Skip to content

Àwọn ẹsẹ Bíbélì nípa Hell

48 ẹsẹ · 31 abala

Àwọn ẹsẹ Bíbélì pàtàkì

Sẹ́ nípa ìwé
  1. Nítorí náà, bí ọwọ́ tàbí ẹsẹ̀ rẹ yóò bá mú ọ dẹ́ṣẹ̀, gé e kúrò, kí o sì jù ú nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti wọ ìjọba ọ̀run ní akéwọ́ tàbí akésẹ̀ ju pé kí o ni ọwọ́ méjì àti ẹsẹ̀ méjì ki a sì sọ ọ́ sínú iná ayérayé.

  2. Bí ojú rẹ yóò bá sì mú kí o dẹ́ṣẹ̀, yọ ọ́ kúrò kí ó sì sọ ọ́ nù. Ó kúkú sàn fún ọ láti lọ sínú ìyè pẹ̀lú ojú kan, ju pé kí o ní ojú méjì, kí a sì jù ọ́ sí iná ọ̀run àpáàdì.

  3. Ní ìbínú, olówó rẹ̀ fi í lé àwọn onítúbú lọ́wọ́ láti fi ìyà jẹ ẹ́, títí tí yóò fi san gbogbo gbèsè èyí ti ó jẹ ẹ́.

  4. “Bẹ́ẹ̀ gẹ́gẹ́ sì ni Baba mi tí ń bẹ ní ọ̀run yóò sí ṣe sì ẹnìkọ̀ọ̀kan, bí ẹ̀yin kò bá fi tọkàntọkàn dárí ji àwọn arákùnrin yín.”

  5. “ ‘Ó sì pàṣẹ kí a gba tálẹ́ǹtì náà lọ́wọ́ rẹ̀, kí a sì fún ọkùnrin tí ó ní tálẹ́ǹtì mẹ́wàá.

  6. Nítorí ẹnikẹ́ni tí ó bá ní a ó fún sí i, yóò sí tún ní sí lọ́pọ̀lọ́pọ̀. Ṣùgbọ́n láti ọwọ́ ẹni tí kò ní ni a ó ti gbà èyí tí ó ní.

  7. Nítorí ìdí èyí, gbé aláìlérè ọmọ ọ̀dọ̀, jù ú sínú òkùnkùn lóde, ibẹ̀ ni ẹ̀kún òun ìpayínkeke yóò gbé wà.’

  8. Bí ọwọ́ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé e sọnù, ó sàn fún ọ kí o ṣe akéwọ́ lọ sí ibi ìyè, ju kí o ní ọwọ́ méjèèjì, kí o lọ sí ọ̀run àpáàdì, sínú iná àjóòkú.

  9. Where their worm dieth not, and the fire is not quenched.

  10. Bí ẹsẹ̀ rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, gé é sọnù, ó sàn kí ó di akesẹ̀, kí o sì gbé títí ayé àìnípẹ̀kun ju kí o ní ẹsẹ̀ méjì tí ó gbé ọ lọ sí ọ̀run àpáàdì.

  11. Where their worm dieth not, and the fire is not quenched.

  12. Bí ojú rẹ bá sì mú ọ kọsẹ̀, yọ ọ́ sọnù, ó sàn kí o wọ ìjọba Ọlọ́run pẹ̀lú ojú kan ju kí ó ní ojú méjì kí ó sì lọ sínú iná ọ̀run àpáàdì.

  13. Níbi ti “ ‘kòkòrò wọn kì í kú, tí iná kì í sì í kú.’

  14. Ní ipò òkú ni ó gbé ojú rẹ̀ sókè, ó ń bẹ nínú ìjìyà oró, ó sì rí Abrahamu ní òkèrè, àti Lasaru ní oókan àyà rẹ̀.

  15. Ó sì ké, ó wí pé, ‘Baba Abrahamu, ṣàánú fún mi, kí o sì rán Lasaru, kí ó tẹ orí ìka rẹ̀ bọ omi, kí ó sì fi tù mí ní ahọ́n; nítorí èmi ń joró nínú ọ̀wọ́n iná yìí.’

  16. “Ṣùgbọ́n Abrahamu wí pé, ‘Ọmọ, rántí pé, nígbà ayé rẹ, ìwọ ti gba ohun rere tìrẹ, àti Lasaru ohun búburú, ṣùgbọ́n nísinsin yìí ara rọ̀ ọ́, ìwọ sì ń joró.

  17. Àti pẹ̀lú gbogbo èyí, a gbé ọ̀gbun ńlá kan sí agbede-méjì àwa àti ẹ̀yin, kí àwọn tí ń fẹ́ má ba á le rékọjá láti ìhín lọ sọ́dọ̀ yín, kí ẹnikẹ́ni má sì le ti ọ̀hún rékọjá tọ̀ wá wá.’

  18. Angẹli karùn-ún sì fún ìpè tirẹ̀, mo sì rí, ìràwọ̀ kan bọ́ sílẹ̀ láti ọ̀run wá, a sì fi kọ́kọ́rọ́ ihò ọ̀gbun fún un.

  19. Ó sì ṣí ihò ọ̀gbun náà, èéfín sì rú jáde láti inú ihò náà wá, bí èéfín ìléru ńlá, oòrùn àti ojú sánmọ̀ sì ṣókùnkùn nítorí èéfín ihò náà.

  20. Òun pẹ̀lú yóò mú nínú ọtí wáìnì ìbínú Ọlọ́run, tí a dà ní ẹ̀kúnrẹ́rẹ́ sínú ago ìrunú rẹ̀; a ó sì fi iná sulfuru dá a lóró níwájú àwọn angẹli mímọ́, àti níwájú Ọ̀dọ́-àgùntàn.

  21. Èéfín ìdálóró wọn ń lọ sókè títí láéláé wọn kò sì ní ìsinmi ni ọ̀sán àti ní òru, àwọn tí ń foríbalẹ̀ fún ẹranko náà àti fún àwòrán rẹ̀, àti ẹnikẹ́ni tí o ba sì gba àmì orúkọ rẹ̀.”

  22. Òkun sì jọ̀wọ́ àwọn òkú tí ń bẹ nínú rẹ̀ lọ́wọ́; àti òkú àti ipò òkú sì jọ̀wọ́ òkú tí ó wà nínú wọn pẹ̀lú: a sì ṣe ìdájọ́ wọn, olúkúlùkù gẹ́gẹ́ bí iṣẹ́ wọn.

  23. Àti ikú àti ipò òkú ni a sì sọ sínú adágún iná. Èyí ni ikú kejì.