̀ nínú ibú.

  3. Nítorí tí ó pàṣẹ, ó sì mú ìjì fẹ́ tí ó gbé ríru rẹ̀ sókè.

  4. Wọ́n gòkè lọ sí ọ̀run wọ́n sì tún sọ̀kalẹ̀ lọ sí ibú: nítorí ìpọ́njú, ọkàn wọn di omi.

  5. Wọ́n ń ta gbọ̀nọ́ngbọ̀nọ́n bí ọ̀mùtí ènìyàn: ọgbọ́n wọn sì dé òpin.

  6. Nígbà náà wọ́n ń kígbe sókè sí Olúwa nínú ìdààmú wọn, ó sì mú wọn jáde nínú ìṣòro wọn.

  7. Ó sọ ìjì di ìdákẹ́rọ́rọ́ bẹ́ẹ̀ ni ríru omi rẹ̀ dúró jẹ́ẹ́.

  8. Inú wọn dùn nígbà tí ara wọn balẹ̀, ó mú wọn lọ sí ibi tí ọkàn wọn lọ.

  9. Nígbà tí wọ́n sì gbé e sókè, wọn sa agbára láti dí ọkọ̀-òkun náà nísàlẹ̀, nítorí tí wọ́n ń bẹ̀rù kí á máa ba à gbé wọn sórí iyanrìn dídẹ̀, wọn fi ìgbokùn sílẹ̀, bẹ́ẹ̀ ni a sì ń gbá wa kiri.

  10. Bí a sì ti ń ṣe làálàá gidigidi nínú ìjì náà, ni ọjọ́ kejì wọn kó ẹrù-ọkọ̀ dà sí omi láti mú ọkọ̀ fẹ́rẹ̀.

  11. Ní ọjọ́ kẹta, wọ́n fi ọwọ́ ara wọn kó ohun èlò ọkọ̀ dànù.

  12. Nígbà tí oòrùn àti ìràwọ̀ kò si hàn lọ́jọ́ púpọ̀, tí ìjì náà kò sì mọ níwọ̀n fún wa, àbá àti là kò sí fún wa mọ́.

  13. Nígbà tí wọ́n wà ní àìjẹun lọ́jọ́ púpọ̀, nígbà náà Paulu dìde láàrín wọn, o wí pé, “Alàgbà, ẹ̀yin bá ti gbọ́ tèmi kí a má ṣe ṣíkọ̀ kúrò ní Krete, ewu àti òfò yìí kì ìbá ti bá wa.

  14. Ǹjẹ́ nísinsin yìí mó gbà yín níyànjú, kí ẹ tújúká; nítorí kí yóò sí òfò ẹ̀mí nínú yín, bí kò ṣe ti ọkọ̀.

  15. Nítorí angẹli Ọlọ́run, ẹni tí èmi jẹ́ tirẹ̀, àti ẹni ti èmi ń sìn, ó dúró tì mi ni òru àná.

  16. Ó wí pé, ‘Má bẹ̀rù, Paulu; ìwọ kò lè ṣàìmá dúró níwájú Kesari. Sì wò ó, Ọlọ́run ti fi gbogbo àwọn ti ó bá ọ wọ ọkọ̀ pọ̀ fún ọ.’

  17. Ǹjẹ́ nítorí náà, alàgbà, ẹ dárayá: nítorí mo gba Ọlọ́run gbọ́ pé, yóò rí bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ bí a ti sọ fún mi.

  18. Ṣùgbọ́n a ó gbá wa jù sí erékùṣù kan.”

  19. Ṣùgbọ́n nígbà tí ó di òru ọjọ́ kẹrìnlá, bí a ti ń gbé wa kọjá lọ láàrín Òkun Adria, láàrín ọ̀gànjọ́ àwọn atukọ̀ funra pé, àwọn súnmọ́ etí ilẹ̀ kan.

  20. Nígbà tí wọ́n sì wọn Òkun, wọ́n rí i ó jì ní ogún ìgbọ̀nwọ́, nígbà tì í wọ́n sún síwájú díẹ̀, wọ́n sì tún wọn Òkun, wọn rí i pé ó jì ni ìgbọ̀nwọ́ mẹ́ẹ̀ẹ́dógún.

  21. Nígbà tí wọ́n bẹ̀rù kí wọn má ṣe rọ́ lu orí òkúta, wọ́n sọ ìdákọ̀ró mẹ́rin sílẹ̀ ni ìdí ọkọ̀, wọ́n ń retí ojúmọ́.

  22. Ṣùgbọ́n nígbà tí àwọn atukọ̀ ń wá ọ̀nà láti sá kúrò nínú ọkọ̀, tí wọ́n sì ti sọ àwọn ọkọ̀ kéékèèké kalẹ̀ sí ojú Òkun, bí ẹni pé wọn ń fẹ́ sọ ìdákọ̀ró sílẹ̀ níwájú ọkọ̀.

  23. Paulu wí fún balógun ọ̀rún àti fún àwọn ọmọ-ogun pé, “Bí kò ṣe pé àwọn wọ̀nyí bá dúró nínú ọkọ̀ ẹ̀yin kí yóò lè là!”

  24. Nígbà náà ni àwọn ọmọ-ogun gé okùn àwọn ọkọ̀ kéékèèké, wọ́n jù ú sílẹ̀ kí ó ṣubú sọ́hùn-ún.

  25. Nígbà tí ilẹ̀ ń mọ́ bọ̀, Paulu bẹ gbogbo wọn kí wọn jẹun díẹ̀, ó wí pé, “Òní ni ó di ìjẹrìnlá tí ẹ̀yin ti ń retí, ti ẹ kò dẹ́kun gbígbààwẹ̀, tí ẹ kò sì jẹun.