Fò sí àkóónú

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Impenitence

170 ẹsẹ · 1 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Ìrètí Israẹli; ìgbàlà rẹ lásìkò ìpọ́njú, èéṣe tí ìwọ dàbí àlejò ní ilẹ̀ náà bí arìnrìn-àjò tí ó dúró fún bí òru ọjọ́ kan péré?

  2. Èéṣe tí ìwọ dàbí ẹni tí a dààmú, bí jagunjagun tí kò le ran ni lọ́wọ́? Ìwọ wà láàrín wa, Olúwa, orúkọ rẹ ni a sì ń pè mọ́ wa; má ṣe fi wá sílẹ̀.

  3. Báyìí ni Olúwa sọ nípa àwọn ènìyàn wọ̀nyí: “Wọ́n fẹ́ràn láti máa rìn kiri; wọn kò kó ọkàn wọn ní ìjánu. Nítorí náà Olúwa kò gbà wọ́n; yóò wá rántí ìwà búburú wọn báyìí, yóò sì fi ìyà ẹ̀ṣẹ̀ wọn jẹ wọ́n.”

  4. Nígbà náà ni Olúwa sọ fún mi pé, “Má ṣe gbàdúrà fún àlàáfíà àwọn ènìyàn wọ̀nyí.

  5. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n gbààwẹ̀, èmi kò ní tẹ́tí sí igbe wọn. Bí ó tilẹ̀ jẹ́ pé wọ́n rú ẹbọ sísun àti ẹbọ ìyẹ̀fun, èmi ò nígbà wọ́n. Dípò bẹ́ẹ̀, èmi ó fi idà, ìyàn àti àjàkálẹ̀-ààrùn pa wọ́n run.”

  6. Ṣùgbọ́n mo sọ pé, “Háà! Olúwa Olódùmarè. Àwọn wòlíì ń sọ fún wọn pé, ‘Ẹ kò ni rí idà tàbí ìyàn. Dájúdájú èmi ó fún yín ní àlàáfíà tí yóò tọ́jọ́ níbí yìí?’ ”

  7. Nígbà náà Olúwa sọ fún mi pé, “Àwọn wòlíì ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ èké ní orúkọ mi. Èmi kò rán wọn, tàbí yàn wọ́n tàbí bá wọn sọ̀rọ̀. Ìran èké ni wọ́n ń rí sí i yín. Àsọtẹ́lẹ̀ èké ni wọ́n ń sọ fún un yín nípa ìran ìrírí, àfọ̀ṣẹ, ìbọ̀rìṣà àti ìtànjẹ ọkàn wọn.

  8. Nítorí náà, èyí ni Olúwa sọ nípa àwọn wòlíì tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ lórúkọ mi. Èmi kò rán wọn, síbẹ̀ wọ́n sì ń sọ pé, ‘Idà kan tàbí ìyàn, kì yóò dé ilẹ̀ yìí.’ Àwọn wòlíì kan náà yóò parẹ́ nípa idà àti ìyàn.

  9. Bẹ́ẹ̀ sì ni àwọn ènìyàn tí wọ́n ń sọ àsọtẹ́lẹ̀ fún ni a ó lé sí òpópónà Jerusalẹmu torí idà àti ìyàn. Wọn kò ní i rí ẹni tí yóò sìn wọ́n tàbí ìyàwó wọn, àwọn ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn. Èmi yóò mú ìdààmú tí ó yẹ bá ọmọkùnrin àti ọmọbìnrin wọn.

  10. O ti kọ̀ mí sílẹ̀,” ni Olúwa wí, “Ìwọ sì wà nínú ìpadàsẹ́yìn. Nítorí náà, Èmi yóò dáwọ́lé ọ, èmi ó sì pa ọ́ run, Èmi kò sì ní fi ojú àánú wò ọ́ mọ́.

  11. Èmi kò tún lè fi ìfẹ́ hàn si ọ, Èmi yóò fi àtẹ fẹ́ wọn sí ẹnu-ọ̀nà ìlú náà. Èmi yóò mú ìṣọ̀fọ̀ àti ìparun bá àwọn ènìyàn mi nítorí pé wọn kò tí ì yípadà kúrò lọ́nà wọn.

