Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Ish-Bosheth

21 ẹsẹ · 6 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

  1. Lákòókò yìí, Abneri ọmọ Neri olórí ogun Saulu ti mú Iṣboṣeti ọmọ Saulu, ó sì mú un kọjá sí Mahanaimu.

  2. Ó sì fi jẹ ọba lórí Gileadi Aṣuri àti Jesreeli àti lórí Efraimu àti lórí Benjamini àti lórí gbogbo Israẹli.

  3. Iṣboṣeti ọmọ Saulu sì jẹ́ ọmọ ogójì ọdún nígbà tí ó jẹ ọba lórí Israẹli, ó sì jẹ ọba fún ọdún méjì. Ilé Juda sì ń tọ Dafidi lẹ́yìn.

  4. Ó sì ṣe, nígbà tí ogun wà láàrín ìdílé Saulu àti ìdílé Dafidi, Abneri sì dì alágbára ní ìdílé Saulu.

  5. Saulu ti ní àlè kan, orúkọ rẹ̀ sì ń jẹ́ Rispa, ọmọbìnrin Aiah: Iṣboṣeti sì bi Abneri léèrè pé, “Èéṣe tí ìwọ fi wọlé tọ àlè baba mi lọ.”

  6. Abneri sì bínú gidigidi nítorí ọ̀rọ̀ wọ̀nyí ti Iṣboṣeti sọ fún un, ó sì wí pé, “Èmi jẹ́ bí orí ajá ti Juda bí? Di òní yìí ni mo ṣàánú fún ìdílé Saulu baba rẹ, àti fún àwọn arákùnrin rẹ̀, àti fún àwọn ọ̀rẹ́ rẹ̀, tí èmi kò sì fi ọ́ lé Dafidi lọ́wọ́, ìwọ sì kà ẹ̀ṣẹ̀ sí mí lọ́rùn nítorí obìnrin yìí lónìí?

  7. Bẹ́ẹ̀ ni kí Ọlọ́run ó ṣe Abneri, àti jù bẹ́ẹ̀ lọ pẹ̀lú, bí Olúwa ti búra fún Dafidi, bí èmi kò ní ṣe bẹ́ẹ̀ fún un.

  8. Láti mú ìjọba náà kúrò ní ìdílé Saulu, àti láti gbé ìtẹ́ Dafidi kalẹ̀ lórí Israẹli, àti lórí Juda, láti Dani títí ó fi dé Beerṣeba.”

  9. Òun kò sì lè dá Abneri lóhùn kan nítorí tí ó bẹ̀rù rẹ̀.

  10. Abneri sì rán àwọn oníṣẹ́ sí Dafidi nítorí rẹ̀ wí pé, “Ti ta ni ilẹ̀ náà ń ṣe? Bá mi ṣe àdéhùn, èmi yóò si kó gbogbo Israẹli tọ̀ ọ́ wá.”

  11. Dafidi sì rán àwọn ìránṣẹ́ sí Iṣboṣeti ọmọ Saulu pé, “Fi Mikali obìnrin mi lé mi lọ́wọ́, ẹni tí èmi ti fi ọgọ́rùn-ún awọ iwájú orí àwọn Filistini fẹ́.”

  12. Iṣboṣeti sì ránṣẹ́, ó sì gbà á lọ́wọ́ ọkùnrin tí a ń pè ní Paltieli ọmọ Laiṣi.

  13. Ọkọ rẹ̀ sì ń bà a lọ, ó ń rìn, ó sì ń sọkún lẹ́yìn rẹ̀ títí ó fi dé Bahurimu Abneri sì wí fún un pé, “Padà sẹ́yìn!” Òun sì padà.

  14. Àwọn ọmọ Rimoni, ará Beeroti, Rekabu àti Baanah sì lọ wọ́n sì wá síh ilé Iṣboṣeti ní ọ̀sán gangan, òun sì sinmi lórí ibùsùn kan ní ọjọ́-kanrí.

  15. Sì wò ó, bí olùṣọ́ ẹnu-ọ̀nà ilé náà ti ń gbọn àwọn pàǹtí, ó tòògbé ó sì sùn lọ, wọ́n sì wá sí àárín ilé náà, wọ́n sì ṣe bí ẹni pé wọ́n ń fẹ́ mú alikama; wọ́n sì gún un lábẹ́ inú. Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀ sì sálọ.

  16. Nígbà tí wọ́n wọ ilé náà lọ, òun sì dùbúlẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀ nínú iyàrá rẹ̀, wọ́n sì pa á, wọ́n sì bẹ́ ẹ lórí, wọ́n gbé orí sálọ, wọ́n sì fi gbogbo òru rìn ni pẹ̀tẹ́lẹ̀ náà.

  17. Wọ́n sì gbé orí Iṣboṣeti tọ Dafidi wá ní Hebroni, wọ́n sì wí fún ọba pé, “Wò ó, orí Iṣboṣeti ọmọ Saulu ọ̀tá rẹ, tí ó ti ń wá ẹ̀mí rẹ kiri, Olúwa ti gbẹ̀san fún ọba olúwa mi lónìí lára Saulu àti lára irú-ọmọ rẹ̀.”

  18. Dafidi sì dá Rekabu àti Baanah arákùnrin rẹ̀, àwọn ọmọ Rimoni ará Beeroti lóhùn, ó sì wí fún wọn pé, “Bí Olúwa ti ń bẹ, ẹni tí ó gba ẹ̀mí mi lọ́wọ́ gbogbo ìpọ́njú.

  19. Nígbà tí ẹnìkan rò fún mi pé, ‘Wò ó, Saulu ti kú,’ lójú ara rẹ̀ òun sì jásí ẹni tí ó mú ìyìnrere wá, èmi sì mú un, mo sì pa á ní Siklagi, ẹni tí ó ṣe bí òun ó rí nǹkan gbà nítorí ìròyìn rere rẹ̀.

  20. Mélòó mélòó ni, nígbà tí àwọn ìkà ènìyàn pa olódodo ènìyàn kan ni ilé rẹ̀ lórí ibùsùn rẹ̀—ǹjẹ́ èmi ha sì lè ṣe aláìbéèrè ẹ̀jẹ̀ rẹ̀ lọ́wọ́ yín bí? Kí èmi sì mú yín kúrò láààyè.”

  21. Dafidi sì fi àṣẹ fún àwọn ọ̀dọ́mọkùnrin rẹ̀, wọ́n sì pa wọ́n, wọ́n sì gé ọwọ́ àti ẹsẹ̀ wọn, a sì fi wọ́n há lórí igi ní Hebroni. Ṣùgbọ́n wọ́n mú orí Iṣboṣeti, wọ́n sì sin ín ní ibojì Abneri ní Hebroni.