Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Kindness: General references

25 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ nípa General references

  1. Bí o bá rí màlúù tàbí àgùntàn arákùnrin rẹ tí ó ń sọnù, má ṣe ṣé àìkíyèsí i rẹ̀ ṣùgbọ́n rí i dájú pé o mú padà wá fún un.

  2. Bí ọkùnrin náà kì í bá gbé ní tòsí rẹ tàbí bí o kò bá mọ ẹni náà, mú un lọ ilé pẹ̀lú rẹ kí o sì fi pamọ́ títí yóò fi wá a wá. Nígbà náà ni kí o fi fún un.

  3. Ṣe bákan náà tí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ arákùnrin rẹ tàbí aṣọ ìlekè tàbí ohunkóhun rẹ̀ tí ó sọnù. Má ṣe ṣe àìkíyèsí i rẹ̀.

  4. Bí o bá rí kẹ́tẹ́kẹ́tẹ́ tàbí màlúù arákùnrin rẹ tí o dùbúlẹ̀ sójú ọ̀nà, má ṣe ṣàìfiyèsí i rẹ̀, ràn án lọ́wọ́ láti dìde dúró lórí ẹsẹ̀ rẹ̀.

  5. “Báyìí ni Olúwa àwọn ọmọ-ogun wí pé, ‘Ṣe ìdájọ́ òtítọ́, kí ẹ sì ṣe àánú àti ìyọ́nú olúkúlùkù sí arákùnrin rẹ̀.

  6. Má sì ṣe ni opó lára tàbí aláìní baba, àlejò, tàbí tálákà; kí ẹnikẹ́ni nínú yín má ṣe gbèrò ibi ní ọkàn sí arákùnrin rẹ̀.’

  7. “Nígbà náà ni ọba yóò wí fún àwọn tí ó wà lọ́wọ́ ọ̀tún pé, ‘Ẹ wá, ẹ̀yin tí Baba mi ti bùkún fún, ẹ jogún ìjọba tí a ti pèsè fún yín láti ìpilẹ̀ṣẹ̀ ayé.

  8. Nítorí ebi pa mi, ẹ̀yin sì fún mi ní oúnjẹ, òǹgbẹ gbẹ mí, ẹ̀yin sì fún mi ní omi. Mo jẹ́ àlejò, ẹ̀yin sì pè mí sínú ilé yín.

  9. Mo wà ní ìhòhò, ẹ̀yin sì daṣọ bò mí. Nígbà tí mo ṣe àìsàn ẹ ṣe ìtójú mi, àti ìgbà tí mo wà ní ọgbà ẹ̀wọ̀n ẹ̀yin bẹ̀ mí wò.’

  10. Bí ẹ̀yin bá fi fún ẹni tí ẹ̀yin ń retí láti rí gbà padà, ọpẹ́ kín ni ẹ̀yin ní? Àwọn ẹlẹ́ṣẹ̀ pẹ̀lú ń yá ẹlẹ́ṣẹ̀, kí wọn lè gba ìwọ̀n bẹ́ẹ̀ padà.

  11. Ṣùgbọ́n kí ẹ̀yin fẹ́ àwọn ọ̀tá yín kí ẹ sì ṣoore, kí ẹ̀yin sì yá ẹlòmíràn, kí ẹ̀yin má ṣe retí láti rí nǹkan gbà padà; èrè yín yóò sì pọ̀, àwọn ọmọ Ọ̀gá-ògo ni a ó sì máa pè yín: nítorí tí ó ṣe rere fún aláìmoore àti fún ẹni búburú.

  12. Àwa tí a jẹ́ alágbára nínú ìgbàgbọ́ yẹ kí ó máa ru ẹrù àìlera àwọn aláìlera, kí a má sì ṣe ohun tí ó wu ara wa.

  13. Olúkúlùkù wa gbọdọ̀ máa ṣe ohun tí ó wu ọmọnìkejì rẹ̀ sí rere, láti gbé e ró.

  14. Ìfẹ́ a máa mú sùúrù, ìfẹ́ a máa ṣeun, ìfẹ́ kì í ṣe ìlara, ìfẹ́ kì í fẹ̀, ìfẹ́ kì í sọ̀rọ̀ ìgbéraga.

  15. Ìfẹ́ kì í hùwà àìtọ́, kì í wá ohun ara rẹ̀ nìkan. Ìfẹ́ kì í bínú fùfù, ìfẹ́ kì í fi búburú ọmọ ẹnìkejì sínú.

  16. Inú ìfẹ́ kì í dùn sí àìṣòótọ́. Ṣùgbọ́n inú rẹ̀ a máa dùn nígbà gbogbo.

  17. A máa faradà ohun gbogbo sí òtítọ́, a máa gba ohun gbogbo gbọ́, a máa retí ohun gbogbo, a máa fàyàrán ohun gbogbo.

  18. Ará, bí a tilẹ̀ mú ènìyàn nínú ẹ̀ṣẹ̀ kan, kí ẹ̀yin tí í ṣe ti Ẹ̀mí mú irú ẹni bẹ́ẹ̀ bọ̀ sípò nínú ẹ̀mí ìwà tútù; kí ìwọ tìkára rẹ̀ máa kíyèsára, kí a má ba à dán ìwọ náà wò pẹ̀lú.

  19. Ẹ máa ru ẹrù ọmọnìkejì yín, kí ẹ sì fi bẹ́ẹ̀ mú òfin Kristi ṣẹ.

  20. Kọ orúkọ ẹni tí kò bá dín ni ọgọ́ta ọdún sílẹ̀ bí opó, lẹ́yìn ti ó ti jẹ́ aya ọkọ kan.

  21. Ẹni ti a jẹ́rìí rẹ̀ fún iṣẹ́ rere; bí ẹni ti ó ti tọ́ ọmọ dàgbà, ti ó ń ṣe ìtọ́jú àlejò, tí ó sì ń wẹ ẹsẹ̀ àwọn ènìyàn mímọ́, tí ó ti ran àwọn olùpọ́njú lọ́wọ́, tí ó sì ń lépa iṣẹ́ rere gbogbo.

  22. Lákòótan, kí gbogbo yín jẹ́ onínú kan, ẹ máa bá ara yín kẹ́dùn, ẹ ní ìfẹ́ ará, ẹ máa ṣe ìyọ́nú, ẹ ni ẹ̀mí ìrẹ̀lẹ̀.

  23. Ẹ má ṣe fi búburú san búburú, tàbí fi èébú san èébú: ṣùgbọ́n kàkà bẹ́ẹ̀, ẹ máa súre; nítorí èyí ni a pè yín sí, kí ẹ̀yin lè jogún ìbùkún.

  24. Ṣùgbọ́n ẹni tí ó bá ni ohun ìní ayé, tí ó sì ri arákùnrin rẹ̀ tí ó ṣe aláìní, tí ó sì sé ìlẹ̀kùn ìyọ́nú rẹ̀ mọ́ ọn, báwo ni ìfẹ́ Ọlọ́run ṣe ń gbé inú rẹ̀?

  25. Ẹ̀yin ọmọ mi, ẹ má ṣe jẹ́ kí a fi ọ̀rọ̀ tàbí ahọ́n fẹ́ràn, bí kò ṣe ni ìṣe àti ní òtítọ́.