  12. Sọ fún wọn wí pé, ‘Èyí ni ohun tí Olúwa wí: Tí ẹ kò bá fi etí sí ọ̀rọ̀ mi, tí ẹ kò sì gbọ́ òfin mi, ti mo gbé kalẹ̀ níwájú yín,

  13. àti tí ẹ kò bá gbọ́ ọ̀rọ̀ àwọn ìránṣẹ́ mi, àwọn wòlíì tí mo rán sí i yín léraléra (ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò gbọ́),

  14. nígbà náà ni èmi yóò ṣe ilé yìí bí Ṣilo, èmi yóò sì ṣe ìlú yìí ní ìfibú sí gbogbo orílẹ̀-èdè ayé.’ ”

  15. ‘Ọ̀rọ̀ Jehonadabu ọmọ Rekabu tí ó pàṣẹ fún àwọn ọmọ rẹ̀ pé wọn kò gbọdọ̀ mu ọtí wáìnì, ni a mú ṣẹ, wọn kò sì mu ọtí wáìnì títí di òní yìí, nítorí tí wọ́n gba òfin baba wọn. Èmi sì ti ń sọ̀rọ̀ fún un yín, ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.

  16. Èmi rán gbogbo àwọn ìránṣẹ́ àti àwọn wòlíì mí sí yín pẹ̀lú wí pé, “Ẹ yípadà nísinsin yìí kúrò ní ọ̀nà búburú yín, kí ẹ sì tún ìṣe yín ṣe sí rere. Kí ẹ ma sì ṣe bọ òrìṣà tàbí sìn wọ́n; ẹ̀yin ó sì máa gbé ní ilẹ̀ náà tí mo fi fún un yín àti fún àwọn baba ńlá yín.” Ṣùgbọ́n ẹ̀yin kò fetí sí mi.

  17. Nítòótọ́, àwọn ọmọ Jehonadabu ọmọ Rekabu pa òfin baba wọn mọ́ tí ó pàṣẹ fún wọn, ṣùgbọ́n àwọn ènìyàn wọ̀nyí kò pa òfin mi mọ́.’

  18. “Nítorí náà, báyìí ni, Olúwa Ọlọ́run àwọn ọmọ-ogun Ọlọ́run Israẹli wí, ‘Fetísílẹ̀! Èmi ó mú gbogbo ohun búburú tí èmi ti sọ wá sórí Juda, àti sórí gbogbo olùgbé Jerusalẹmu nítorí èmi ti bá wọn sọ̀rọ̀: Ṣùgbọ́n wọn kò sì dáhùn.’ ”

  19. “Wọn sì wí pé, àwa kò ní fetísílẹ̀ ọ̀rọ̀ tí o bá bá wa sọ ní orúkọ Olúwa.

  20. Dájúdájú, à ó ṣe gbogbo nǹkan tí a sọ pé à ò ṣe. A ó sun tùràrí sí ayaba ọ̀run, à ó sì da ohun mímu sílẹ̀ gẹ́gẹ́ bí ẹbọ sí àwa àti àwọn baba wa, àwọn ọba àti àwọn aláṣẹ ti ṣe ní àwọn ìlú Juda àti ni àwọn ìgboro Jerusalẹmu. Nígbà náà àwa ní oúnjẹ púpọ̀, a sì ṣe rere a kò sì rí ibi.

  21. Síwájú sí i, ó sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ohun tí ó wà níwájú rẹ, jẹ ìwé kíká yìí; kí o sì lọ fi bá ilé Israẹli sọ̀rọ̀.”

  22. Mo sì ya ẹnu mi, ó sì mú mi jẹ ìwé kíká náà.

  23. Ó tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, jẹ ìwé kíká tí mo fún ọ yìí, fi bọ́ inú àti ikùn rẹ.” Nígbà náà ni mo jẹ ẹ́, dídùn rẹ̀ dàbí oyin ní ẹnu mi.

  24. Ó sì tún sọ fún mi pé, “Ọmọ ènìyàn, lọ ni ìsinsin yìí bá mi sọ ọ̀rọ̀ mi fún ilé Israẹli.

  25. A kò rán ọ sí àwọn tó ń sọ èdè àjèjì tàbí tí èdè wọn ṣòro láti gbọ́, ṣùgbọ́n orílẹ̀-èdè Israẹli ni mo rán ọ sí